'Ìfẹ̀hónúhàn wa kò lọ́wọ́ òṣèlú nínú, ìdí tí a fi wọ́de lórí ọ̀nà tí kò da rèé'

Àwọn ọ̀dọ́ Aduramigba, Ido-Osun gbé onírúurú àkọ́lé lọ́wọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọsẹ to kọja ni awọn ni awọn ọdọ agbegbe Aduramigba ni Ilu Ido-Osun, ipinlẹ Osun ṣe iwọde ifẹhonuhan lori ọna kan ti ijọba apapọ n ṣe ni agbegbe naa.

Gẹgẹ bi iwadii ṣe fi han, ile ifowopamọ agbaye, ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Osun ni wọn pawọpọ ṣe ọna naa labẹ eto Rural Access and Agricultural Marketing Project, RAAMP.

Ni ọjọbọ, ọjọ Kẹẹdogun ni awọn ọdọ naa ṣe iwọde lati fi ẹhonu wọn han lori ọna ọhun bi wọn ṣe fẹsun kan pe lẹyin ọjọ meji ti wọn da ọda sori rẹ ni ojo nla kan hu.

Iwadii fi han pe ọjọ Kọkanla, osu Karun-un, ọdun yii ni wọn da ọda si oju titi naa, to si bẹrẹ si ni bajẹ ni ọjọ mẹrin ti wọn da ọda si.

Eyi lo mu awọn ọdọ naa ṣe iwọde ti wọn si n ke si Gomina Ademola Adeleke lati lọ maa ṣayẹwo awọn akanṣe iṣẹ ti wọn ba ti n gbe jade lati le mọ iru iṣẹ tawọn kọngila ti wọn n gbeṣẹ fun n ṣe.

Lẹyin ifẹhonuhan wọn yii, Gomina Adeleke ni oun ti gbe igbimọ kan dide lati ṣe abẹwo sibi ọna naa, ki wọn si wa jabọ fun oun lori iru iṣẹ to wa nibẹ.

Bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn tun ọna naa ṣe ni kiakia, ki wọn si ri pe ko si iṣẹ ajanbaku lori iṣẹ naa.

Eyi lo mu BBC News Yoruba kan si ilu Ido-Osun, ijọba ibilẹ, Egbedore lati wo bi nnkan ṣe n lọ nibẹ.

'Kò sí òjú àgbàrá tí omi lè máa gbà kọjá níbi titit ti kọngila ṣe'

Ọ̀nà tó hú lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wọ́n ṣe é
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaga adugbo Aduramigba, nibi ti ifẹhonuhan ti waye, Sunday Ogundare sọ fun BBC News Yoruba pe iṣẹ ajanbaku ni kọngila to gba iṣẹ ọna naa sibẹ, to si jẹ pe ọna naa ko dara.

O ni ko si ojuṣan agbara ti omi le maa gba kọja ti ojo ba n rọ láti le mu ki ọna ọhun tọjọ nibẹ.

Ogundare sọ pe awọn ko fẹ ki Gomina Ademola Adeleke ri igbese awọn bi atako si iṣẹ titi ti agbaṣẹṣe naa ṣe tabi ro wi pe awọn oloṣelu lo wa nidii ifẹhonuhan tawọn ọdọ naa ṣe.

‎‎O fi kun pe idagbasoke kan gboogi ni ilu Ido-Osun lo jẹ awọn logun tawọn fi gbe igbesẹ lati ṣe ifẹhonuhan lori ọna naa pe ko ni nnkankan ṣe pẹlu ikunsinu to wa laarin ilu Ede ati Ido-Osun bawọn kan ṣe n sọ.

‎‎O wa rọ Gomina Adeleke lati wa ọna atunse si oju ọna naa ati wi pe ki ijọba maa ṣayẹwo awọn kongila daadaa ki wọn to maa gbe iṣẹ fun wọn lati le mọ aridaju iru iṣẹ ti wọn le ṣe.

Ọdọ ilu Ido-Osun mii, Raheem Abdullah kọminu pe ko si idagbasoke kan gboogi ni ilu awọn ti awọn si n fẹ ayipada to loorin lori rẹ.

‎‎‎‎O ni yatọ si ọna ti ko dara ti wọn ṣẹṣẹ ṣe ọhun, omi ẹrọ igbalode ti ijọba ṣe si ilu naa ko ṣiṣẹ titi di asiko yii ati pe ina sola igbalode ti Gomina Adeleke n ṣe kaakiri ilu ni ko de ilu Ido-Osun rara.

Ọ̀nà tó hú lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wọ́n ṣe é

Ijọba Osun kọ lo n ṣe titi ti ko dara naa amọ gomina ti bẹrẹ igbesẹ le lori – Kọmiṣanna

Kọmiṣanna fun idagbasoke ẹsẹkuku ni ipinlẹ Osun, ‎‎Ganiyu Olaoluwa nigba to n fesi lori ẹsun awọn araalu naa sọ pe kii ṣe ijọba ipinlẹ Osun lo n ṣe ọna Aduramigba to n fa awuyewuye naa.

O ni eto ijọba apapọ to n ri si idagbasoke ẹsẹkuku pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba ipinlẹ lo n ṣe iṣẹ titi naa.

‎‎ Olaoluwa sọ pe igbese ti bẹrẹ lori atunse ọna ọhun ati pe gomina Ademola Adeleke ti ṣe agbedide igbimọ to maa ri si ọna naa.

"Mo n fi da awọn eeyan Aduramigba loju pe atunse maa ba oju ọna naa laipẹ nitori Gomina Ademola Adeleke ti gbe igbese awọn igbesẹ to lagbara lori ọrọ naa."