Gbajúmọ̀ olórin "Dadakuada", Alhaji Jaigbade Alao jáde láyé!

Jiagbade Alao

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajúmọ̀ olórin dàdàkúàdá ìlú Ilorin, Alhaji Jaigbade Alao ti jáde láyé.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, ogúnjọ́ oṣù Kẹta ní Ọba orin Dàdàkúàdá náà kí dúnnìyàn pé ó dìgbà ní ìlú Ilorin, olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara.

Ẹ ó rántí pé ní ọdún 2022 ni bàbá náà kéde pé òun fi iṣẹ́ orin kíkọ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó pé ọgọ́fà ọdún lókè eèpẹ̀.

Ni aafin Ọba ilu Ilorin, Emir Ibrahim Zulu Gambari ni Jaigbade Alao ti kede ọrọ naa ni ọdun to kọjá.

Irawọ Alhaji Aminullahi Jaigbade Alao tan bi osupa to si da yatọ kedere ninu àwọn to n kọ orin naa.

Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ orin Dàdàkúàdá ni ó ń ṣe idaro baba naa nigba to kede pe oun fẹ fi orin kikọ naa silẹ.

Sawawu kan naa ni Jaigbade wa pẹlu awọn olorin Dadakuada mii bi Odolaye Aremu, Aremu Ose, Iyabo Baluu, Omoeke Amao ati Iya Tamiwo.

Amọ ninu gbogbo wọn, ko si ẹni ti wọn da lọla pẹlu oye Oba Orin bi ti Jaigbade Alao.