Ohun mọ́kànlá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Omololu Olunloyo, gómìnà Oyo tẹ́lẹ̀ tó di olóògbé

Omololu Olunloyo

Oríṣun àwòrán, Olunloyo Family

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oni, ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 ni Omololu Olunloyo dagbare faye laarin ọjọ diẹ si ọjọ ibi aadọrun ọdun ọdun rẹ laye.

Oni yii kan naa ni mọlẹbi rẹ kede pe ọlọjọ ti de fun gomina ipinlinlẹ Oyo tẹlẹri naa.

Iwọnyii ni awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa oloogbe ọhun.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Omololu Olunloyo

  • Ilu ibadan ni wọn bi si lọdun 1935, orukọ abisọ rẹ si ni Victor Omololu Sowemimo Olunloyo
  • Ọmọlẹyin Kristi ni baba rẹ nigba ti iya rẹ jẹ Musulumi
  • Baba rẹ dagbere faye lọdun 1948 nigba to wa lọmọ ọdun mẹtala pere
  • Victor Olunloyo jẹ ẹnikan to ja fafa ninu imọ ẹkọ, o si tun ṣe aṣeyọri gẹgẹ oloṣẹlu
  • Oniruru iwe ni oloogbe naa kọ jade nipa imọ applied mathematics ati number theory
  • Nigba to wa lẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni wọn yan an sipo kọmiṣọna fun idagbasoke ọrọ aje lọdun 1962
  • Wọn tun yan sipo lasiko ijọba ologun Col. Adeyinka Adebayo
  • Olunloyo di oniṣiriṣi ipo oṣelu mu, o si tun jẹ oye niluu Oyo ati niluu Ile Ife
  • O ṣe gomina ipinlẹ Oyo fun oṣu mẹta ki ijọba ologun to gbajọba lọwọ oloṣelu lọdun 1983
  • Lọdun 2011, oun ni alaga ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo
  • Lọdun 2024, iroyin ofege nipa iku rẹ gba igboro kan, amọ o sọ lọdun naa lọun pe akoko oun ko tii to

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀, Omololu Olunloyo jáde láyé

Victor Olunloyo

Oríṣun àwòrán, @thecableng

Gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri, Victor Olunloyo, ti jade laye.

Iroyin ni afẹmọju oni ọjọ Aiku ni oloogbe naa fi aye silẹ.

Ninu atẹjade kan ti awọn to sunmọ mọlẹbi oloogbe naa fi lede, ọjọ perete lo ku ko ṣe ọjọ ibi aadọrun ọdun rẹ loke eepẹ ki ọlọjọ to de.

Atẹjade ọhun ti Oladapo Ogunwusi buwọlu lorukọ mọlẹbi sọ pe "Victor Olunloyo ti lọ sile."

Atẹjade naa sọ pe "Pẹlu ọgbẹ ọkan ni a fi kede ipapoda Ọmọwe Victor Omololu Olunloyo, gomina ipoinlẹ Oyo nigba kan ri, oluṣiro, onimọẹrọ ati agba ọjẹ nipa eto iṣẹjọba, ni ọjọ diẹ si ọjọ ibi aadọrun ọdun rẹ.

"Olunloyo, to jẹ Balogun ilu Oyo ati Otun Bobasewa Ife, ni olori akọkọ nile ẹkọ gbogboniṣe ilu Ibadan ati ipinlẹ Ilorin, o tun di awọn ipo mii mu."

Iroyin iku Olunloyo lọdun to kọja

Ṣaaju ni awọn ileeeṣẹ iroyin kan ti kọkọ jabọ pe Olunloyo ti papoda ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2024, amọ nigba ti awọn akọroyin lọ sile rẹ lasiko naa, o ni ṣaka lara oun da,

O sọ nigba naa pe "Mo ṣi wa nibi, mi o tii lọ."

Gomina tẹlẹ ri ọhun ni inu oun ko si iroyin iku oun nigba ti oun ṣi wa laaye.

O fi kun pe oi si ẹni ti ko ni ku, yala ẹni ti wọn n royin iku rẹ ni o tabi ẹni to n royin iku ẹlomiran.

O ni "Oloriire ni mi, baba mi ku lẹni ọdun mejilelogoji nigba ti iya mi ku lẹni ọdun mejilelọgọrun un, emi naa ti pe ẹni ọdun mọkandinlaadọrun bayii, mo ti lo kọja iye ọdun ti igbagbọ wa pe o yẹ ki n lo laye."