A kò ní yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù lóṣù Kẹfà mọ́- Ìjọba àpapọ̀

Bẹntiroolu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìgbìmọ́ tó ń rí sí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti fẹnukò pé àwọn kò ní yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù gẹ́gẹ́ bí èròńgbà pé yóò wáyé nínú oṣù Kẹfà ọdún yìí.

Mínísítà fétò ìsúná àti ààtò ìlú, Zainab Ahmed ló kéde ìfẹnukò nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé wọn tó wáyé ní ìlú Abuja.

Igbákejì ààrẹ Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinnbajo ló ṣaájú ìpàdé náà.

Ahmed ní ìgbìmọ̀ náà gbà pé ìnílò ṣì wà fún ìjíròrò lórí ìgbésẹ̀ náà tó sì fi kun pé ìjọba àpapọ̀, pẹ̀lú àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba tuntun tí yóò gba àkóso nínú oṣù tó ń bọ̀ nílò láti ṣe àwọn iṣẹ́ kan lórí ìgbésẹ̀ náà.

“Ìgbìmọ̀ fẹnukò pé àkókò yìí kò dára tó láti gbé irú ìgbésẹ̀ yìí ṣùgbọ́n a máa tẹ̀síwájú láti ṣe àwọn nǹkan tó tọ́ lórí ìgbésẹ̀ yìí.”

Bákan náà ló fi kun pé lóòótọ́ ni àwọn gbà pé ó yẹ kí àwọn yọ ìrànwọ́ orí epo náà nítorí kìí ṣe ohun tí ìjọba le máa ṣe àmúṣẹ rẹ̀ lọ.

Ó fi kun pé àwọn fẹ́ kí àwọn yọ ìrànwọ́ ọ̀hún nígbà tí kò ní ṣe ìpalára fún àwọn ọmọ Nàìjíríà púpọ̀ jù.

Ó tẹ̀síwájú pé àwọn yóò wá àwọn nǹkan mìíràn tí wọn yóò máa ṣe àmúlò rẹ̀ yàtọ̀ sí ìrànwọ́ orí epo èyí tí yóò ní ipa lára àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò sì ní jẹ́ kí wọ́n mọ ìpalára ìrànwọ́ náà púpọ̀ tí wan bá yọ ọ́.

“A ní ìlànà tí a gbé kalẹ̀ èyí tí a máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lé lórí kó tó di inú oṣù Kẹfà ọdún yíì”, Ahmed sọ.