Ogún Naira ni mo gbà fún Sinímá Ọ̀pá Ajé tó sọ mí di olókìkí – Àjan Abija

Àkọlé fídíò, Ogún Naira ni mo gbà fún Sinímá Ọ̀pá Ajé tó sọ mí di olókìkí – Àjan Abija
Ogún Naira ni mo gbà fún Sinímá Ọ̀pá Ajé tó sọ mí di olókìkí – Àjan Abija

Ọkan gboogi oṣere sinima agbelewo aye atijọ, Alhaji Adeyẹmi Sikiru ti ọpọ eeyan mọ si "Ajan Abija" ti ke gbajare lori awọn ipenija to n ba a finra lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti o ti fi oju han ninu awọn sinima agbelewo to kale-kako.

Ninu ọrọ ti o ba BBC Yoruba sọ, Sikiru ni oun ko mọ wi pe dandan ni ki olokiki ni owo lọwọ tabi ki o ko ọrọ jọ lasiko ti oun n bẹ lẹnu iṣẹ tiata.

Ọkan lara awọn ere to sọ Alhaji Sikiru di olokiki nigba naa lọhun ni sinima kan ti wọn pe ni Ọpa Aje ninu eleyii ti o ti kopa gẹgẹ bii Ajan Abija

Ogun Naira ni mo gba fun sinima Ọpa Aje to sọ mi di Olokiki – Ajan Abija

Ajan Abija

Alaye to ṣe fun akoroyin wa ni pe ogun Naira pere ni oun gba lori sinima naa, nitori ilepa owo tabi ọrọ ko si ni ọkan oun ni gbogb asiko yii.

Wọn maa n saba kun arakunrin yii ni ẹfun ninu awọn ipa to ko ninu sinima, eyii lo si faa to fi nira fun ọpọlọpọ eeyan lati daa mọ.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe inu ipenija nla ni oun wa bayii, nitori pe awọn iṣẹ idọti ni oun n ṣe bayii nitori atijẹ, bẹẹ sini alaafia ara oun tun ti di fiafia.