Sanwo-Olu borí ìdìbò gómìnà l'Eko, LP ní àfi kí INEC wọ́gilé ìdìbò ọ̀hún

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/Facebook

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ẹgbẹ oṣelu APC lo bori idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Eko.

Alamojuto eto idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Eko, to tun jẹ giwa fasiti ìmọ ẹrọ FUTA nilu Akurẹ, Ọjọgbọn Adenike Temidayo Oladiji lo kede esi ibo naa ninu eyi to ti sọ pe, ibo 762134 lo gbe Gomina Sanwo-Olu wọle fun saa keji ni iṣejọba.

Oludije fun ẹgbẹ oselu Labour, Gbadebọ Rhode-Vivour lo ṣe ipo keji pẹlu ibo 312329

Ti Abdulazeez Olajide Adeniran to jẹ oludije fun ẹgbẹ oselu PDP si ko ibo 62449 lati gbe ipo kẹta.

Ninu ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ Eko, Sanwo-Olubori ninu mọkandi logun; Amuwo ọdọfin nikan ni Gbadebọ Rhodes- Vivour ti moke.

Lasiko ti alaga ẹgbẹ oṣelu Labour ni ipinlẹ Eko, Pasitọ Dayọ Ekong fi n fi ero ati iha ti ẹgbẹ oselu Labour kọ si eto idibo naa han, O pe fun wiwọgile eto idibo naa eyi to ni o kun fun ọpọlọpọ jagidijagan, iwa ipa ati wipe ọpọ emi lo sọnu lori ọrọ idibo naa.

Ṣaaju lawọn aṣoju ẹgbẹ oselu kan to wa inkle ni ibudo akojọpọ esi ibo gomina nipinlẹ Eko naa ti fi to alakoso ajọ INEC nipinlẹ Eko, ọgbẹni Sẹgun Agbaje pe awọn sakiyesi awọn eeyan kan ti wọn n pe ara wọn ni aṣoju ẹgbẹ oselu Labour lawọn ibudo idibo kan lọjọ Satide pẹlu ayederu kaadi idanimọ fun awon asoju ẹgbẹ lọwọ eyi to yatọ gedegbe si eyi ti ajọ INEC fi sita.

Nigba to n fesi alakoso ajọ INEC nipinlẹ Eko ni o yẹ ki wọn pe oun nigba ti idibo naa n lọ lati lee ke s'awọn agbofinro lati ko awọn eeyan naa.

O fi kun un pe lootọ lẹgbẹ oselu Labour nipinlẹ naa wa ba ajọ naa pe awọn fẹ yan awọn eeyan kan ti awọn fẹ fun ni taagi fun idibo, ṣugbọn ti oun fi to wọn leti pe olu ileeṣẹ ajọ naa nikan lo laṣẹ labẹ ofin lati fun ẹnikẹni ni kaadi idanimọ lasiko idibo naa ati pe ẹgbẹ ti ba ṣe eyi funrararẹ n tako ofin ni.

Bakan naa ni Alakoso ajọ INEC nipinlẹ Eko tun rọ awọn ọmọ Naijiria, paapaajulọ awọn oloṣelu lati maṣe sọ oro oṣelu di booba o pa, booba o buu lẹsẹ to ba jẹ pe lootọ ni ìlépa wọn da le igbayegbadun araalu

Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa Babajide Sanwo-Olu

Aworan Babajide Sanwoolu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwoolu/Facebook

Babajide Sanwo-Olu ni gomina ipinlẹ Eko lati ọdun 2019, o si n du ipo naa fun igba keji.

Wọn bi Sanwo-Olu lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 1965, niluu Eko, eyii to mu ko jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọta bayii.

O kẹkọọ nile ẹkọ Government Demonstration School, Gbaja, Surulere, ko to lọ si Ijebu-Ife Grammar School, nipinlẹ Ogun.

Lati ibẹ lọ, o kẹkọọ gboye ni fasiti ilu Eko, University of Lagos, o tun kẹkọọ lawọn ile ẹkọ mii bii John F. Kennedy School of Government, London Business School ati Lagos Business School.

Sanwo-Olu jẹ ọmọ ẹgbẹ Chartered Institute of Personnel Management, CIPM, ati Nigeria Institute of Training and Development, NITAD.

O ṣiṣẹ nile ifowopamọ Lead Merchant Bank laari ọdun 1994 si 1997 ko to lọ si UBA ati FCMB.

