''Èédú àti ewé ni àwọn èèyàn ń jẹ ni Sudan báyìí''

Aworan ọkan lara awọn eeyan ti ogun n le kiri ni Sudan

Oríṣun àwòrán, EPA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni bayii, eedu ati eweko ni awọn eeyan ti ogun n le kiri ni Sudan n jẹ lati wa laaye, ko si ounjẹ fun wọn mọ.

Ajọ oluranlọwọ kan lo fidi eyi mulẹ fun BBC.

Ajọ naa ṣalaye, pe lẹyin ti ikọlu tun ba awọn eeyan nibudo ti wọn sa si nitosi El-Fasher, eedu ati eweko lo ku ti wọn n jẹ.

"Iroyin to ba ni lẹru gbaa la n gbọ nipa wọn. Awọn eeyan n sa kuro ni El-Fasher lọ si Tawila, ṣugbọn bi wọn ṣe n de naa ni wọn ṣe n di oloogbe.

" Noah Taylor, ọmọ orilẹ ede Norway; olori ikọ to n ri si ọrọ awọn alai-ribi-gbe naa lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

"Ai ri omi mu lo n pa awọn kan, nigba ti wọn maa rin irin ogoji kilomita, ti I ṣe maili mẹẹẹdọgbọn lati Zamzam, bẹẹ inu oorun ganrin-ganrin ni wọn ti n rin irin ọhun.

"A ti gbọ pe oku awọn eeyan ṣi wa loju ọna laaarin El-Fasher si Tawila.

"A ba mọlẹbi kan sọrọ, wọn sọ fun wa nipa ọmọbinrin kan to n da nikan fi ẹsẹ rin lati El-Fasher, wọn n ba a laṣepọ ipa leralera loju ọna naa, nigba to si de si Tawila, niṣe lo ku latari ọgbẹ ti wọn ti da si i loju ara."

Noah Taylor, olori ikọ alaanu to n ri si ọrọ awọn alai-ribi-gbe naa lo ṣalaye bẹẹ.

Nibẹrẹ oṣu Kẹrin yii ni awọn ologun RSF to n daamu awọn eeyan Sudan, kọlu ibudo aabo tawọn alainile n farapamọ si ni Zamzam.

Ilu El-Fasher yii lo gbẹyin ninu ninu awọn to wa nigbekun RSF lapa Iwọ-Oorun Sudan.

Íṣoro owó ti jẹ́ kí UN dín oúnjẹ tó ń wọ agbègbè tí ìyàn ti ń mú ní Sudan kù

Gẹgẹ bi awọn ajọ alaanu kaakiri agbaye ṣe wi, awọn ounjẹ ati iranwọ to n lọ si agbegbe ti iyan ti n mu yii ti dinku jọjọ.

Eyi ri bẹẹ latari owo iranwọ ti wọn lo dinku.

Ajọ UN pẹlu fidi eyi mulẹ.

Ninu ọrọ Taylor lo ti ni awọn eeyan to n sa wa si Tawila wa ti n pọju.

O ni ilu naa ti n koju iṣoro lati gba alejo awọn ti ogun n le de.

Taylor sọ pe ko si ounjẹ, ko somi, eeyan bii 130,000 si 150,000 lo si ti sa wa Tawila bayii bo ṣe sọ.

Lọsẹ to kọja ni awọn eeyan to n sa kiri lati Zamzam, sọ fun BBC pe wọn ti dana sun ile awọn.

Awọn eeyan naa sọ pe wọn yinbọn mọ awọn pẹlu.

RSF ti wọn fẹsun kan sọ pe loootọ lawọn kọlu ibudo naa, ṣugbọn awọn ko ṣe iṣẹ ibi kankan.

Ìkọlù kò yéé tẹ́síwájú láwọn apá ibò mí-ìn ní Sudan

Ni Iwọ-Oorun Kordofan, eeyan mẹrinlelaadorin (74 ) ni RSF pa labule Al-Za'afah, bi awọn dokita to n ṣetọju nibẹ ṣe sọ lọjọ Ẹti.

O kere tan, eeyan 481 ni wọn ti pa ni Ariwa Darfur, lagbegbe El-Fasher, lati ọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin, bi UN ṣe salaye lọjọ Ẹti.

Wọn tilẹ sọ pe o ṣee ṣe ko ju bẹẹ lọ.

Volker Türk lati ajọ to n ri si ọrọ ọmọniyan ,sọ pe, o ti ṣoro lati ṣe aanu fawọn to nilo rẹ bayii.

O ni awọn eleto ilera funra wọn ti n koju idunkoko, wọn si ti kọlu ibi ti wọn ti n ri omi lo.

Bakan naa lo ṣalaye nipa bi wọn ṣe n fipa ba awọn obinrin lo pọ gan-an.

Ọdun keji ree ti awọn RSF ti n koju awọn ologun Sudan, eeyan ẹgbẹrun lọna aadọjọ ( 150,000) ni wọn ti pa.

Ko din ni miliọmu mẹtala eeyan ti wọn si ti fi ile wọn silẹ, ti wọn sa lọ patapata.

Awọn ajọ oluranlọwọ sọ pe ogun yii lo buru ju ninu itan ifiyajẹ ọmọniyan lagbaaye.