Mọ́gàjí Ogbomoso àti Ibadan tako àbá láti sọ Alaafin di alága láéláé ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba Oyo

Aworan Olubadan, Alaafin ati Soun

Oríṣun àwòrán, Soun of Ogbomoso Land/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Awuyewuye ko tii tan lori aba ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo lati sọ Alaafin Oyo di alaga laelae igbimọ lọbalọba ipinlẹ naa.

Ṣaaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti bẹrẹ igbesẹ lati mu atunṣe ba ofin igbimọ lọbalọba ati ijoye nipinlẹ Oyo.

Ninu iwe ofin lọbalọba ti ọdun 2000, Alaafin ni olori igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo pẹlu aṣẹ lati ọwọ ijọba lati dari ipade ati awọn nnkan mii .

Ṣugbọn lasiko iṣejọba Gomina Adebayo Alao Akala, atunṣe ba ofin naa lọdun 2011, ti wọn si yi ofin ọhun pada si pe ki awọn Ọba ma pin ipo alaga jẹ.

Ipo naa wa laarin Alaafin Oyo, Olubadan ti ilẹ Ibadan ati Soun Ogbomoso.

Amọ, awọn Mọgaji idile marun un to n jẹ Soun Ogbomoso ati Mọgaji ilu Ibadan ti tako aba naa, wọn ni pinpin lo yẹ kawọn maa pin oye alaga lọbalọba ipinlẹ Oyo laarin Alaafin Oyo, Olubadan ti ilẹ Ibadan ati Soun ilu Ogbomoso

Awọn Mọgaji Ogbomoso tako igbesẹ lati sọ Alaafin di alaga igbimọ lọbalọba Oyo

Awọn Mọgaji lati awọn idile marun un to n jẹ Soun ilu Ogbomoso ti tako aba lati ṣatunṣe ofin igbimọ lọbalọba ipinlẹ Oyo eyi to wa niwaju ile lati sọ Alaafin Oyo di alaga laelae igbimọ naa.

Ninu atẹjade kan tawọn Mọgaji marun un ọhun, Ọmọba Olawuyi Itabiyi (Aburumaku), Ọmọba Sikiru Oyeyiola (Gbagun), Ọmọba Amos Olawole Olaoye (Laoye), Ọmọba Samuel Oyebamiji Oyedeji (Bolanta) ati Ọmọba Stephen Ilufoye Layode (Odunaro) fi sita ni wọn ti sọ pe igbesẹ yii tako itan awọn lọbalọba nipinlẹ Oyo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn Mọgaji Ogbomoso ni aawọ ni igbesẹ si yoo da silẹ, wọn ni ijọba apaṣẹ waa Oyo Ile ti pari lati ọdun 1837 nigba tawọn Fulani wo ijọba naa lulẹ.

Wọn ni lẹyin ti Oyo Ile wo lulẹ tan ni iṣejọbamii ti bẹrẹ titi di akoko yii.

''A koro oju si igbesẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo lori atunṣe ofin lọbalọba ipinlẹ Oyo eyi ti wọn fẹ lo lati sọ Alaafin di alaga laelae igbimọ lọbalọba.

Igbesẹ yii tako ohun ti itan sọ, Oyo ni itan ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin lai ṣe ani ani, amọ, o ṣeni laanu pe gbogbo agbara ijọba Oyo Ile ti dopin lodun 1837 nigba ti awọn Fulani jagun ṣekun nibẹ.

Itan tuntun mii bẹrẹ nigba tawọn oniruuru ijọba n dide lẹyin ti Oyo Ile tuka, itan yii si wa di ọjọ oni.

Itan yii lo si yẹ kawọn lọbalọba maa tẹle lati yan olori laarin wọn.

Agbara Oyo ti dopin lati igba ti Oyo-Ile ti Alaafin Oranmiyan da silẹ wo lulẹ,'' awọn Mọgaji Ogbomoso lo sọ bẹẹ.

Awọn Mọgaji Ogbomoso ni ko yẹ ki ojuṣaaju wa ninu ọrọ naa raa tori Ọmọba Atiba lo da Oyo tuntun to wa di oni silẹ lọdun 1875.

Koda, awọn Mọgaji naa tun sọ pe Ogbomoso lo ni ilẹ ti Oyo wa lori rẹ lonii.

Awọn Mọgaji naa tun ṣalaye bii Ooni ṣe maa n rawọ ẹbẹ si Ogbomoso ati Ibadan lati fawọn eayan Oyo nilẹ ti wọn le tẹdo si lẹyin ti Oyo wo lulẹ.

''Awọn eeyan lati Oyo Ile n lọ lati ibikan si omiran ni Oke Ogun ki wọn to debi ti wọn wa lonii.

Koda, Ogbomoso lo daabo bo ilẹ ti wọn wa lori rẹ lonii laye igba naa.

Awọn Mọgaji ni Alaafin Oranmiyan ni aarẹ abaṣẹ waa kii ṣe Atiba to da Oyo tuntun silẹ.

Lai deena pẹnu, awọn Mọgaji Ogbomoso duro lori ẹsẹ wọn pe ki Alaafin, Olubadan ati Soun maa pin oye alaga igbimọ lọbalọla ipinlẹ Oyo lọ.

Wọn ni eyi ti waye tẹlẹ ri, ati wi pe Soun to waja, Oba Oladunni Oyewumi Ajagungbade Kẹta gan an ti jẹ alaga igbimọ naa sẹyin.

