Mọ̀lẹ́bí Omololu Olunloyo ṣàlàyé nípa bí olóògbé nàá ṣe kú

Oríṣun àwòrán, Other
Ọpọ awọn ololufẹ ati awọn abanikẹdun lọ pejọ silẹ gomina nigba kan ri nipinlẹ Oyo, Omololu Olunloyo to papoda ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2025.
Ọkan ninu awọn iyawo oloogbe, Aderonke Olunloyo sọ pe, bi ala lo jẹ nigba to gbọ nipa iku ọkọ rẹ nitori oun ko figba kan ro iku si gomina tẹlẹ.
"Bi ala lo jẹ nigba ti wọn pe mi lori aago igbelewọ mi wi pe, ọkọ mi ti jade laye."
Aderonke ni ile iwosan aladani kan ni awọn gbe oloogbe naa lọ ti o sii ti n gba itọju, ọjọ Aiku ti o jade laye loyẹ ki wọn daa silẹ ni ile iwosan.

"Sadeede ni wọn ni eemi rẹ ko lọ geere mọ, ti wọn si fi afẹfẹ 'oxygen' si ni imu ko tọ di wi pe o jade laye."
Aderonke ni ninu gbogbo awọn oloṣelu orile-ede Naijiria, ọkan gboogi ni Omololu jẹ nitori wi pe ko kowo jẹ nigba ti o wa lori aleefa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo/Osun.
Lara awọn to tun ṣe abewo si idile naa ni olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, Rt Adebo Ogundoyin, to si nii gbogbo Ipinlẹ Oyo ni lo n se aro Baba Omololu Olunloyo.
O ni ile igbimo asofin ipinlẹ Oyo yoo ṣa ipa rẹ lati fi nnkan gbogi lelẹ ti yoo si jẹ nnkan ti gbogbo awọn eeyan yoo maa fi ranti Omololu Olunloyo.
Ogundoyin tesiwaju wi pe, gbogbo oloṣelu nipinlẹ Oyo lo n ri baba gẹgẹ bii adari to ṣe e mu yangan, okedun wi pe gbogbo ọgbọn atinuda ati imọ Omololu Olunloyo ni ipinlẹ Oyo yoo padanu.
Ọdun 1983 ni Omololu Olunloyo jẹ gomina ipinle Oyo ati Osun labẹ ẹgbẹ oselu NPL tí o si jẹ gomina fun oṣu mẹta ki ijọba ologun Buhari /Idiagbon to ro gbogbo wọn loye.















