Àwọn mọ̀lẹ́bí ọkùnrin tí ‘ìdun jẹ títí tó fi kú’ pè fún ìdájọ́ òdodo

THE HARPER LAW FIRM

Oríṣun àwòrán, THE HARPER LAW FIRM

Awọn mọlẹbi ọkunrin kan to ku sinu ọgba ẹwọn niluu Atlanta, nilẹ Amẹrika, ti sọ pe idun atawọn kokoro mii lo jẹ oloogbe naa titi to fi jade laye.

Ṣaaju ni Lashawn Thompson ti kọkọ dero ẹwọn ni Fulton County ti wọn si gbe lọ si ileewosan awọn alaarun ọpọlọ to wa nibẹ lẹyin to bẹrẹ si n ṣe bii ẹni ti ori rẹ ko pe.

Agbẹjọro ẹbi rẹ, Michael D Harper, fi aworan oloogbe naa lede ninu eyii ti idun ti jẹ ara rẹ.

O ni “A ba oku Ọgbẹni Thompson ninu yara ọgba ẹwọn kan to kun fun idọti lẹyin ti idun atawọn kokoro mii ti jẹ láàyè.”

“Inu yara ọgba ẹwọn ti wọn fi Thompson si buru jai, koda, ko yẹ ẹrankọ ka to maa sọ pe ọmọ eniyan.”

Harper ti wa pe fun iwadii iku oloogbe ọhun bayii.

Bi oloogbe naa ṣe jade laye

Lẹyin oṣu mẹta ti wọn ti fi ṣikun ofin mu afurasi ọhun ni wọn ṣadede ba ninu yara ẹwọn to wa ti ko le gbe apa tabi ẹsẹ, amọ lẹyinorẹyin, o ti dakẹ.

Agbẹjọro rẹ, Harper sọ pe awọn to n ṣo ọgba ẹwọn naa atawọn oṣiṣẹ eto ilera nibẹ mọ pe ko gbadun, amọ wọn ko ṣe nnkankan lati tọju rẹ.

Oniṣegun to yẹ yara wo ti sọ pe lootọ ni idun pọ ninu yara ẹwọn ọhun.

Amọ esi abajade ayẹwo naa ko sọ ni pato ohun gan to ṣokunfa iku rẹ.

Aworan ti agbẹjọro rẹ fi lede ṣafihan idun ni oju ati gbogbo ara rẹ.

Onimọ kan nipa idun ni fasiti Kenturkey, Michael Potter, sọ pe inu yara naa ko ṣe e wo.

Potter idun le ṣokunfa ki eeyan ma le gbe ọwọ tabi ẹsẹ nitori ẹjẹ ni idun n mu.