Ààwẹ̀ Mùsùlùmí bẹ̀rẹ̀ lónìí, Sultan ti Sokoto kédè!

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Aarẹ igbimọ apapọ fun awọn ẹlẹsin Islam ati Sultan ti Sokoto, Muhammad Sa’ad Abubakar ti fi aridaju han wipe wọn ti ri Oṣu tuntun ninu awọ sanmọ eyiun Osupa eyi to n saami ibẹrẹ Oṣu alapọnle ti Ramadan 1444AH.
Ninu atẹjade kan to jade loju opo Twitter igbimọ to n bojuto riri oṣupa ni Naijiria, Sultan ti Sokoto pe gbogbo Musulumi jakejado naijiria lati bẹrẹ aawẹ gbigba ni Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta, ọdun 2023 lẹyin.
Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe orilẹede Naijria ṣẹṣẹ n pari eto idibo ni, Sultan ti Sokoto tun kesi awọn Musulumi Naijria lati gbadura fun aṣeyọri awọn adari tuntun ti wọn dibo yan.
Ẹ ṣaanu awọn to toṣi laarin wa ki ara le dẹ wọn ninu ilu to le koko yii

Oríṣun àwòrán, OTHERS
“Gẹgẹ bi a ṣe n pari eto idibo gbogbogbo ọdun 2023 ti awọn adari si ti n yọju ni ipele ti ijọba apapọ ati ti ipinlẹ, nipa ifẹ Allah, a n funpe si gbogbo Musulumi lati lo oṣu mimọ yii fi gba adura fun aṣeyọri wọn lati tukọ gbogbo ọrọ to kan orilẹede nla wa, Naijiria”.
Bakan naa lo tun pe awọn ọmọ Naijiria ẹlẹyinju aanu lati ṣeranwọ fun awọ́n ti ko rọwọ họri lawwujọ wọn ninu oṣu yii.
“A n pe awọn ti o ri jẹ laarin wa lati ṣeranwọ fun awọn to to ku diẹ kaato fun atawọn to toṣi lawujọ pẹlu ounjẹ lasiko oṣu Ramadan yii lati lee jẹ kawọn eeyan gbadun irọrun ninu bi ilu ṣe le koko yii.
Allah yoo san wa lẹsan fun Ibadah wa, pẹlu Jannatul Firdaus, Ameen. Ramadan Kareem si gbogbo eeyan.”











