Perimenopause: Wo àwọn ọ̀nà mẹ́fà láti mójútó ìlera lásìkò tí nǹkan oṣù obìnrin ti fẹ́ dúró

Obinrin tó jókòó lórí àga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Perimenopause jẹ́ ìgbà tó ṣe kókó ní ìgbésí ayé obìnrin àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kò mọ̀
    • Author, Armen Nersessian
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Kó tó di pé nǹkan oṣù obìnrin kò ní wá mọ́ nígbà tí wọ́n bá dàgbà dé àyè kan, àwọn nǹkan kan tí máa ń kọ́kọ́ wáyé ní àgọ́ ara obìnrin.

Nǹkan yìí ni àwọn olóyìnbó ń pè ní "Perimenopause" tó sì máa ń dààmú ọ̀pọ̀ obìnrin àmọ́ wọ́n kìí sábà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò nímọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí àti ìlàkàkà tó máa ń wáyé fáwọn obìnrin lásìkò náà.

Ní àwọn agbègbè àtàwọn orílẹ̀ èdè kan, ó fẹ́ẹ̀ dàbí èèwọ̀ láti máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan oṣù obìnrin.

Perimenopause jẹ́ àsìkò tó máa ń wáyé ṣáájú kí obìnrin má tò rí nǹkan oṣù mọ́, nígbà tí àwọn ẹ̀yà ara obìnrin bá ń yípadà, táwọn ẹ̀yà ara tó wà fún ọmọ bíbí bá ń lọ sílẹ̀.

Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ẹ̀yà ara bíi oestrogen, progesterone, follicle-stimulating hormone (FSH), luteinising hormone (LH), àti testosterone kò bá ṣiṣẹ́ lbó ṣe yẹ́ mọ́.

Àwọn ayípadà yìí máa ń ní ipa lórí ara àti ìgbé ayé àwọn obìnrin pàápàá lórí ìgbòkègbodò wọn lójoojúmọ́.

Àwọn àpẹẹrẹ perimenopause, gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìlera ní UK, National Health Service, NHS, ṣe sọ ni:

  • Kí nǹkan oṣù máa ṣe ségesège
  • Kí èèyàn máa làágùn púpọ̀ ní alẹ́
  • Kí ọkàn èèyàn má papọ̀ sójú kan
  • Kí ó máa rẹ èèyàn láti inú
  • Àìrí oorun sùn dáadáa
  • Kí àtọ̀ obìnrin má wà á dáadáa
  • Kí ìbálòpọ̀ má wu obìnrin

Nígbà tí ọjọ́ orí obìnrin bá ti ń súnmọ́ ogójì ọdún lọ ní àwọn àmì yìí ti máa ń fojú hàn díẹ̀ díẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ obìnrin ló máa ń wọ ipò yìí nígbà tí ọjọ́ orí wọ́n bá ti ń lọ sí márùndínláàádọ́ta gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization ṣe sọ.

Níní ìmọ̀ nípa àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ lára lásìkò yìí àti gbígbé ìgbésẹ̀ ṣáájú rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà láti mú kó rọrùn fún èèyàn láti wọ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ètò ìlera kan máa ń ṣiṣẹ́ láti mójútó ìpele yìí fáwọn obìnrin kan, àwọn míì máa ń là á kọjá nípa ìgbé ayé ojoojúmọ́ wọn.

Àwọn ọ̀nà láti mójútó àwọn àmì perimenopause nìyí:

Jíjẹ oúnjẹ tí yóò máa ran hòmóònù lọ́wọ́

Àwòrán àwọn oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn oúnjẹ aṣaralóore máa ń ṣe ìrànwọ́

Jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ń ṣara lóore máa ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn ẹ̀yà ara tó ń rí sí nǹkan oṣù obìnrin.

Lára irúfẹ́ oúnjẹ tí obìnrin tó bá ti wà ní ipele le fi kún oúnjẹ ni:

Àwọn oúnjẹ tó bá ní èròjà phytoestrogen nínú bíi ẹ̀wà sóyà, èso, ẹ̀fọ́, ẹran tí kò ní ọ̀rá púpọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣíṣe eré ìdárayá

Àwòrán obìnrin tó ń ṣe eré ìdáráya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣíṣe eré ìdárayá máa ń mú kí ara jí pépé nítorí ó máa ń lékún "dopamine" nínú ọpọlọ.

Eré ìdárayá máa ń ṣe àtúntò sí ọpọlọ, tó sì máa ń mú ara yá gágá.

Èyí ṣe àfihàn ipa tí eré ìdárayá ń ní lórí ìlera ọpọlọ èèyàn.

Ìwádìí ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Exeter fi hàn pé àìṣe nǹkan oṣù mọ́ fún obìnrin kò ṣe ìdádúró fún èrèdí eré ìdárayá.

Mímú àdínkù bá wáhàlá ṣíṣe

Ṣíṣe wáhàlá púpọ̀ máa dákún àwọn àmì perimenopause tó fi mọ́ kí àárẹ̀ ọkàn àti àìrí oorun sùn dáadáa.

Ìwádìí ilé ìwòsàn Mayo Clinic kan lọ́dún 2019 fi hàn pé mímú àdínkù bá wàhálà ṣíṣe máa ń dín àwọn àmì àpẹẹrẹ perimonopause kù.

