Funke Akindele sọ̀rọ̀ sókè lẹ́yìn tí èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko jáde

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Funke Akindele

Gbajugbaja oṣere tiata, to tun jẹ oniṣowo ati oloṣelu, Funke Akindele ti dupọ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun akitiyan wọn lasiko eto idibo gomina to kọja.

Ninu atẹjade kan loju opo Twitter ati Instagram rẹ lo ti fi ẹmi imoore naa han.

O ni ọpọ ẹkọ loun kọ lati ara eto idibo naa, oun ko si kabamọ pe oun dije.

Funke, to dije du ipo igbakeji gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹbẹ oṣelu PDP ni o lulẹ lẹyin ti INEC kede pe Babajide Sanwo-Olu ti ẹgbẹ oṣelu APC lo yege.

Funke ni “Ọpọlọpọ ẹkọ ni mo kọ lasiko eto idibo, nitootọ, mi o kabamọ pe mo gbe igbesẹ lati du ipo oṣẹlu.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

“Nitori naa mo fẹ dupẹ lọwọ awọn eeyan ilu Eko fun igbagbọ wọn ninu mi, mo ri gbogbo akitiyan awọn to ti mi lẹyin lori ayelujara ati loju aye.”

"Mo ranti bi awọn eeyan ṣe tẹwọ gba wa lasiko ti a n ṣe ipolongo ibo."

Funke sọ siwaju si pe esi idibo ọhun le ma lọ bi awọn ṣe lero amọ awọn gbiyanju iwọn ti wọn le ṣe."

“Mo si fẹ fi akoko yii gba gbogbo awọn to ba ni ifẹ orilẹ-ede yii lọkan lati maṣẹ sọ ireti nu.”

Ṣaaju atẹjade yii ni Funke ti kọkọ yọ gbogbo ọrọ to ni ṣe pẹlu oṣelu kuro loju Instagram rẹ.