Wó àwọn àgbábọ́ọ̀lù Super Eagles tì yóò kojú Guinea Bissau

Awọn agbabọọlu Naijiria

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹgbẹ agbabọlu agba orilẹede yii yo koju ẹgbẹ agbabọlu lati orilẹede Guinea Bissau lati mo ẹniti yo bori lati kopa ninu idije ife ẹye adulawọ ni ilu Abuja.

Awọn agbabọlu ti yo kopa ninu idije naa ni wọn ti n de si buba igbaradi ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ ti alabala meji ti yo waye.

Lara awọn ti olukọ ẹgbẹ agbabọlu Orilẹede yii Jose Santos Peseiro pe fun idije naa ni balogun Ahmed Musa, Victor Osimhen,Ademola Lukman ati awọn Agbabọlu Ogun miran.

Orilẹede Nigeria yo gba ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ni papa iṣere Mashood Abiola to wa ni Abuja ti wọn si gba abala ẹkẹji ni ọrilẹede Guinea Bissau lọjọ kẹtadinlọgbọn osu yi.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Diehardsupereaglesfan/Facebook

Ẹgbẹ agbabọlu Super Eagles lo un bori pẹlu amin mẹfa ni ipele ti wọn wa lẹyin ti wọn ti bori ẹgbẹ agbabọlu Sierra Leone ati Sao Tome.

Awọn adari ayo fun idije akọkọ ti yo waye ni Abuja lo wa lati Orilẹede Egypt ti Mahmoud Elbana dari pẹlu Youssef Elbosaty, Sami Halhal and Ahmed El-Ghandour.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nigeriafootball federation/Facebook

Orukọ Awọn Agbabọlu Super Eagles.

Awọn Asọle:Francis Uzoho (AC Omonia, Cyprus); Victor Sochima (Rivers United); Kingsley Aniagboso (Giant Brillars)

Agbaọwọ Ẹyin: Oluwasemilogo Ajayi (West Bromwich Albion, England); Bright Osayi-Samuel (Fenerbahce SK, Turkey); Kevin Akpoguma (TSG Hoffenheim, Germany); Kenneth Omeruo (CD Leganes, Spain); Calvin Bassey (FC Ajax, The Netherlands); Daniel Bameyi (YumYum FC); Zaidu Sanusi (FC Porto, Portugal); Bruno Onyemaechi (Boavista FC, Portugal)

Agbaọwọ Arin:Wilfred Ndidi (Leicester City, England); Frank Onyeka (Brentford FC, England); Alex Iwobi (Everton FC, England); Joe Aribo (Southampton, England)

Agbaọwọ Waju: Kelechi Iheanacho (Leicester City, England); Ahmed Musa (Sivasspor K, Turkey); Samuel Chukwueze (Villarreal CF, Spain); Moses Simon (FC Nantes, France); Ademola Lookman (Atalanta BC, Italy); Terem Moffi (OGC Nice, France); Victor Osimhen (Napoli FC, Italy); Paul Onuachu (Southampton FC, England)