Ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlérí góòlù - àṣírí ìwà àìtọ́ tó ń kojú àwọn ọmọdékùnrin kan láwọn ibùdó ìwakùsà tó lòdì sófin ni South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Mayeni Jones
- Role, BBC News, Johannesburg
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Awọn nnkan kan wa ninu iroyin yii, titi kan fidio kan to le bani lọkan jẹ.
Bi wọn ṣe n lo awọn ọmọde nilokulo ni ohun to jẹ ijọloju julọ fun Jonathan, ọkunrin kan to ṣiṣẹ fun oṣu mẹfa nibudo iwakusa abẹ ilẹ kan ti wọn ko lo mọ ni South Africa.
Wọn gba awọn kan lati maa ṣiṣẹ, wọn n fun wọn lowo ti ko to nnkan rara, ṣugbọn awọn kan wa to jẹ pe ibalopọ gan-an ni wọn tori ẹ gba wọn sibẹ, gẹgẹ bi awọn to lukoro iṣẹlẹ naa ṣe sọ.
Jonathan to ku diẹ ko pe ọgbọn ọdun bayii, wa iṣẹ aje lọ si South Africa ni, pẹlu ireti pe oun yoo ri owo tabua ko wale nirọrun nibi awọn ibudo iwakusa ati goolu ti wọn ko lo mọ to wa nibẹ.
BBC ko ni i fi orukọ rẹ ni apetan sita, nitori ati da aabo bo o lọwọ awọn ẹlẹgiri awakausa to n huwa aitọ nibudo iwakusa naa. Ki wọn ma baa doju ija kọ ọ nitori ọrọ to ba ikọ akoroyin wa sọ.
Jonathan ṣalaye ooru buruku to n mu nibudo naa toun dojukọ, iṣẹ aṣekudorogbo fun ọpọlọpọ wakati ati ounje ti ko to nnkan to n ri jẹ.
Gbogbo ẹ lo ni o daamu aye oun. Ṣugbọn gbogbo ẹ kere lẹgbẹ iṣekuṣe ati ilokulo ti wọn n lo awọn ọmọdekunrin nibẹ, gẹgẹ bo ṣe ṣalaye ni kikun fun wa nipa ibi to ti ṣiṣẹ naa.
''Mo máa ń rí àwọn àgbàlagbà ọkùnrin awakùsà tó ń bá àwọn ọmọkùnrin ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lò pọ̀''
"Mo maa n ri awọn ọmọde naa nibudo iwakusa- awọn ọṣoọrọkunrin ti ọjọ ori wọn ko ju mẹẹẹdogun si mẹtadinlogun lọ. (15-17).
"Awọn kan a si maa lo wọn bẹẹ nitori ipo ti wọn ba ara wọn. O maa n ba mi lẹru diẹ, ara mi ko si gba iru ẹ lati maa ri."
Jonathan lo ṣalaye bẹẹ.
O ni igba mi-in wa ti awọn agbalagba awakusa yoo maa fipa ba wọn lo pọ pẹlu ileri lati fun wọn ni goolu. Wọn yoo ni ki wọn farabalẹ fun ibalopọ, awọn yoo fun wọn ni goolu tawọn ba ri bii paṣipaarọ.
"To ba jẹ ọmọ to nilo owo kia, yoo gba fun wọn."
Jonathan ṣalaye nipa bi awọn ọmọde naa ṣe maa n sa di awọn awakusa yii fun aabo, ṣugbọn aabo naa yoo ba nnkan kan de ṣaa ni, ki i ṣe ọfẹ.
O ni wọn tun maa n lo ibalopọ gẹgẹ bi ijiya fun ọmọ to ba kọ lati pari iṣẹ ti wọn ba ni ko ṣe. Wọn yoo ba a lo pọ gẹgẹ bi ijiya.
Jonathan sọ pe ajeji ni awọn ọmọ to wa nibi iwakusa toun ti ṣiṣẹ naa, wọn ko si mọ itumọ ohun ti wọn n fi aye wọn ṣe.

Oríṣun àwòrán, AFP
''Àwọn ọ̀daràn awakùsà máa ń mọ̀-ọ́n-mọ̀ gba ọmọdé síbi iṣẹ́ àìtọ́ náà ni''
Oluwadii nipa iwakusa ati ajafẹtọọ kan, Makhotla Sefuli, fidi eyi mulẹ.
