Gbomule "lantern": Ǹjẹ́ ó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ fì òǹtẹ̀ lu àwọn ilé iṣẹ́ àyànílówó 173 tí wọ́n fún láṣẹ?

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba apapọ ti fọwọ si ile isẹ ayanilowo lori intanẹẹti to to ẹtalelaadọsan lati sisẹ lorilẹede yii.
Ile isẹ ayanilowo ọkandinlọgofa ni wọn fun lasẹ patapata ti ile iṣẹ mẹrinlelaadọta si gba asẹ fidihẹ.
Igbesẹ naa lo bẹrẹ nigba ti awọn ile isẹ ayanilowo ori erọ ayẹlujara bẹrẹ si ni dojuti awọn onibara wọn, ajọ to daabo bo etọ awọn oníbàárà lorilẹede yii lo bẹrẹ igbesẹ naa ki wọn le daabo bo eto awọn ọmọ orilẹede yii.
Ijọba apapọ tun rọ awọn ile isẹ ayanilowo lati ni ẹka ile ifowopamo to daaju ki wọn to fi ontẹ ijọba lu wọn.
Ijọba gbọdọ fi ilana ofin de awọn ile isẹ ayanilowo... - Onimọ nipa ọrọ aje Jemilat, Tade
Ṣugbon ọpọ awọn ọmọ orilẹede yii lo ti n sọrọ lori igbesẹ ijọba yii, awọn onimọ nipa ọrọ aje ni awọn to n ya ni lowo lori ẹrọ ayelujara intanẹẹti gbọdọ tẹle ofin ti ijọba ṣe fun awọn ayanilowo.
Ọjọgbọn Jameelah Omolara Yaqub ti fasiti ipinlẹ Eko ni bi ijọba ṣe fi ontẹ lu awọn ayanilowo ori erọ ayelujara dara, ṣugbon wọn gbọdọ fi ofin de wọn ki wọn ma baa tẹsiwaju lati fi awọn onibaara wọn ṣe yẹyẹ.
Ọpọlọpọ igba ni awọn ti wọn ya owo lọwọ awọn ayanilowo yii n sọ iriri ibanujẹ ti wọn la kọja nigbakuugba ti awọn to ni owo ba ti wa beere owo wọn.
Lara awọn iya ti awọn mii ti sọ pe awọn jẹ ni bii ki wọn dede wa gbe awọn nnkan ini ẹni to ya owo ninu ile rẹ.
Awọn mii ni "wọn a ti eeyan mọ inu ile iyagbẹ, wọn maa n wọ ẹlomii tuururu nilẹ tori pe ko tete ri owo san" ati oniruuru idunkoko mọni mii.
Ọjọgbon Oludayo Tade ti Fasiti Ibadan ni ai ri ijọba mojuto awọn ile isẹ ayanilowo lo mu akude ba bi awọn ayanilowo se n wuwa si awọn onibara wọn.
Tade ni ijọba gbọdọ gbe igbẹsẹ ti yoo ṣafihan ilana táa fi n ya owo ati ilana taa fi maa daa pada ti yoo si mu adinku ba awọn to finufẹdọ gbẹmi ara wọn nitori airi owo san.
Jameelah ni ilana ofin ti ijọba apapọ ba la silẹ fun awọn ile iṣẹ yii gbọdọ faaye gba ki akọsilẹ wa fun awọn ti wọn n gba owo lọwọ wọn ki wọn si dẹkun ati maa ba ni lorukọ jẹ.
O ni ofin ti yoo daabo bo awọn onibara awọn ayanilowo gbọdọ wa, eyikeyi ti ko ba si tẹle ilana yii ni ki wọn gba iwe aṣẹ lowọ rẹ.
O rọ ijọba lati pese eto ẹyawo fun awọn ọlọja ẹsẹ kuku ki wọn ma baa ko si panpẹ awọn ayanilowo-panilẹkun.