Awọn Mọgaji naa wa rọ ile igbimọ aṣo ipinlẹ Oyo lati ma ṣe ohun ti yoo tako itan to wa nilẹ.

Apapọ ẹgbẹ ọmọ Ibadan, Mogaji tako igbesẹ lati sọ Alaafin di alaga laelae fun igbimọ lọbalọba Oyo

Ṣaaju ni a ti mu iroyin kan wa fun yin pe ẹgbẹ gbogbo ọmọ bibi ilẹ Ibadan CCII, Mogaji ilẹ Ibadan, Baalẹ ati Ọba ni wọn ti dide tako igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati sọ Alaafin ti ilu Oyo di alaga laelae fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.

Bakan naa ni ẹgbẹ ọmọ Ibadan tun ṣe ikilọ fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo pe, ki wọn mase da rogbodiyan silẹ, ti wọn si tẹnu mọ pe ipo alaga igbimọ lọbalọba jẹ ipo ti wọn ma n pin jẹ, ki ṣe fun eeyan kan ṣosọ.

Ninu atẹjade ti Aarẹ Mogaji ilẹ Ibadan, Mogaji Nurudeen Akinade fisita, Ibadan ko fi igba kankan jẹ igbakeji si Oyo ṣugbọn o wa fun aabo gbogbo ilẹ Yoruba.

Akinade ni igbala Ibadan tobi, to si ti gba ilẹ Yoruba silẹ ni ọpọ igba.

O tẹsiwaju pe ti Ibadan ko ba ṣe idaduro fun awọn Fulani lasiko ogun Fulani, ọpọ ilẹ Yoruba ni yoo jẹ pe Emir ni yoo maa jẹ ni ilu wọn.

"Oloye Obafemi Awolowo ko le di olori ijọba iwọ oorun Naijiria ti ki i ba ṣe ti awọn ọmọ Ibadan to fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Action Group (AG) lati koju NCNC ti Nnamdi Azikwe.

"Ibadan ti n gba ilẹ Yoruba silẹ fun ọjọ pipẹ, ko si igba kankan ti a jẹ ipo keji si Oyo tabi ilu kankan nilẹ Yoruba, koda Ibadan lo yẹ ko jẹ alaga laelae fun igbimọ lọbalọba.

"Nitori a ko sọrọ ko tumọ si pe a ya oponu rara.

Nigba ti Ibadan ko ja fun ipo Alaga laelae, ki lo de ti Oyo fi fẹ ṣe bẹẹ? Ile igbimọ aṣofin yoo da ara wọn ni ẹbi ti abadofin yii ba di ofin.

"Gomina nigba kan ri, Christopher Alao Akala lo bu wọlu ki ipo alaga lọbalọba jẹ pinpin lasiko iṣejọba rẹ.

Oba Samuel Odulana Odugbade, si lo jẹ alaga fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.

Ibadan ko ni tẹwọgba aba yii rara nitori awa ni a maa n siwaju ninu gbogbo nnkan."

"Alaafin nifẹ si igbesẹ ile aṣofin Oyo, to si fọwọ si i pẹlu''

Ṣaaju ni Alaafin Oyo, Oba Akeem Ọwọade ti ni inu oun dun pupọ, ti oun si fọwọ si igbesẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo lati sọ Alaafin di alaga laelae fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.

Agbẹnusọ fun oriade naa, Bode Durojaye lo sọ eyi di mimọ lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.

Durojaye ni iwọsi nla lo jẹ fun Alaafin lati ma pin ipo alaga jẹ pẹlu awọn Oba to ku nitori Alaafin ki I ṣe ẹni Arifin rara.

"Igbesẹ nla ni eyi jẹ nitori abuku nla ni ki Alaafin maa ba Ọba miiran ma pin oye jẹ.

Ọwọ nla lo yẹ ki a fun Alaafin.

"Alaafin nifẹ si igbesẹ yii, to si fọwọ si pẹlu.

Alaafin nikan lo lẹtọ lati jẹ alaga lọbalọba nipinlẹ Oyo, ti a ba wo o lati ibi itan ati agbara."

Ninu ọrọ rẹ, Durojaye ni pẹlu itan adayeba, ko si Ọba kankan nipinlẹ Oyo to le fi ẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu Alaafin nibikibi.

O ni awọn ilu yoku to n fariga lori igbesẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, ni ẹtọ lati ṣe bẹẹ ṣugbọn o ni ko si ẹnikẹni ninu wọn toto bẹẹ lati gbena woju Alaafin Oyo.

"Ta a gan lo kaju ẹ lati gbena wo oju Alaafin.

Wọn ni ẹtọ lati fi ẹdun ọkan wọn han sita lori abadofin ṣugbọn otitọ ni pe Alaafin ni olori fun awọn lọbalọba nigba kugbakugba.

"Emi ko ri pe igbeṣẹ yii le fa wahala nipinlẹ Oyo, ṣugbọn ẹ ma jẹ ka fi ọrọ si abẹ ẹnu sọ.

Ewo ninu awọn Ọba nipinlẹ Oyo lo ni irufẹ ifẹ apọnle ti alaafin ni, ṣe Olubadan, Soun tabi Olugbon ni,'' Ọgbẹni Durojaye lo sọ bẹẹ.