Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn méje, àwọn mẹ́rìndínlógún míì farapa

Ọ̀kadà ń gba ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ ńlá tó ṣubú lulẹ̀ kọjá

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kò dín ní èèyàn méje tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tawọn mẹ́rìndínlógún míì sì farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ kan tó wáyé ní agbègbè ìlú Essa ní òpópónà Agaie-Badeggi ní ìjọba ìbílẹ̀ Katcha, ìpínlẹ̀ Niger.

Ní nǹkan bíi aago mẹ́ta òru ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Karùn-ún ni ìjàmbá ọkọ̀ náà wáyé

Adarí àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Niger ìyẹn Niger State Emergency Management Agency, NSEMA, Abdullahi Baba-Arah ló kéde ìròyìn náà nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde Àìkú.

Baba-Arah ṣàlàyé pé ọkọ̀ ńlá kan tó kó àwọn oúnjẹ wooro tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ ni ìjàmbá náà kọlù.

Ó ní ọkọ̀ náà tún kó àwọn èrò mẹ́rìndínlógójì yàtọ̀ sí oúnjẹ tó kó àti pé láti ìpínlẹ̀ Eko ni wọ́n ti gbéra tí wọ́n sì ń ṣe ìrìnàjò lọ sí ìpínlẹ̀ Kano.

Ó ní ìgbàgbọ́ wà pé ọ̀nà Lambata sí Bida tí kò dára pàápàá láwọn ibi tí wọn kò ì tíì túnkọ́ ló ṣokùnfà ìjàmbá ọkọ̀ ọ̀hún.

Àwọn àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, tó fi mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ NSEMA, àwọn aráàlú, àwọn arìnrìnàjò ló gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí àwọn èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ tí ìjàmbá náà kọlù.

Baba-Arah fìdí rẹ̀ múlẹ̀, lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, é èèyàn méje ló ti jáde láyé, táwọn mẹ́rìndínlógún míì sì farapa.

Àwọn mọ́kànlá nínú àwọn tó farapa náà ni wọ́n ṣèṣe gidi nígbà tí àwọn márùn-ún yóòkù sì farapa díẹ̀ tí wọ́n sì ti ń gba ìtọ́jú ní àwọn ilé ìwòsàn ní Badeggi àti Agaie.

Bákan náà ni àwọn ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá náà ti gba òkú wọn lẹ́yìn ìjàmbá náà.

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Niger, Niger State Emergency Management Agency wá rọ àwọn ọlọ́kọ̀ pàápàá àwọn ọlọ́kọ̀ èrò láti máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lójú pópó pàápàá nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìrìnàjò alẹ́.

Bákan náà ló fi kun pé ìgbìyànjú ń lọ láti ṣe àwọn ọ̀nà tí kò dára ní òpópónà Lambata sí Bida ní kíákíá lati dènà irúfẹ́ ìjàmbá bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Ìjàmbá ọkọ̀ wọ́pọ̀ láwọn òpópónà ní Nàìjíríà tó sì jẹ́ pé onírúurú nǹkan ló máa ń ṣokùnfà rẹ̀.

Lára àwọn nǹkan tó máa ń fa ìjàmbá ọkọ̀ ni ọ̀nà tí kò dára, eré àsápajúdé látọwọ́ àwọn awakọ̀, gbígbé ọkọ̀ tí kò dára sọ́nà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.