Báwo ni àwọn ohun èèlò ìkunjú tí ò ń lò ṣe burú sí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Nazanin Motamedi
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Má parọ́: Ọjọ́ wo ni o ṣàyẹ̀wò ìgbà tí ọjọ́ máa lọ lórí àwọn ohun èèlò ìkunjú tí ò ń lò kẹ́yìn? Ṣé àwọn ohun èèlò ìkunjú tí ọjọ́ ti lọ lórí wọn le ní ìpalára fún ààwọ̀ ara à rẹ tàbí fi ìlera rẹ sínú ewu?
Báwo ni o ṣe máa ń fọ àwọn búrọ̀ṣì tí ò ń lò láti fi kun ojú? Ṣé o ti yá másíkárà ọ̀rẹ́ ẹ̀ rẹ rí tàbí lo ìtọ́tè wo níbi tí ó ti fẹ́ rà á? Èwo nínú àwọn ohun èèlò ìkunjú rẹ ni àwọn kòkòrò àìfojúrí wà nínú rẹ̀ jùlọ - ṣé másíkárà ni, tìròó, kàìnkàìn tàbí àwọn búrọ́ọ̀ṣì?
Kí a má parọ́, mi ò kí ń sábà ṣe ìmọ́tótó àwọn ohun èèlò ìkunjú mi lóòrè kóòrè tàbí wo ìgbà tí ọjọ́ máa lọ lórí wọn, èyí ló jẹ́ kí n kó wọn lọ fún àyẹ̀wò – lábẹ́ ẹ̀rọ aṣàyẹ̀wò ohun àìfojúrí microscope ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì London Metropolitan University ní United Kingdom.
Dókítà Maria Pilar botey-Salo, olùkọ́ àgbà lẹ́ka Biosciences ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Human Sciences náà mójútó ìwádìí yìí. Ó darí àyẹ̀wò àwọn tììròó, másíkárà, ìtọ́tè, àtíkè, búrọ́ọ̀ṣì àti kàìnkàìn tó lé ní àádọ́rin tó fi mọ́ ti èmi náà.
Wọ́n gbé àwọn nǹkan tí wọ́n ti gbà náà sábẹ́ àyẹ̀wò láti mọ àwọn nǹkan tó wà lára wọn.

Báwo ni ohun èèlò ìkunjú mi ṣe ti bàjẹ́ tó?
Bí àwọn kòkòrò àìfojúrí tó wà lára àwọn ohun èèlò ìkunjú yìí ṣe pọ̀ tó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún mi.
Dókítà Botey-Salo sọ pé tììróò ló ní àwọn kòkòrò àìfojúrí tó pọ̀ jùlọ. Ó ṣàlàyé pé èyí le rí bẹ́ẹ̀ látàrí bí ó ṣe jẹ́ pé òun ló ń kan ojú àti ara jùlọ, tó sì lè gbé àwọn kòkòrò bí i "staphylococcus".
Mo gbà pé mó máa ń gbé báàgì ohun èèlò ìkunjú kalẹ̀ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lóòótọ́, tí mo sì máa ń fi tììróò kalẹ̀ láì ní dé fún ọ̀pọ̀ ìṣẹ́jú nígbà míì.
"Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé òhun ló fà á," Dókítà Botey-Salo sọ. "Tí omi bá wọ ara rẹ̀ láti ibẹ̀, ó ṣeéṣe kí kòkòrò àìfijúrí máa ti ibẹ̀ jáde. A tún rí "staphylococcus" lára àwọn ohun èèlò mìíràn tí a ṣàyẹ̀wò tó fi mọ́ àwón búrọ́ọ̀ṣì àti másíkárà."
Staphylococcus máa ń fa onírúurú àwọn àìsàn, ó le jẹ́ àwọn àìsàn kékeré, tó sì lè di ńlá bíi conjunctivitis, erysipelas àti impetigo.
Kí ló dé tí mi ò ní àwọn àìsàn yìí tó sì jẹ́ pé mò ń lo tììróò yìí lọ́pọ̀ ìgbà?
Dókítà Botey-Salo ṣàlàyé pé tí ara èèyàn bá pé, ó ṣeéṣe kí àwọn àìsàn yìí má jẹyọ. àmọ́ tí èèyàn bá ní àpá lára, àwọn kòkòrò yìí le gba ibẹ̀ wọnú ara èèyàn tó sì lè ṣàkóbá fún èèyàn. Tí èròjà ara tó máa ń bá àwọn àìsàn jà náà kò bá lágbára tó, ó ṣeéṣe kó jẹ́ ohun ìkọnilóminú.

