Omololu Olunloyo, ọmọ Ibadan àkọ́kọ́ tó jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, àmọ́ tí kò lò ju oṣù mẹ́ta lọ

Omololu Olunloyo

Oríṣun àwòrán, Other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, ni gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri, Victor Olunloyo, ti jade laye.

Iroyin ni afẹmọju jọ Aiku ni oloogbe naa fi aye silẹ.

Ninu atẹjade kan ti awọn to sunmọ mọlẹbi oloogbe naa fi lede, ọjọ perete lo ku ko ṣe ọjọ ibi aadọrun ọdun rẹ loke eepẹ ki ọlọjọ to de.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ, ojugba Oloogbe Obafemi Awolowo, ni baba to bi Omololu Olunloyo, amọ oloogbe Samuel Ladoke Akintola, lo jẹ awokọṣe fun un nidii oṣelu.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Omololu wa nigba to di kọmisanna fun eto ọrọ aje, labẹ iṣakoso Ọmọwe Moses Majekodunmi, gẹgẹ bi olori nigba iṣejọba Tafawa Balewa.

Lẹyin eyi lo da ara rẹ pọ mọ ẹgbẹ National Council of Nigeria and the Cameroons.

Ko pẹ pupọ si asiko naa ni Olunloyo di olori awọn ileeṣẹ ijọa – eto ẹkọ, ati ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.

Eyi waye labẹ iṣakoso gomina Ologun fun ẹkun Western Region, Adeyinka Adebayo.

Koda, o gba ami ẹyẹ kọmisanna alagbada, to tayọ julọ nigba naa.

Yatọ si eyi, Omololu Olunloyo tun ni ọga agba akọkọ fun ileẹkọ gbogboniṣe Polytechnic ilu Ibadan, ko to di pe ijọba miran, Ọgagun Oluwole Rotimi, yọ ọ.

Ọmọ Ibadan akọkọ to di gomina ipinlẹ Oyo

Omololu Olunloyo

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara awọn ipo ti Omololu Olunloyo tun dimu ni alaga nigba kan ri fun ileeṣẹ Oodua Investment Limited ati awọn miran.

Lọdun 1983, oloogbe Olunloyo darapọ mọ awọn oludije fun ipo gomina ipinlẹ Oyo.

Lasiko naa, gomina to wa nipo, Oloye Bola Ige, naa n gbaradi fun saa keji nipo. Ṣugbọn ṣa, alatako rẹ, Olunloyo ati awọn alatilẹyin rẹ n fi ipolongo ibo wọn "Ọmọ w ani, ẹ jẹ ko ṣe e", kọju ija si i.

Eyi ni irinṣẹ ti wọn lo lati ri i daju pe o wọle sipo gẹgẹ bi ọmọbibi ilẹ Ibadan akọkọ ti yoo di gomina ipinlẹ Oyo.

Olunloyo wọle lootọ, ninu idibo ọhun to waye ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 1983, pẹlu bo ṣe fi ẹyin Bola Ige, janlẹ.

Ṣugbọn ṣa, Olunloyo ko tọjọ lori ipo naa – oṣu mẹta pere lo lo nipo. Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 1983 lo kuro.

Eyi ko ṣẹyin iditẹgbajọba ti Ọgagun Muhammadu Buhari lewaju rẹ.

Lẹyin ti iditẹgbajọba naa waye, Olunloyo wa lara awọn eeyan ti wọn fi ofin de pe, ko gbọdọ dije-dupo lati inu eyikeyi ẹgbẹ oṣelu ti Ọgagun Sani Abacha, da silẹ.

Gbogbo igbiyanju rẹ lẹyin naa lati dije fun ipo gomina lọdun 1999 ati 20023, ni ko so eso rere ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to wa.