Mi ò mọ̀ pé mo lè dé ipò ọba - Owa Obokun tuntun Ilẹ̀ Ijẹsa

Oríṣun àwòrán, Kabiyesitv/Facebook
Ori to maa dade ko ni ṣai dade, Ọwa Obokun Adimula tuntun ti ilẹ Ijesa, Ọba Clement Adesuyi Haastrup, Ajimoko Kẹta, ti sọ pe oun ko lero wi pe oun le de ipo ọba lọjọ kan.
Ọba Haastrup ti ayẹyẹ gbigba ade rẹ yoo waye lọjọ kẹtalelogun oṣu Karun un yii fidi ọrọ yii mulẹ nibi apejẹ kan ti alaga igbimọ to n ri ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ naa, Ọjọgbọn Wale Omole, ṣe agbekalẹ rẹ.
Nigba ti o n sọrọ níbi apejẹ ọhun, Ọba Haastrup sọ pe "mi o mọ pe iru ọjọ yii le dé, gbogbo igba ti mo ti n wale sẹyin lati ṣe iranwọ fawọn araalu ni mo maa n sọ fun wọn pe mi o ṣe nnkan ti mo n ṣe ki n le jẹ gomina tabi di ọba.
Mo kan n ran awọn eeyan lọwọ lati mu inu wọn dun ni, mi o mọ pe mo le pada wa a jọba."
Ọwa Obokun fi asiko naa dupẹ lọwọ Eledua at'awọn eeyan ilẹ Ijesa fun anfaani ti wọn fun un lati sin wọn gẹgẹ bii ori ade.
Ọba Haastrup wa kepe gbogbo ọmọ Ijesa nile ati lẹyin odi wi pe ki wọn fọwọ sowọ pọ pẹlu oun fun idagbasoke ilẹ Ijesa.
"O yẹ kí gbogbo wa mọ pe iṣẹ n bẹ niwaju wa, gbogbo wa gbọdọ ṣetan lati gbe ilẹ Ijẹsa ga.
O dami loju pe gbogbo ọmọ Ijẹsa nile ati lẹyin odi lọ ní nnkan amuyẹ lati gbe ilẹ wa ga, ọjọ rere si wa niwaju wa," Ọwa Obokun lo sọ bẹẹ.
Ọba Haastrup ko ṣai dupẹ lọwọ igbimọ to n sagbatẹru ayẹyẹ gbigba ade rẹ eyi ti Ọjọgbọn Omole, Ọga agba ile ẹkọ giga fasiti OAU tẹlẹri, jẹ alaga rẹ.
Ọba Haastrup ni "lati igba ti mo ti orukọ awọn to wa ninu igbimọ ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ ni ọkan mi ti balẹ tori pe Ọmọluabi ni gbogbo wọn.
Mo si gbagbọ pe wọn o ṣiṣẹ takun takun ti eto naa yoo fi k'ẹsẹ jari," Ọba Haastrup ṣalaye.
Gbogbo ọmọ Ijẹsa lo ti di ọmọ mi bayii - Ọwa Obokun
Ọwa Obokun wa sọ pe gbogbo ọmọ Ijẹsa lo ti di ọmọ oun bayii.
Ẹwẹ, Ọjọgbọn Omole dupẹ lọwọ Eledua fun iyansipo Ọba Haastrup gẹgẹ bii Ọwa Obokun kọkanlelogoji ilẹ Ijẹsa.
Ọga agba ile ẹkọ giga fasiti OAU tẹlẹri ni idunnu lo jẹ foun pe Ọba Haastrup gori itẹ awọn baba nla rẹ loju aye oun.
Ko ṣai dupẹ lọwọ awọn ọmọ igbimọ yoku fun ipa ribiribi ti wọn n ko lati ri pe ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ naa lọ bo ṣe yẹ ko lọ.
Ninu ọrọ tiẹ, Ajirowa ilẹ Ijẹsa, Alhaji Lateef Bakare, tó tun jẹ igbakeji alaga igbimọ naa dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ igbimọ.
O ni gbogbo nnkan to yẹ kí Ọwa Obokun tuntun ṣe ni o ti ṣe to fi mọ wiwọ Ipebi.
Ajirowa ni ahesọ ọrọ lasan lawọn to n sọ pe owo ni Ọba Haastrup fi ra ipo naa.
O ni irọ tó jinna si ootọ ni ọrọ naa, torí gbogbo aṣa ibilẹ ti wọn máa n ṣe fun Ọba nilẹ Ijẹsa ni Ọba Haastrup kopa ninu rẹ pata.
Ta ni Adesuyi Haastrup?
Hasstrup, to ti fi akoko igba kan ri di ipo igbakeji gomina ipinlẹ Osun mu ni yii jọba lẹyin ti Ọba Gabriel Adekunle Aromolaran waja.
Oun ni yoo si jẹ Owa Obokun kọkandinlaadọta.
Haastrup ni igbakeji gomina Isiaka Adeleke laarin ọdun 1992 si ọdun 1993.
Ọjọ kọkandinlgun, oṣu Kẹsan an, ọdun 1948 ni wọn bi Haastrup ni idile Ajimoko ti ilẹ Ijesha.
O kẹkọọ ni Eko Boys High School laarin ọdun 1963 si 1967 ko to tẹsiwaju ni Federal School of Sciences, ipinlẹ Eko laarin ọdun 1968 si 1969.
Lẹyin naa lo lọ kẹkọọ ni fasiti Howard, to wa niluu Washington D.C., nilẹ Amẹrika.















