Níbo ni ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu wa?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ibeere to gba ẹnu awọn ọmọ Naijiria kan ni pe nibo ni aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Ahmed Tinubu wa nitori o ti se diẹ ti wọn ti gburo rẹ mọ ni Naijiria

Bola Tinubu lo n duro di Ọjọ Kọkandilọgbọn, osu karun un ti aarẹ Buhari yoo gbe ijọba fun lọna ijọba tiwantiwa.

Eyi ko ṣẹyin bi ajọ INEC ṣe kede pe Tinubu to dije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC lo bori gẹgẹ bi aarẹ ninu idibo sipo aarẹ to waye ni Naijiria.

Awọn miran tilẹ n sọpe aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa gba oke okun lọ lati lọ ṣiṣẹ abẹ, nitori igba ti wọn ri Tinubu kẹyin ni asiko igbaradi fun idibo sipo gomina ni Ọjọ Kejidinlogun, Osu Kẹta , ọdun 2023.

Ni Ọjọ Kejilelogun ni agbẹnusọ rẹ, Tunde Rahman fi lede pe Tinubu ti gba oke okun lọ lati lọ simi, lati ibẹ lọ si Saudi Arabia fun Umrah, ki o to pada wa si Naijiria fun iburawọle rẹ ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un, ọdun 2023.

Nibo ni Bola Tinubu wa?

Adari ikọ iroyin fun ikọ ipologun fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress sọ fun BBC Pidgin pe nkan ti Rahman sọ nigba ti Tinubu lọ si oke okun naa ni oun yoo sọ.

Ọga Bayo Onanuga ni aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa wa ni orilẹede Faranse lati sinmi, ko to bẹrẹ iṣẹ aarẹ ni Ọjọ kọkandinlọgbọn, Osu Karun un.

O ni ko si otitọ ninu iroyin pe Tinubu lọ fun iṣẹ abẹ, to si ran awọn eniyan leti wi pe saaju ni Tinubu ti ni oun n lọ si ilẹ Yuroopu lati lọ sinmi.

‘’Tinubu ko lọ sibẹ fun iṣẹ abẹ. O lọ sinmi kuro ninu hila hilo to rọmọ eto idibo Naijiria lati gbaradi fun iṣẹ iṣejọba Naijiria.’’

‘’Ẹ le pe e ni isinmi. A ti pe ọpọ eniyan lo ti lọ sibẹ lati lọ ṣabẹwọ si, to fi mọ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoo-Olu ati igbakeji rẹ ni ọṣẹ to kọja.’’

Bakan naa lo ni igbakeji aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa ti lọ ri Tinubu ni ọṣẹ to kọja ni ilẹ Faransẹ.

Amọ o ni oun ko mọ igba ti Tinubu yoo pada bọ wa si Naijiria.