Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbégi dínà ojú pópó nítorí àìrí omi àti iná lò

Awọn akẹkọọ Adeyemi College of Education, Ondo, ti gbegi dina opopona ilu Ondo si Ore, eyii to gba iwaju ile ẹkọ giga naa kọja bi wọn ṣe n ṣe ifẹhonuhan tako awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa.
Awọn akẹkọọ ọhun lo jade lọpọ yanturu lati fẹhonuhan tako aibikita awọn adari ile ẹkọ naa si airi ina mọnamọna ati omi lo ninu ile ẹkọ naa.
Opopona ọhun ni wọn ti di pa lati nkan bii aago mẹfa abọ owurọ leyi to mu idaduro ba irinna ọkọ lọna ọhun.
Ọpọ awọn arinrinajo ni wọn ko lee kọja, tawọn miran si n wa ọna miran lati gba kọja.

Pupọ ninu awọn akẹkọ naa ni wọn mu garawa omi to ṣofo lọwọ lati fihan pe awọn ko ri omi wẹ tabi dana.

Lara awọn akẹkọ naa to ba BBC Yoruba sọrọ ni bonkẹlẹ sọ pe owo gọbọi lawọn n san lati gbe ninu ọgba ile ẹkọ naa amọ awọn ko ri ere owo si wọn n san.
Wọn wa rọ awọn adari ile ẹkọ naa lati wa wọrọkọ fi ṣada ki ọrọ naa to bọ sori.
Igbiyanju BBC lati gbọ ọrọ latẹnu awọn adari ile ẹkọ naa lo ja si pabo.
Ẹwẹ, wamuwamu lawọn agbofinro wa niwaju ile ẹkọ naa lati ripe ifẹhonuhan ọhun ko da omi alaafia agbegbe naa ru.












