Ilé-ẹjọ́ pàṣẹ iṣẹ́ àṣekára fún olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ ní DR Congo nítorí ìwà àjẹbánu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé-ẹjọ́ kan ní orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo, DR Congo, ti ní kí wọ́n fi ipá mú olóòtú ìjọba orílẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ rí, Augustin Matata Ponyo láti ṣiṣẹ́ ìlú fún ọdún mẹ́wàá fún ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ogúnjọ́, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 ni ilé-ẹjọ́ Congolese Constitutional Court ní Ponyo jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí iye rẹ̀ tó $245m tó jẹ́ owó ìlú.
Bákan náà ni wọ́n tún ní kí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí fún ilé ìfowópamọ́ àgbà orílẹ̀ èdè náà, Deogratias Mutombo náà ṣe iṣẹ́ ipá fún ọdún márùn-ún.
Agbẹjọ́rò Ponyo sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Reuters pé ìdájọ́ náà kò dára tó àti pé ó lọ́wọ́ òṣèlú nínú.
Ilé-ẹjọ́ ní lára àwọn owó tó wà fún ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbìn láti kojú ìṣòro ọ̀wọ́ngógó ounjẹ tó ń kojú orílẹ̀ èdè náà ni wọ́n ti kó owó náà jẹ.
Ponyo ṣe olóòtú ìjọba DR Congo láàárín ọdún 2012 sí 2016, tó sì ti di adarí ẹgbẹ́ òṣèlú Leadership and Governance for Development, LGD.
Kí ó tó di olóòtú ìjọba, ó ti ṣe mínísítà fétò ìsúná tí wọ́n sì kan sáárá si fún bí ó ṣe lo owó tó gbà láti àjọ International Monetary Fund láti fi mú ìdúró ire bá ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè náà.
Deogratias Mutombo, gómìnà tẹ́lẹ̀ rí fún ilé ìfowópamọ́ àgbà tí òun náà rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún hé kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ìdájọ́ náà.
Fífi ipá múni láti ṣe iṣẹ́ àṣekára bá òfin mú ní orílẹ̀ èdè DR Congo nígbà tí ilé ẹjọ́ bá gbé ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ kalẹ̀.
Àwọn méjéèjì ni wọ́n ti fòfin dè láti máa kópa níbi iṣẹ́ ìlú fún ọdún márùn-ún láti ìgbà tí iṣẹ́ wọn ti parí gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn AFP ṣe sọ.
Ponyo, ẹni tó ṣe ìpolongo tako ààrẹ DRC, Felix Tshisekedi níbi ètò ìdìbò ọdún 2023 kó tó yọwọ́ níbi ètò ìdìbò náà, ti jiyàn àwọn ẹ̀sùn náà lọ́pọ̀ ìgbà.
Láti ọdún mẹ́rin ni wọ́n ti wà lórí ìgbẹ́jọ́ náà lẹ́yìn tí adarí ètò ìsúná àpapọ̀ ti kéde ìwà àjẹbánu tó wáyé níbi àkànṣe iṣẹ́ Bukanga-Lonzo Agro-Industrial Park lọ́dún 2020.
Iléeṣẹ́ ìròyìn Reuters ní páàkì náà ni ìdókoòwò lẹ́ka ètò ọ̀gbìn tó tóbi jùlọ ní Africa àti pé ilé ìfowópamọ́ ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbìn, African Development Bank Group ti gbèrò pé okoòwò náà máa pèsè iṣẹ́ tó tó 22,000.
Èròńgbà tí wọ́n fi gbé àkànṣe iṣẹ́ ètò ọ̀gbìn náà kalẹ̀ ni láti ṣe ìtùnú fáwọn èèyàn bí mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n tó ń kojú àìsí oúnjẹ ní DR Congo èyí tí ìpànìyàn Rwanda ọdún 1994 ṣe okùnfà rẹ̀.












