Sunday Igboho: Títí di àkókò yìí, ìjọba àpapọ̀ ṣì ń wá mi kiri

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajijagbara fun ominira ilẹ Yoruba, Sunday "Igboho" Adeyemo ti sọ pe oun ṣi wa lara awọn ti ijọba Naijiria n wa kiri.

Igboho tun fi oko ọrọ ṣọwọ si adari igbimọ ipolongo ibo Aarẹ Bola Tinubu tẹlẹ, Naja'atu Mohammed, latari bo ṣe sọ pe ọdaran ti wọn n wa ni oun amọ n yan fanda kaakiri.

Gẹgẹ bi awọn iroyin kan, ajọ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS, sọ pe oun n wa Igboho lori ẹsun pe oun n ko ohun ija oloro pamọ.

Ṣaaju ni Naja'atu Mohammed ti kọkọ sọ pe ojuṣaju wa ninu ọwọ ti ijọba Tinubu fi n mu awọn afurasi ni Naijiria.

O ni ijọba ko sọ nnkankan mọ nipa ọrọ Sunday Igboho amọ ko sinmi lati maa ba Nnamdi Kanu ṣe ẹjọ.

Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti Igboho fi lede, o ni ọrọ ti Naja'atu sọ ko mu ọgbọn dani.

Atẹjade naa ni "Ijọba apapọ ṣi n wa mi bo tilẹ jẹ Tinubu ni Aarẹ Naijiria bayii."

Igboho kilọ fun Naja'atu pe ko ṣọra ni dida orukọ oun ninu ọrọ rẹ lọna ati tako ijọba Tinubu.

O ni "Lọwọ yii, iwe irinna Germany mi ni mo fi n rinrinajo kaakiri ilẹ Europe atawọn orilẹede mii bayii, mi o si le wọ Naijiria lẹyin ti ijọba ana ti Muhammadu dari rẹ ni oun n wa mi.

"Titi di akoko yii, aṣẹ lati maa wa mi ṣi wa lode.

"Ki ni ẹṣẹ mi gan? Nitori pe mo sọrọ soke tako bi wọn ṣe n pa awọn agbẹ ni ipakupa ti won si n fi ipa ba awọn obinrin wa lopọ laye ijọba Aarẹ Buhari."

Igboho ni ọjọ kini, oṣu Keje ọdun 2021 ni ajọ DSS yabo ile oun pẹlu oninruru ohun ija ogun lọna ati gbẹmi oun amọ Eledua lo ko oun yọ lasiko ti iro ibọn dun lakọlakọ fun odidi wakati mẹrin.

Lẹyin naa lo bẹrẹ lọwọ Naja'atu ibi to wa lasiko ti awọn Fulani darandaran n gbẹmi awọn agbẹ kaakiri Naijiria.

Igboho pari ọrọ rẹ pe igbeṣe Tinubu lati koju eto abo to mẹhẹ lai lo awọn eeyan bii Gumi lo mu ki Naja'atu maa sọ isọkusọ nipa oun.