Ṣó o l'áyà! Ẹ wo bí Eniola Ajao ṣe fakọyọ lórí ètò tí BBC fi n dàn ìmọ̀ èdè Yorùbá wò

Àkọlé fídíò,
Ṣó o l'áyà! Ẹ wo bí Eniola Ajao ṣe fakọyọ lórí ètò tí BBC fi n dàn ìmọ̀ èdè Yorùbá wò

Gbajumọ oṣerebinrin, Eniola Ajao, kopa ninu eto Ṣo o laye lori BBC.

Eto Ṣo o laya ni awọn oṣere ati olorin, ti ma n fi bi wọn ṣe ni imọ nipa ede Yoruba - owe, aṣa, gbolohun, itan, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ibeere mẹwaa ni Arabinrin Eniola dahun ni abala yii, ẹ wo bo ṣe fakọyọ si ninu idahun wọn.

Eniola Ajao

Oríṣun àwòrán, Eniola Ajao

Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Eniola Ajao

Ilu Epe, nipinlẹ Eko, ni wọn ti bi Eniola Ajao. Ibeji si ni pẹlu.

O lọ si ile-ẹkọ Yaba College of Technology, ko to o lọ si Fasiti ilu Eko, University of Lagos nibi to ti gba iwe ẹri nipa iṣẹ iṣiro owo, accounting.

Eniola Ajao ti bi ọmọkunrin kan.

Ọdun 2004 lo bẹrẹ si ni ṣe fiimu, nigba to kopa ninu ere Ìgbà Aìmọ̀.

Diẹ lara awọn fiimu ti Eniola Ajao ti kopa

Ọpọlọpọ ere agbelewo ati ti sinima, ni Eniola Ajao ti ṣe. Diẹ lara wọn re e:

  • The Vendor
  • Yeye Alara
  • Wetin Women Want
  • Olokiki Oru(The midnight Sensation)
  • Ajebidan
  • Blackout
  • Ajibade
  • Wasila reloaded
  • Omoge carwash
  • Diety
  • Beast of Two Worlds - Ajakaju
  • Lakatabu
  • Lisabi: The Uprising
  • Owambe Thieves