Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé níbi ìwúyè Aláàfin tuntun
Lẹyin ọdun mẹta ti awuyewuye ti rọ mọ ipo Alaafin Ọyọ ati ori itẹ, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makide kede Alaafin tuntun fun ilu Ọyọ.
Ninu atẹjade ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi ranṣẹ si awọn oniroyin lorukọ Kọmisana fun iroyin, Ọmọọba Dọtun Oyelade, wọn kede Ọmọọba Akeem Abimbola Owoade gẹgẹ bii Alaafin tuntun fun Ọyọ.
Alaafin Owoade si lo n jẹ Alaafin lẹyin ti Alaafin ana, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta waja ni ọjọ Kejilelogun osu kẹrin ọdun 2022.

Ọjọ Karun osu kẹrin ọdun 2025 ni ayẹyẹ iwuye Alaafin tuntun fun ilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade Kinni.
Ilu Oyo si ni ayẹyẹ iwuye naa yoo ti waye, ti BBC Yoruba si ti wa nikalẹ digbi lati maa mu awọn iroyin ohun to n sẹlẹ nibẹ wa fun yin.
Lootọ ni iwuye ti pari, ẹ wa wo awọn ohun pataki to yẹ ki ẹ mọ nipa bi ayẹyẹ naa ṣe lọ






