Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àgbà òṣèré Yemi My Lover tó fi ké gbàjarè pé òun nílò ìrànlọ́wọ́?

Oríṣun àwòrán, yemimylover/Instagram
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá tó mi ìlú tìtì ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1990 sí ìbẹ̀rẹ̀ 1993, a ò lè ṣe láì má dárúkọ fíìmù Yemi My Lover.
Fíìmù náà gbajúmọ̀ fun orin àti àwọn nǹkan tó jọ mọ́ eré ilẹ̀ India èyí tí olóòtú eré náà, Yemi Ayebo fi jẹ́ kó yàtọ̀ sáwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá míì tó wà nígbà náà.
Àmọ́ olóòtú sinimá náà, Yemi Ayebo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Yemi My lover ti ké gbàjarè sáwọ ọmọ Nàìjíríà fún ìrànlọ́wọ́.
Yemi My lover, tó di ìlú mọ̀ọ́ká fún eré rẹ̀, Yemi My Lover tó gbé jáde lọ́dún 1993 ṣàlàyé àwọn ìlàkàkà tó ń kò lójú láti ìgbà náà.
Fíìmù Yemi My Lover gbajúmọ̀ láàárín ọdún 1993 tó jáde títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000 pẹ̀lú àwọn orin tí wọ́n kọ nínú fíìmù náà. Káàkiri ilẹ̀ Yorùbá ni fíìmù náà ti gbajúmọ̀.
Níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tí Yemi My Lover ṣe pẹ̀lú ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mr LilGaga tó wà lórí YouTube sọ pé òun kò rí owó lórí fíìmù ọ̀hún.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn alágbàtà fíìmù lọ ṣe ẹ̀dà sinimá náà, tí wọ́n sì ń tà á lọ́wọ́ ara wọn nítorí òun kò gbé fíìmù náà fún alágbàtà kankan láti bá òun tà á.
Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn alágbàtà òun ni wọ́n ń dẹ́yẹ sí òun, tí wọ́n sì ṣe ẹ̀dà fíìmù náà, tí ọ̀pọ̀ wọn sì fi àágùn owọ kó ọrọ̀ jọ.
Ó fi kun pé nǹkan kò ì tíì di ti orí ayélujára báyìí nígbà náà, fún ìdí náà òun kò ríbi pariwo fáráyé lórí àwọn nǹkan tí ojú òun rí lórí fíìmù ọ̀hún.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn olórin bíi Olamide ṣe lo lára fíìmù rẹ̀ náà láti fi ṣe orin, ó ní nǹkan ìdùnnú ló jẹ́ fún òun pé wọ́n lò lára fíìmù náà láti fi ṣe orin.
Ṣùgbọ́n ó ní kò dùn mọ́ òun bí Olamide kò ṣe kàn sí òun nígbà tó fẹ́ ya fíìmù fún orin náà.
"Mo lérò pé Olamide máa kàn sí mi pé kí n kópa nínú fídíò orin náà, ó dùn mí pé kò ṣe bẹ́ẹ̀.
"Mi ò rí Olamide rí láye mi, iInú mi máa dùn tó bá kàn sí mi lónìí, ó wù mí láti ri"
"Ó tó fíìmù mẹ́tàdínlógún tí mo ṣe lẹ́yìn Yemi My Lover àmọ́ mi ò rí èrè lára wọn"