O ni awọn ikọ awakusa ti wọn jẹ ọdaran maa n mọ-ọn-mọ daju sọ awọn ọmọde lati fi wọn ṣiṣẹ nibudo iwakusa aitọ kaakiri South Africa ni.
Ọpọ wọn lo jẹ pe lati orilẹede alamuleti ni wọn ti ko wọn wọle lọna aitọ. Ileri asan, iṣẹ olowo nla ni wọn sọ fun wọn pe wọn aa maa ri ṣe nileeṣẹ iwakusa naa.
"Bi wọn ba ti de South Africa ni wọn yoo fipa gba iwe irinna wọn lọwọọ wọn… Gbogbo wa la mọ pe wọn n lo awọn ọdọkunrin yii nilokulo." Ọgbẹni Sefuli lo ṣalaye bẹẹ.
BBC ti ba meji, o kere tan, ninu awọn awakusa to n ṣiṣẹ nibi aitọ yii sọrọ, wọn sọ fun wa pe awọn ri awọn ọmọdekunrin ti wọn n ṣe baṣubaṣu nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ naa.
Ọkan ninu wọn, Tshepo, (ki i ṣe orukọ rẹ gan-an niyẹn) sọ fun wa pe oun ri awọn ọkunrin agbalagba ti won n fipa ba awọn ọdọkunrin lo pọ nisalẹ ajaalẹ ti wọn wa.
"Nigba mi-in, nitori owo ni wọn ṣe n ṣe e. Wọn maa n gba awọn mi-in ki wọn le maa ba wọn lo pọ lasan, nitori owo nla ti wọn yoo sọ pe wọn yoo san fun ibalopọ ajaalẹ."
O fi kun un pe ibalopọ yii maa n daamu awọn ọmọ naa gan-an.
" O maa n jẹ ki wọn yi iwa wọn pada, wọn ko si ki n le jẹri ẹnikẹni mọ. Wọn o ni i fẹ ki eeyan sun mọ wọn, nitori wọn ti ro pe ko sẹni tawọn le fọkan tan nibẹ mọ."
Aṣiri awọn nnkan ti oju awọn ọdọ n ri yii tu jade lasiko kan lọdun to kọja, nigba ti awọn ọlọpaa ati awọn awakusa lọna aitọ yii kọju ija sira wọn.
Fídíò àṣírí ìkọ̀kọ̀ tú síta
Gadagba ni awọn ohun to n ṣẹlẹ ni ibudo iwakusa Buffelsfontein, nitosi ilu Stilfontein, lagbegbe Ariwa, n han loju iwe iroyin kaakiri agbaye, nigba ti aṣiri iṣẹ aabo ibẹ tu sita.
Awọn alaṣẹ ibẹ ni wọn ni wọn n lẹdi apo pọ, ti wọn ko si fẹẹ tu aṣiri iwakusa aitọ to n waye nibẹ, eyi ti ijọba South Africa sọ pe o mu ki ọrọ aje ilu naa padanu $3.2bn (£2.6bn) lọdun to kọja.
Wọn gbe eto kan kalẹ lati koju rẹ, eyi ti wọn pe ni 'Vala Umgodi',itumọ rẹ ni ''ẹ di oju iho naa', loṣu Kejila ọdun 2023, wọn ṣeleri lati fiya jẹ ikọ awakusa lọna aitọ naa.
Lara igbesẹ ti wọn gbe naa ni bi awọn ọlọpaa ṣe din ounjẹ ati omi to n lọ si ibudo iwakusa Stilfontein ku. Minisita kan tiẹ sọ pe ki wọn fin wọn pa mọnu iho naa. Awọn oṣiṣẹ kan ni wọn sọ pe wọn ko fẹẹ jade nitori ibẹru ọlọpaa to le mu wọn ni.
Ko pẹ ti awọn fidio kan bẹrẹ si i jade sita, to n ṣafihan ọpọ ọkunrin to ti gbẹ tan, ti wọn n bẹbẹ pe ki wọn waa doola awọn, ati awọn ti wọn ti so ara wọn soke nibẹ. Nigbẹyin ṣaa, kootu paṣẹ pe kawọn alaṣẹ doola wọn.