Lára àwọn nǹkan tí èèyàn lè ṣe ni mímí sókè sílẹ̀ lóòrè kóòrè, kíkọ ìwé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Sísùn dáadáa

Obìnrin tó wà lórí ibùsùn àmọ́ tí kò ì tíì sùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lásìkò perimenopause, àwọn obìnrin míì kìí rí oorun sùn dáadáa

Láti ṣe àmójútó oorun lásìkò perimenopause le nira díẹ̀ nítorí ẹ̀yà ara tó ń ṣokùnfà àìrí oorun sùn máa ń le díẹ̀ láti mójútó.

Oestrogen àti progesterone, tó jẹ́ ẹ̀yà ara tó máa ń ṣàmójútó oorun máa ń lọlẹ̀ gidi lásìkò perimenopause tó sì ṣòro láti ṣàwárí ìtọ́jú kan pàtó fún-un.

Bákan náà ni àwọn nǹkan míì bíi àyípadà sí bí èèyàn ṣe sùn látàrí ọjọ́ orí le mú àlékún bá ìṣòro àìrí oorun sùn dáadáa.

Àwọn nǹkan tó le ran oorun súnsùn lọ́wọ́ ni irú aṣọ tí èèyàn ń wọ̀ sùn àti ibùsùn tí èèyàn ń lò.

Ó dára láti máa wọ aṣọ àti ibùsùn tó jẹ́ aláṣọ dípò èyí tó jẹ́ ọlọ́ràá.

Níní àsìkò tí èèyàn dára púpọ̀ fún ẹ̀yà ara àti jíjìnà sí caffeine lásìkò tí èèyàn bá fẹ́ sùn.

Lílo àwọn èròjà ìbílẹ̀

Àwọn nǹkan ìbílẹ̀ bíi atalẹ̀ pupa, sya àtàwọn míì jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń lò láti fi kojú àwọn àmì àpẹẹrẹ perimenopause.

Àmọ́ àwọn onímọ̀ ìlera ṣèkìlọ̀ lórí bí wọ́n ṣe le ṣiṣẹ́ sí nítorí kò sí ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa wọn.

Ó dára láti kàn sí àwọn onímọ̀ ìlera ṣáájú kí èèyàn tó máa fi oògùn ìbílẹ̀ kún ti òyìnbó fún ààbò tó péye àti kí wọ́n le ṣe iṣẹ́ tó yẹ.

Kathy Abernethy, adarí ètò menopause fún Peppy sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló máa ń lo oògùn ìbílẹ̀ tí ìwádìí kò fi wọn múlẹ̀.

Ó tẹmpẹlẹmọ pé jíjẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore ni ọ̀nà tó dára jùlọ láti rí àwọn èròjà aṣaralóore àti pé Vitamin D àti calcium dára.

Níní àwọn èèyàn lára

Perimenopause le ní ipa tó pọ̀ lára táwọn onímọ̀ sì máa ń rọ àwọn èèyàn láti máa jíròrò pẹ̀lú ẹbí àti ọ̀rẹ́ lórí àwọn nǹkan tí èèyàn ń kojú.

Ó dára láti bèèrè fún ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ lórí àwọn ìlàkàkà tí èèyàn bá ń kojú lásìkò perimenopause.

Ìgbà wo lo máa ń fi wáyé?

Ọ̀pọ̀ ọdún ni perimenopause máa ń lò kó tọ lọ. Àwọn onímọ̀ sọ pé ó máa ń lò tó ọdún mẹ́rin sí mẹ́wàá.

Iye ìgbà tó máa fi pẹ́ sí máa ń dá lé ẹ̀yà ara, ìgbé ayé èèyàn àti ìlera.

Àmọ́ menopause ní tirẹ̀ ọjọ́ kan péré ni, ìgbà tí obìnrin kò ní ṣe nǹkan oṣù mọ́ fún odidi ọdún kan gbáko.

Ìwádìí ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan lọ́dún 2022 ìyẹn Study of Women Health Across Nation sọ pé àwọn obìnrin tó jẹ́ aláwọ̀dúdú ṣeéṣe kí wọ́n má tètè rí nǹkan oṣù mọ́ àti níní àwọn àmì àpẹẹrẹ tọ lágbára.

Ipa perimenopause pẹ̀lú ìbáṣepọ̀

Àwọn obìnrin mẹ́rfin tó ń rẹ́rìn-ín

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Perimenopause máa ń ní ipa lórí ìbáṣepọ̀ ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Shahrzad Pourabdollah, tó jẹ́ onímọ̀ ní ìbálòpọ̀ àti ìbáṣepọ̀ ní London sọ fún BBC pé perimenopause máa ṣe àkóbá fún ìbáṣepọ̀ yàtọ̀ sí ọkọ ẹni nìkan, tó fimọ́ àwọn ọmọ.

Ó ní ọ̀pọ̀ obìnrin ni kìí lè sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí wọ́n ń kojú tó sì máa ń fa ìpinyà púpọ̀.

Àmọ́ tó sọ pé pẹ̀lú ìpolongo àti sùúrù, àwọn lọkọlaya lè kojú ìṣòro yìí lásìkò náà.

Báwo ni èèyàn ṣe lè dá àmì perimenopause sí àìlera míì

Àwọn àmì àpẹẹrẹ perimenopause le farajọ àwọn àìlera bíi thyroid disorder.

Bí àpẹẹrẹ kí nǹkan oṣù máa ṣe ṣégeṣège le jẹ́ ti àyípadà ẹ̀yà ara tàbí ohun tí wọ́n ń pè ní thyroid imbalance.

Lílo àwọn áàpù tàbí kíkànsí ilé ìwòsàn jẹ́ ọ̀nà láti fi mọ́ bóyá perimenopause ni tàbí àìsàn míì.

Bákan náà ni àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ máa ń ṣàfihàn àìlera tó bá jẹ́ gan.