Èèyàn 27 tún kú nínú ìjamba ọkọ̀ ojú omi ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkọ oju omi kan tun ti dojude loju agbami ni ipinlẹ Kwara to si tipasẹ bẹẹ ran weyan mẹtadinlọgbọn lọ sọrun.
Gẹgẹ bi ọrọ ti awọn ti ijamba ọkọ oju omi naa ṣoju wọn sọ, ero akoju kun ara ohun to ṣokunfa ijamba ọkọ to doju de laarin agbami naa.
Nnkan bii oṣu meje sẹyin ni irufẹ iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ to si gba ẹmi ọgọrun eeyan
Iroyin sọ pe, awọn ero ọja to n bọ lati ọja kan ti wọn lọ na ni ipinlẹ Niger lo kun inu ọkọ oju omi naa.
Ọkan lara awọn ti ori koyọ ninu ijamba ọkọ oju omi naa sọ pe ọwọ afẹfẹ iji lile kan to nbọ wa si ọgangan ọkọ naa lo da a nu si agbami.
Alaga ijọba ibilẹ Kaiama, Abdullah Danladi to lewaju ikọ olukẹdun kan lọ ba Emir ilu Kaiama, Alaaji Muazu Umar, at'awọn ẹbi awọn oloogbe ijamba naa ni ọrọ ijamba ọkọ ọlọdọọdun naa ti to gẹ bayii, ati wi pe, ijọba ko ni fi aye silẹ fun awọn ọbayejẹ to n fi aikiyesara gbẹmi awọn to n fi ọkọ oju omi ṣe irinsẹ.
Lara awọn ohun tuntun to ni ijọba fẹ bẹrẹ si ni ṣiṣẹ le lori ni lilo aṣọ amunilefo lori omi, fidofin de irinajo alẹ at'awọn igbesẹ miran.
Loṣu kẹwaa ọdun 2024 ni irufẹ ijamba ọkọ oju omi bayii waye lagbegbe ileto Gbajibo lagbegbe aala ipinlẹ Kwara ati Niger, to si gba ẹmi eeyan ọgọta, ninu eyi ti ọgọrọ awọn ọmọde pẹlu awọn obinrin ti jade laye
Ọkọ oju omi ibilẹ naa to lagbara lati ọgọrun ero lọ ree ko ọdunrun eniyan lọjọ naa ki o to doju de.
Aarẹ Tinubu paapaa ti kẹdun pẹlu awọn eeyan agbegbe naa at'awọn mọlẹbi awọn to ku ninu ijamba ọkọ oju omi naa.
Bakan naa laarẹ tun ke si ajọ irinna oju omi ni Naijiria, (NIWA) lati ṣe iwadii ohun to sokunfa ijamba ọkọ oju omi naa