Oríṣun àwòrán, Yemi Ayebo/Facebook
Yemi My Lover tún ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ fíìmù àgbéléwò ni òun ṣe lẹ́yìn tí òun rib í Yemi My Lover ṣe gbajúmọ̀ àmọ́ ìràwọ̀ àwọn fíìmù náà kò tàn bíi ti Yemi My Lover.
Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn fíìmù tí òun gbé jáde náà ló dára ju Yemi My Lover lọ àmọ́ àwọn èèyàn kò tẹ́wọ́ gbà wọ́n bíi Yemi My Lover.
Ó sọ pé òun máa ń dúpẹ́ fún Ọlọ́run pé òun wà láyé, tí òun sì wà ní àlááfíà àmọ́ nǹkan kò fararọ fún òun láti ìgbà náà.
"Lẹ́yìn Yemi My Lover, àwọn tí wọ́n máa ń ṣe ẹ̀dà fíìmù ṣàkóbá gidi fáwọn ffíìmù tí mo gbé jáde, èyí ló fa ìbẹ̀rẹ̀ àìsí owó lọ́wọ́ mi."
Bákan náà ló sọ pé ilẹ̀ òun tí òun rà lẹ́yìn tí òun ṣe fíìmù Yemi My Lover ni òun padà tà nígbà tí òun kò rí nǹkan jẹ mọ́.
Ó ní òun nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn akẹgbẹ́ òun láti lè ri pé òun padà sípò àti pé òun nílò ìbáṣepọ̀ wọn láti lè máa kóp nínú eré sinimá.
Ó sọ pé àwọn akẹgbẹ́ òun kìí pé òun sí iṣẹ́ wọn, tó sì jẹ́ pé òun gbàgbọ́ pé àwọn ni wọ́n lè sọ ìdí tí wọn kìí fi pé òun sí sinimá.
Àwọn àgbà òṣèré ń tọrọ fún ìrànlọ́wọ́
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí táwọn àgbà òṣèré yóò máa tọrọ ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn.
Ní ọ̀sẹ̀ yìí kan náà ni àgbà òṣèré, Jumoke George pariwo síta pé láti bíi ọdún mẹ́fà sẹ́yìn ni òun kò ti rí ilé gbé mọ́, tó sì jẹ́ pé ilé ìjọsìn kan ni wọ́n ti fún òun ní yàrá kan láti máa sùn.
Jumoke George tún sọ pé àkọ́bí ọmọ òun tún ti kúrò nílé láti ọdún mẹ́rin sẹ́yìn tó sì da ọmọ méjì sílẹ̀ fún òun láti máa tọ láti ìgbà náà.
Ó sọ èyí nígbà tó ń bá òṣèré mìíràn, Biola Adebayo sọ̀rọ̀ lórí ètò Talk to B tó sì sọ ọ̀pọ̀ ìlàkàkà tó ń là kọjá, tó sì sọ pé láti inú oṣù Kìíní ọdún yìí ni òun ti ń ṣàìsàn.
Yàtọ̀ sí Jumoke George, ọ̀pọ̀ àwọn àgbà òṣèré tí wọ́n ti kópa nínú eré fíìmù lásìkò ọdún 1990 sí ìbẹ̀rẹ̀ 2000 ni wọ́n sábà máa ń bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn aráàlú lórí ìpèníjà wọn.
Èyí máa ń mú awuyewuye dání, báwọn èèyàn ṣe máa ń kọminú pé kílódé táwọn ]oṣèré kìí ran ara wọn lọ́wọ́.
Ta ni Yemi My Lover?

Oríṣun àwòrán, yemimylover/Instagram
Òdú ni Yemi Ayebo, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Yemi My Lover láàárín àwọn eléré fíìmù tó gbajúmọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ 1990 sí 2000.
Ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹsàn-án ni wọ́n bí Yemi My Lover.
Ọmọ bíbí ìlú Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun ni.
Ọdún 1987 ló bẹ̀rẹ̀ eré sinimá àmọ́ ọdún 1993 ló di gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ nínú eré sinimá tó fun lórúkọ Yemi My Lover.
Ipa rẹ̀ dá yàtọ̀ lágbo eré fíìmù nígbà náà nítorí bó ṣe mú orin kíkọ bíi ti àwọn India wọnú eré Yorùbá.
Olùdarí eré àti olóòtú eré ni Yemi My Lover tó yi gba ọ̀kan-ò-jọ̀kan àmì ẹ̀yẹ lórí eré fíìmù.















