Àgbàrá òjò wọ́ ọlọ́kadà lọ ní Eko, wọ́n rí òkú rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti kéde pé àwọn ti ṣàwárí òkú ọkùnrin kan tó jẹ́ ọlọ́kadà tí àgbàrá òjò gbé lọ.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin fi léde lọ́jọ̀bọ̀ ṣàlàyé pé, ọkùnrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wasiu Babatunde Adeniran ni àgbàrá òjò wọ́ lọ nígbà tí òjò ńlá kan rọ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ogúnjọ́, oṣù Karùn-ún.
Ní agbègbè òpópónà márosẹ̀ Eko sí Abeokuta, Alakuko, ìpínlẹ̀ Eko ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Ìròyìn ní Adeniran, ẹni ọgọ́ta ọdún pàdánù ìjánu ọ̀kadà rẹ̀ nínú òjò ńlá náà, tí àgbàrá òjò náà sì wọ́ ohun àti ọ̀kadà rẹ̀ lọ.
Àtẹ̀jáde iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé "Adeniran ṣubú lórí ọ̀kadà tó ń gùn, tí àgbàrá òjò sì gbé ọ̀kadà náà lọ."
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàlàyé pé ojú ẹsẹ̀ ni ìgbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí Adeniran àti ọ̀kadà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àmọ́ ọ̀kadà nìkan ni àwọn ṣàwárí ní nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.
Wọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ni wọ́n tó rí òkú Adeniran.
Hundeyin fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ Ọjọ́rú, ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Karùn-ún ni wọ́n ṣàwárí òkú Adeniran nínú odò Obasanjo River tó wà ní Ota, ìpínlẹ̀ Ogun.
Àwọn ọlọ́pàá lọ sí ibẹ̀ láti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn ohun tí ojú wọn rí níbẹ̀ láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìwádìí.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ṣàlàyé pé wọ́n ti gbé òkú Adeniran lọ sí mọ́ṣúárì fún àyẹ̀wò lẹ́yìn tí wọ́n ya àwòrán rẹ̀ tán.
Bákan náà ló ní ìwádìí ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ní ìfarajìn sí ṣíṣe ìwádìí tó lóòrìn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì bá àwọn ẹbí olóògbé dárò lórí àdánù wọn.















