Ọ̀pọ̀ tó ń ṣe jákujàku lórí ayélujára kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ òṣèré tíátà wa- Ogungbe
Ninu awọn oṣere tiata Yoruba, odu ni Segun Ogungbe kii ṣe aimọ foloko.
O ti to ọjọ mẹta ti oṣere to juwe ara rẹ gẹgẹ bi olukọtan,oludari ati oṣere bakan naa yi ti n da bira lagbo tiata Naijiria.
Pupọ awọn ololufẹ rẹ ni ko mọ pe oṣere yi jẹ ọmọ Abeokuta lapa kan, Osun ati Eko bakan naa.
Lasiko ifọrọwanilẹnuwo to waye laarin rẹ ati BBC Yoruba o ṣe alaye nipa awọn ohun toju ri lagbe oṣere ati awọn ipenija to n ba iṣẹ yi ni Naijiria.
Ti ijọba wa pọ pẹlu ko maa bẹnu atẹ lu awa oṣere
Lara alaye ti Segun Ogungbe ṣe fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo yi, o ni kaka ki ijọba Naijiria maa gbori yin fawọn oṣere niṣe ni wọn n bẹnu atẹ lu wọn.
O ni eleyi jẹ ara nkan to n ko irẹwẹsi ọkan ba awọn oṣere ṣugbọn inu awọn dun pe lagbaye awọn eeyan mọ riri iṣẹ tawọn n ṣe.
''Awọn ijọba wa maa n bẹnu atẹ lu awa oṣere ṣugbọn lagbaye awọn ijọba miran ko ko iyan wakere rara''
O fikun ọrọ rẹ pe iru nkan bayi jẹ ipenija ni paapa fawọn ti o ṣẹṣẹ n dara pọ mọ iṣẹ tiata.
Nipa bi awọn kan ti ṣe n ba orukọ ẹgbẹ oṣere jẹ loju opo ayelujara Ogungbe ṣalaye pe pupọ wọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣere tiata.
''Pupọ awọn to n ṣe jakujaku kii ṣe ọmọ ẹgbẹ wa. Ṣe ẹ mọ pe onikalauku lo ni igbalaye lati ṣe ohun to ba wu wọn, tori naa lawọn wọnyi ṣe n hu iwakiwa loju opo ayelujara''
Owo ni kẹkẹ ihinrere fiimu to dantọ
Ogungbe to ni fiimu baba Ogunde, Jayesinmi ni ohun ti kọkọ kopa ṣalaye pe bi eeyan ba fẹ ṣe fiimu to dantọ afi ko ni owo gidi lọwọ.
O ni pupọ ni o n tiraka lati gbe fiiimu jade ti eleyi a si maa mu ki irufẹ fiimu bẹẹ ku diẹ kaato.
''Ṣe ẹ ri owo ti wọn ma fi n ya fiimu,owo nla ni ṣugbọn awọn eeyan a ṣaa wo pe emi naa fẹ gbe sinima jade''
O ni igba ti owo nla ko ba si ti yọ, fiimu raunraun ni wọn maa n gbe jade sita.
Lakotan, o sọrọ nipa isọlẹnu tawọn eeyan maa n ko ba awọn oṣere wi pe to ba rẹ wọn, wọn a maa tọrọ iranwọ lọwọ araye.
O ni ko si ootọ ninu ọrọ pe awọn kii ṣe iranwọ fun ara wọn ti o ba rẹ oṣere laarin wọn.
O beere fun atilẹyin araalu pe ki wọn gbaruku ti awọn oṣere ki wọn si ye fi ẹnu ṣata igbiyanju awọn oṣere tiata ni Naijiria.















