Afẹ́fẹ́ gáàsì bú gbàmù l'Eko, èèyaǹ márùndínlógún dèrò ilé ìwòsàn

Gas explosion

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni eeyan marundinlogun to farapa yanayana lẹyin ibugbamu gassi to waye ni Ijora Badia, to wa ni ijọba ibilẹ Apapa Iganmu, nipinlẹ Eko.

Atẹjade kan ti adari ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ipinlẹ naa, Margaret Adeseye, fi lede sọ pe nnkan bii aago mẹrin abọ irọlẹ ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti ina ṣẹyọ lara silinda gaasi oni iwọn 25kg kan bu gbamu nibi ti awọn silinda mii wa.

Gẹgẹ bii ohun ti Adeseye sọ, ina naa bẹrẹ lẹyin ti ina kan ṣẹyọ lẹba gaasi silinda gaasi ọhun to ti n jo tẹlẹ.

O ni "Wọn ko ṣe itọju awọn silinda naa daadaa, eyii to mu kii gaasi jo jade ninu rẹ to si fara kan ina. Ina ọhun lo ṣokunfa ibugbamu naa.

"A tete ri ina naa pa, a si ti ko awọn silinda to ku sibẹ jade. Eyii ran wa lọwọ lati dena ijamba to yẹ ko waye nibẹ, alaafia si ti pada jọba lagbegbe ọhun."

Bo tilẹ jẹ pe o ni ko si ẹmi ẹnikẹni to sọnu nibẹ, eeyan marundinlogun ni ina jo lara.

O fi kun pe ọpọ awọn ti iṣẹlẹ naa kan ni wọn tọju nibẹ lẹsẹkẹsẹ, nigba ti wọn gbe awọn mii lọ sile iwosan to wa nitosi.

O ṣalaye apapọ awọn oṣiṣe panapana, oṣiṣe LASEMA, ẹṣọ alaabo ipinlẹ Eko, LNSC ati LASAMBUS lo ri ẹyin ina ọhun ti wọn si doola awọn eeyan nibẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹta odun yii ni gaasi nla kan bu gbamu lori afara Otedola niluu Eko yii kan naa, nibi ti eeyan marun un ti padanu ẹmi wọn.

Yatọ si awọn to ku nibi iṣẹlẹ afara Otedola, ọpọ ọkọ ati dukia lo tun sọnu sibẹ.