Tope Olorunfemi: Ìyá rẹ̀ ní ọmọ òun kìí ṣe Yahoo, òbí rẹ̀ ló ra mọ́tò kabúkabú fun
Mojisola Olorunfemi, tii se mama Tope Olorunfemi, ọkunrin ti araalu dana sun lọjọ Aiku to kọja nilu Akure ti sọrọ soke.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, mama oloogbe naa salaye pe owu ati ilara lasan lo mu ki wọn dana sun ọmọ oun.
Mama Tope ni oun wa nibẹ nigba ti wọn dana sun ọmọ naa, ti awọn to dana sun si n pariwo pe nibo lo ti ri owo ra asọ olowo iyebiye ati mọto to n lo.
Bakan naa lo ni gbogbo alaye ti oun se fun wọn lati jọwọ ẹmi ọmọ oun lo ja si pabo.
Mama Tope fikun pe "Wọn ni nibo lo ti ri asọ to wọ sọrun, bata ati mọto to n lo?
Emi ati baba rẹ si la ra mọto naa fun nigba to ni oun ko ri isẹ se.
A ni ko maa fi mọto naa se kabukabu nitori o ti niyawo ati ọmọ.
Awọn to pa ọmọ mi tun ni wọn ba asọ ọmọ, kolo ati ọsẹ ninu mọto rẹ.
Awọn ẹru ọmọ rẹ ati ti iyawo rẹ si lo wa ninu mọto to n gbe, kii se eroja Yahoo rara."
Mama oloogbe naa wa rawọ ẹbẹ sijọba lati se idajọ ododo lori awọn to pa ọmọ oun nitori kii se onijibiti ori ayelujara bi wọn se lero.
O fikun pe oun da eeyan meji mọ ninu awọn eeyan to suru pejọ pa ọmọ oun loju oun.
O ni orukọ ọkan ninu wọn ni Luku, ti ekeji si n jẹ Jobe.
Bakan naa, iyawo oloogbe sọrọ pẹlu BBC Yoruba, to si n sọkun asundakẹ lori iku ọkọ rẹ.
Oun naa si fidi rẹ mulẹ pe ẹru ọmọ oun ati toun ni awọn gbe fun ọkọ oun pe ko maa gbe lọ si Eko.
O ni ọkọ oun kii se Yahoo, kabukabu lo n se.
Wayi o, ọwọ ileesẹ ọlọpaa ti tẹ eeyan kan lori isẹlẹ naa.