Àwọn kókó tó wà nínú àbádòfin ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba tí Ilé aṣòfin Oyo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/ X
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti yi ohùn pada lori aba ti wọn da ṣaaju lati sọ Alaafin di alaga awọn ọba ipinlẹ naa laelae.
Aba to ṣaaju naa fẹ ki Alaafin Oyo maa jẹ alaga titi aye labẹ ofin, ki Olubadan ati Soun Ogbomoso si maa pin ipo Igbakeji alaga ọhun.
Ṣugbọn lanaa, ogunjọ oṣu Karun-un ọdun 2025, ile igbimọ naa fẹnuko lati jẹ ki Alaafin, Olubadan ati Soun Ogbmoso maa pin ipo alaga naa bo ṣe wa tẹlẹ.
Ki yoo si fun Alaafin nikan rara.
Eyi waye lẹyin ti Igbakeji alaga igbimọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Bamidele Adeola, jẹ abọ ifikunlukun wọn.
Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni aba naa wọ ipele keji nile igbimọ aṣofin Oyo.
Ijokoo ọjọ Iṣẹgun yii lo si jẹ ikẹta ati asọkagba lori rẹ.
Ile igbimọ naa tun buwọlu iyansipo awọn alaga mẹtala mi-in, titi to fi mọ Ọtun ati Osi Olubadan.
Labẹ atunyẹwo keji, wọn gbe ipo Igbakeji alaga fun Eleruwa ti Eruwa, Olugbon ti Orile-Igbon ati Aseyin ilu Iseyin pẹlu awọn miran.
Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Oyo, Adebo Ogundoyin, sọ pe imugbooro awọn ipo yii yoo jẹ ki awọn olori le ṣoju agbegbe wọn kaakiri ipinlẹ Oyo.
O ni yoo jẹ ki iṣẹ idagbasoke ya kankan laaarin igbimọ, yoo mu iṣọkan wa laaarin awọn oriade, yoo si ro ijọba lagbara lawujọ ladelade.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ aṣofin ati awọn eeyan Ibadan, Ogbomoso pelu awon ilu mi-in nipinlẹ Oyo lo faramọ ipinnu tuntun lori aba yii, awọn aṣofin meji tako o, wọn si binu jade lasiko ti ipade naa n lọ lọwọ.
Àwọn wo ló ń bínú?
Ọnarebu Gbenga Oyekola to n ṣoju ẹkun Atiba ati Ọnarebu Rahman Olorunpoto to n ṣoju Oyo East/West, lo binu jade nile igbimọ lasiko ipade naa.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ranpẹ to ṣe pẹlu awọn akọroyin lori ipinnu ile igbimọ, Ọnarebu Rahman sọ pe
"O yẹ ka maa lo otitọ ninu ofin yoowu ta a ba n ṣe. Gbogbo wa la mọ ipo Alaafin, a si mọ ohun ti itan wi.
" Olori ọba ni Alaafin, ko si yẹ ka maa ṣofin nitori irọrun oṣelu.
"Ofin to le koju igba, to le duro pẹ lo yẹ ka maa ṣe. Ofin to ba itan mu lo yẹ ka maa ṣe.''
Ọnarebu Rahman fi kun un pe igbesẹ tile igbimọ gbe lori ọrọ yii ko tẹ awọn lọrun.
O ni ko sibi kan ti wọn ti pepade apero ṣaaju lati jẹ ki araalu sọ ero ọkan wọn, wọn ko pe ẹnikẹni lati Oyo lati waa sọrọ lori aba naa.
Eyi ko dun mọ ọ ninu rara gẹgẹ bo ṣe sọ.
Yatọ si awọn aṣofin yii, awuyewuye tun n waye lati awọn ẹka mi-in naa ti ipinnu ile igbimọ ko dun mọ.
Wọn ni Oyo lagba, ko si yẹ ki Alaafin maa ba Olubadan ati Soun Ogbomoso du ipo alaga igbimọ lọbalọba rara.
Ṣugbọn awọn kan n sọ pe bi Alaafin ba fi di alaga bẹẹ titi aye, a jẹ pe awọn ilu bii Ibadan, Ogbomoso, Oke-Ogun ati bẹẹ bẹẹ lọ ko ni i lẹnu-lọrọ ipinlẹ wọn mọ laye.
Wọn ni ko ma baa ri bẹẹ ni awọn aṣofin ṣe ni ki ipo naa jẹ pinpin bo ṣe wa latilẹ, ti wọn si tun ṣafikun awọn oloye mi-in si.
Wọ̀nyí ni díẹ̀ nínú àwọn Ọbalaye ti yoo wa ninu igbimọ naa

Oríṣun àwòrán, OTHERS
- Alaafin Oyo
- Olubadan
- Soun Ogbomoso
- Eleruwa -Eruwa
- Olugbon -Orile-Igbon
- Okere -Saki
- Aseyin- Iseyin
- Onpetu- Ijeru
- Aresaadu- Iresaadu
- Iba -Kisi
- Onjo- Okeho
- Onikoyi - Ikoyi-lle
- Sabiganna - Iganna
- Balogun -Ibadan
- Otun Olubadan
- Olu -Igboora
- Basorun - Oyo
- Otun Balogun - Ibadan
- Osi Olubadan
- Alajaawa -Ajaawa
- Onidere -Idere
- Asigangan - Igangan
- Onigbeti - Igbeti
- Alepata/Ona Onibode/ Onigboho Onighope yoo maa pin ipo naa lọdun meji-meji lati ṣoju ijọba ibilẹ Oorelope.
- Ati bẹẹ bẹẹ lọ.