Fífọ ọwọ́ ṣe pàtàkì
Ṣé ó máa ń fọ ọwọ́ ọ̀ rẹ kí o tó kún ojú? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò àìfojúrí ni èèyàn máa ń fi ọwọ́ kó lóòrè kóòrè, tí èèyàn kò bá sì máa ṣe ìmọ́tótó ọwọ́ nígbàkugbà, ó ṣeéṣe kí èèyàn ko ran àwọn ohun èèlò ìkunjú rẹ̀. Èyí le wáyé nígbà tí èèyàn bá ń kun eyeshadow, ìtẹ́tè àti àtíkè pẹ̀lú ọwọ́ lásán.
Dókítà Botey-Salo tún ṣàwàrí ohun ìjayà kan. Ó ṣàlàyé pé àwọn ṣàwárí "Enterobacter cloacae" kòkòrò àìfojúrí tó máa ń wà nínú ìfun lára ohun èèlò náà."
Ó ní èyí fi hàn pé àìsí ìmọ́tótó tó péye pàápàá nílé ìgbọ̀nsẹ̀ nítorí pé lára ìgbọ̀nsẹ̀ ni ó ṣeéṣe kí wọ́n ti rí kòkòrò náà.
Ìwádìí fi hàn pé tí èèyàn bá ṣan ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àwọn ẹ̀rúnrún ìgbọ̀nsẹ̀ kan lè fò sókè láàárín ìṣẹ́jú àáyá. Àwọn ìgbọ̀nsẹ̀ náà le ní kòkòrò àìfojúrí Enterobacter. Tí àwọn ohun èèlò ìkunjú bá wà ní ìtòsí, ó ṣeéṣe kí àwọn kòkòrò àìfojúrí náà wọ ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn kòkòrò Enterobacter jẹ́ ohun ìkọnilóminú nítorí pé wọ́n lè fa àìsàn bíi àìsàn ilé ìtọ̀, ọ̀nà ọ̀fun, osteomyelitis àti endocarditis.
Àwọn ìwádìí tó ti wà tẹ́lẹ̀ fi hàn pé Enterobacter le ṣẹ̀mí lára àwọn ohun èèlò ìkunjú, tí èyí sì léwu púpọ̀ nítorí ojú ni a máa ń lo àwọn ohun èèlò yìí sí.
Ikọ̀ olùwádìí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Metropolitan University tún ṣàwárí kòkòrò àìfojúrí mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Candida lára àwọn ohun èèlò make up. Tí kòkòrò yìí bá wọ ara, ó le fa àìsàn vaginal candidiasis tàbí oral candidiasis.
Ìwádìí míì tí wọ́n ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ Aston University ní Birmingham ní UK lórí àwọn ohun èèlò ìkunjú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500). Ìwádìí náà ṣàfihàn pé ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́rin sí àádọ́rùn-ún (79-90%) àwọn ohun èèlò ìkunjú ló ní àwọn kòkòrò àìfojúrí bíi parasite, bacteria tàbí fungus nínú. Àwọn mìíràn ni ìpalára tí wan le ṣe fún èèyàn kò lágbára tàwọn míì sì lágbára.
Pàtàkì ìgbà tí ọjọ́ máa lọ lórí àwọn ohun èèlò
Ìgbà tí ọjọ́ máa lọ lórí àwọn ohun èèlò yìí ṣe pàtàkì nítorí òhun ló máa sọ nípa bí àwọn kẹ́míkà tó wà nínú wọn tó le ṣe ìdádúró àwọn kòkòrò àìfojúrí yìí láti máa dàgbà. Àwọn ohun èèlò tí omi pọ̀ nínú wọn ṣeéṣe kí wọ́n tètè máa ní kòkòrò àìfojúrí ju àwọn tí kò ní omi lọ.
"Ti ohun èèlò ìkunjú kan kò bá ní ìgbà tí ọjọ́ máa lọ lórí wọn, ó dára kí èèyàn sọ ọ́ nù lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tàbí ìgbà tí èèyàn bá rò pé ó ṣeéṣe kí ọjọ́ lọ lórí wọn," dókítà Bashir sọ.
"Tí èèyàn kò bá mọ ìgbà tí ọjọ́ máa lọ lórí àwọn àwọn make up, ó sà n kí èèyàn ra òmíràn ju kí àìsàn wọlé tọ̀ ọ́ wá lọ."

The worst offenders and how to avoid them
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ilé ẹ̀kọ̀ London Metropolitan University ṣe sọ, àwọn ohun èèlò tí wọ́n máa ń tètè bàjẹ́ ni másíkárà àti foundation nítorí pé wọ́n ní omi nínú àtàwọn búrọ́ọ̀ṣì tí wọ́n fi máa ń kùn wọ́n.
"Àwọn ohun èèlò tó ní omi nínú ni ó ṣeéṣe kí kòkòrò àìfojúrí tètè pọ̀ nínú wọn," Dókítà Botey-Salo sọ. "Àwọn ohun èèlò tí ọjọ́ ti lọ lórí wọn ni ìwádìí wa da lé lórí."
Dr Botey-Salo ní káwọn èèyàn máa tẹ̀lé ìgbésẹ̀ yìí láti rip é àwọn ohunèèlò wọn kò tètè máa bàjẹ́:
Fọ ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó kun ojú.
Ma lo àwọn ohun àyẹ̀wò tí o bá dé ilé ìtajà tí wọ́n ti ń tà wọ́n
Máa fi ọṣẹ àti omit ó lọ wọ́ọ́rọ́ fọ àwọn búrọ́ọ̀ṣì rẹ lóòrè kóòrè, kí o sì rip é wọ́n gbẹ dáadáa kí o tó kó wọn sínú àpò wọn padà.
Kò dára láti máa kó àwọn ohun ìkunjú rẹ̀ sínú ilé ìwẹ̀ nítorí omi.
Ri daju pé àwọn másíkárà, foundation, àti tììróò rẹ ni ò ń fi ọmọrí wọn dé wọn nígbà gbogbo.
Wo ìgbà tí ọjọ́ máa lọ lórí ohun èèlò kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ ọ́ sára ọ̀kọ̀ọ̀kan láti máa rántí ìgbà tó yẹ láti sọ wọ́n nù.
Má pìn-ín make up rẹ lò pẹ̀lú ẹlòmíràn
Dókítà Botey-Salo ni ó dára láti máa wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí ní gbogbo ìgbà láti dènà àìsàn lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àìfojúrí.












