Ìdí tí mo fi sunkún nígbà tí MKO Abiola jáde láyé - Alake ilẹ̀ Ẹ̀gbá

Àkọlé fídíò, Ìdí tí omi fi sunkún nígbà tí MKO Abiola jáde láyé - Alake ilẹ̀ Ẹ̀gbá
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọba Adetoun Gbadebọ ni Alake kẹwaa fun ilẹ Ẹgba lẹyin to gun ori itẹ awon baba rẹ ni ọjọ keji oṣu kẹjọ ọdun 2005 tii ṣe ogun ọdun sẹyin.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Kabiyesi Alake ṣalaye pe lootọ ilu Ẹgba ti bi oniruuru awọn akọni ọmọ ti wọn ti di awokọṣe lagbaye. O ni eyii kun ara itakun idagbasoke ilu Ẹgba.

Aworan Ọbasanjọ, Abiọla ati Earnest Shonekan

O salaye siwaju sii pe lara awọn eekan ọmọ ilu Ẹgba ni Oloogbe MKO Abiola wa, ẹni ti gbogbo agbaye gba pe oun lo bori idibo aarẹ odun 1992 eyi ti ijọba ologun igba naa wọgile.

Nigba ti o n ṣe alaye idi ti omije fi bọ loju rẹ nigba naa, Alake ilu Ẹgba ni oun woye pe, nigba ti Ọlọrun mọ pe Abiola ko ni pada wa aile laaye, ki lo de ti ko fi gba ẹmi rẹ ṣaaju.