Wo esi idibo gbogbo ijọba ibilẹ ipinlẹ Eko

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

AGEGE LG

A 57

AA 41

AAC 27

ADC 235

ADP 149

APC 35845

APM 41

APP 14

BP 21

LP 8486

NNPP 70

NRM 15

PDP 3176

SDP 8

YPP 11

ZLP 88

AJEROMI IFELODUN LG

A 64

AA 33

AAC 45

ADC 213

ADP 140

APC 39798

APM 73

APP 15

BP 40

LP 19821

NNPP 121

NRM 19

PDP 2607

SDP 11

YPP 19

ZLP 181

IKEJA LG

A 37

AA 12

AAC 21

ADC 310

ADP 109

APC 32273

APM 044

APP 10

BP 18

LP 15174

NNPP 130

NRM 14

PDP 1616

SDP 60

YPP 11

ZLP 60

MUSHIN LG

A 106

AA 25

AAC 27

ADC 312

ADP 180

APC 52249

APM 45

APP 7

BP 22

LP 11759

NNPP 86

NRM 13

PDP 4006

SDP 16

YPP 16

ZLP 83

SURULERE LG

A 77

AA 236

AAC 22

ADC 350

ADP 123

APC 42451

APM 33

APP 11

BP 83

LP 28069

NNPP 118

NRM 16

PDP 2200

SDP 27

YPP 96

ZLP 89

IBEJU LEKKI LG

Reg voters 134496

Accred voters 27480

A 6

AA 3

AAC 11

ADC 101

ADP 49

APC 19369

APM 12

APP 7

BP 8

LP 3785

NNPP 12

NRM 6

PDP 3189

SDP 3

YPP 4

ZLP 15

IFAKO IJAYE LG

A 30

AA 24

AAC 28

ADC 356

ADP 128

APC 38682

APM 42

APP 11

BP 24

LP 13020

NNPP 55

NRM 7

PDP 2262

SDP 11

YPP 15

ZLP 88

BADAGRY LG

A 45

AA 72

AAC 34

ADC 212

ADP 170

APC 41482

APM 67

APP 14

BP 22

LP 4863

NNPP 46

NRM 19

PDP 5472

SDP 13

YPP 21

ZLP 60

LAGOS MAINLAND LG

A 19

AA 10

AAC 17

ADC 278

ADP 92

APC 26021

APM 46

APP 6

BP 57

LP 9999

NNPP 55

NRM 45

PDP 2362

SDP 10

YPP 22

ZLP 45

ALIMOSHO LG

A 64

AA 63

AAC 89

ADC 658

ADP 293

APC 83631

APM 100

APP 24

BP 59

LP 37136

NNPP 210

NRM 40

PDP 7872

SDP 28

YPP 43

ZLP 214

OJO LG

A 33

AA 24

AAC 19

ADC 191

ADP 98

APC 30797

APM 37

APP 32

BP 37

LP 19027

NNPP 101

NRM 16

PDP 3889

SDP 10

YPP 30

ZLP 109

IKORODU LG

A 45

AA 42

AAC 56

ADC 501

ADP 256

APC 64697

APM 71

APP 13

BP 28

LP 13207

NNPP 80

NRM 22

PDP 3797

SDP

YPP 21

ZLP 96

OSHODI ISOLO LG

A 34

AA 36

AAC 55

ADC 258

ADP 272

APC 36792

APM 40

APP 8

BP 40

LP 24948

NNPP 73

NRM 16

PDP 2515

SDP 13

YPP 18

ZLP 99

AMUWOODOFI LG

A 14

AA 34

AAC 10

ADC 156

ADP 63

APC 17576

APM 20

APP 6

BP 39

LP 34860

NNPP 82

NRM 7

PDP 1809

SDP 11

YPP 10

ZLP 66

Kosofe

A 45

AA 20

AAC 80

ADC 632

ADP 196

APC 49,344

APM 46

APP 49

BP 33

LP 26,123

NNPP 152

NRM 22

PDP 3537

SDP 1,376

YPP 34

ZLP 120

ETIOSA LG

A 29

AA 8

AAC 13

ADC 617

ADP 96

APC 25963

APM 34

APP 7

BP 25

LP 19967

NNPP 52

NRM 24

PDP 1468

SDP 18

YPP 50

ZLP 59