Ibí yìí ni Ọya wọlẹ̀ sí nílùú Ira, ìpínlẹ̀ Kwara, àti ìdí gan-an tó fi bínú wọlẹ̀
Ninu itan Yoruba, akọni obinrin ni Ọya, iyawo Alaafin Sango.
Itan sọ pe Oya binu wọlẹ ni ilu kan ti wọn n pe ni Ira.
Lode oni, ipinlẹ Kwara ni ilu Ira wa, nijọba ibilẹ Oyun.
BBC Yoruba ṣe abẹwo si ilu Ira, paapaa ni oju ibi ti Ọya to pada di oriṣa nla nilẹ Yoruba, wọlẹ si.
Kabiesi ilu Ira, Ọba Abdulwahab Oyetoro, Onira ti Ira, to gba BBC lalejo ṣalaye pe, Igbo Oya ni wọn n pe ibi ti Oya wọlẹ si niluu naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọmọ bibi ilu Ira gan-an ni Oya, ko to o di pe o lọ si ilu Ọyọ nigba iwasẹ.
Ṣaaju ko to o lọ, o ti kọkọ fẹ oriṣa nla miran ti a mọ si Ogun, amọ igbeyawo naa pada tuka.
Lẹyin rẹ ni Ọya di olori Alaafin Sango niluu Oyo.
Kabiesi Oyetoro sọ pe ọmọọba ni Ọya funra rẹ niluu Ira, to si ni agbara lati fa òjò.
"Gbogbo ogun ti Sango ma n lọ ni Ọya n tẹle lọ gẹgẹ bi iyawo rẹ.
"Agbara yii ni Ọya ma n ,o lati rọ ojo le awọn ọta ti ọkọ rẹ ba n ba a jagun lori, titi gbogbo awọn nnkan ija ati amuṣagbara wọn yoo fi bajẹ. Eyi ma n mu ko rọrun fun Sango lati bori ninu ogun."
Ija to waye laarin Sango ati awọn afọbajẹ niluu Oyo, ti a mọ si Oyomesi, pada yọri si bi Alaafin ọhun ṣe waja.
Lẹyin ipapoda rẹ ni Ọya pada si ilu abinibi rẹ niluu Ira.

Gẹgẹ bi Ọba Oyetoro ṣe sọ, Oya n gbe igbeaye rẹ niluu Ira, to si n ṣe iṣẹ agbọmọla.
Nigba to ya, awọn alagbara ọkunrin tun bẹrẹ si ni wa a wa lati fi ṣe aya. Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe ti gburo agbara to ni. Ṣugbọn gbogbo wọn ni Ọya kọ lati fẹ ẹ.
'Esi ti Ọya ma n fun wọn ni pe, lẹyin ti oun ti ṣe olori Alaafin fun Sango, oun ko le fẹ ọkunrin miran mọ.
Nigba to ya, awọn ẹbi rẹ bẹrẹ si i yọ ọ lẹnu lati yan ọkunrin kan lati fẹ. Nigba ti idaamu naa pọ, ni Ọya binu wọlẹ si ibi to di Igbo Oya niluu Ira, ipinlẹ Kwara, to si wa nibẹ titi di oni.
Nigba iwasẹ, wọn ma n bọ Ọya ni ọrun tabi oṣooṣu, amọ nisinsiyi, ko ri bẹẹ mọ nitori ẹsin to ti wọle, gẹgẹ bi Ọba Oyetoro ṣe sọ.
Bakan naa lo sọ pe eewọ ni fun awọn to n bọ oriṣa Ọya lati maa sin aguntan.