Mọ́kànlélọ́gbọ́n nínú àwọn tí wọ́n gbé jáde láti àjàalẹ̀ jẹ́ ọmọdé
Lara awọn ti wọn gbe jade ni awọn ti wọn ni ọjọ ori awọn ko to nnkan, ṣugbọn nigba to jẹ arinrinajo ni wọn, ti ko si si iwe to le sọ pato ọjọ ori wọn, awọn alaṣẹ ṣe ayẹwo fun wọn lati mọ .
Nipasẹ eyi, ẹka Department of Social Development (DSD) fidi ẹ mulẹ pe mọkanlelọgbọn (31) ninu awọn ti wọn doola ni Stilfontein jẹ ọmọde.
Ọmọ orilẹede Mozambique ni gbogbo wọn, nigba to si di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, wọn da mẹtadinlọgbọn (27) pada sile ninu wọn.
Ajọ Save the Children South Africa, ṣeranwọ lati ṣe ogbufọ awọn kan lara ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun awọn ọmọde awkusa na ati awọn oṣiṣẹ ti wọn doola.
"Wọn la idaamu ọkan kọja gan-an, nitori awọn mi-in ninu wọn naa ri i bi wọn 'se n fipa ba ẹgbẹ wọn sun lojuu won," OLudari ajọ alaanu naa, Gugu Xaba, lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
"Ironu pe o ṣee ṣe kawọn ma jade kuro ninu ajaalẹ naa ti ṣakoba fun awọn ọmọ yẹn.
"Awọn agbalagba awakusa yẹn yoo kọkọ maa ṣe bii pe wọn n kọ wọn niṣe, bii pe wọn fẹran wọn."
O ni wọn yoo kọkọ ni kawọn ọmọde naa maa ba awọn agbalagba ọkunrin naa ṣere to n ṣaaju ibalopọ, lẹyin ọjọ diẹ ni wọn yoo bẹrẹ si i fipa ba wọn lo pọ .
"O le to ọmọde mẹta si mẹrin ti awọn agbalagba yẹn maa ni lọwọ, ti wọn n ṣe nnkan kan naa pẹluu wọn."
Gugu Xaba,lo ṣalaye bẹẹ.
Most children are trafficked in order to be used as sex slaves. And you've got a pimp who is taking the money"
Arabinrin Xaba ṣalalye pe awọn awakusa naa n gba awọn ọmọde siṣẹ nitori o rọrun lati darii wọn, owo ti wọn yoo si tun san fun wọn ko ni i pọ.
"Ko ye awọn ọmọde yẹn, to o ba sọ fun wọn pe ma a san 20 rands ($1; £0.80) fun iṣẹ ọjọ kan fun ẹ.' Awọn agbalagba inu wọn maa n kọ lati ṣiṣẹ nigba mi-in, ṣugbọn ko sohun ti ọmọde le ṣe si i. Fun idi eyi, o rọrun lati ri ọmọde to maa ṣiṣẹ, ọmọ ti ko lẹnikan ti yoo gbeja rẹ, wọn yoo ko wọn lọ ṣiṣẹ nibẹ."
Yatọ si pe wọn n rẹ wọn jẹ nipa ti owo, Xaba sọ pe wọn n gba awọn kan nitori ibalopọ gangan.
Ọpọ awakusa lọna aitọ yii maa n lo ọpọlọpọ oṣu labẹ ilẹ, ti wọn ko ni i jade soke fun igba pipẹ. Ọja ti wọn yoo maa naa kuku ti wa labẹlẹ nibẹ, ti wọn n pese ohunkohun ti wọn ba fẹ fun wọn.
"Ọpọ ọmọ ti wọn n ko wa sibẹ lo jẹ nitori ki wọn le maa lo won bii ẹrú ibalopọ ni. Awọn agbodegba kan si wa to n gba owo naa, itumọ rẹ ni pe ojoojumọ ni wọn n lo ọmọde naa fun owo nàbì."
BBC beere lọwọ awọn ọlọpaa ati awọn DSD boya wọn le fi ẹsun kan ẹnikẹni fun iṣekuṣe yii. Wọn ko da wa lohun.
Ẹnikan lara awọn to n ṣiṣẹ lori ẹsun yii ni Stilfontein, sọ pe awọn ọmọ naa gan-an ko fẹẹ jẹrii .
Bẹẹ, ibudo iwakusa aitọ naa n tẹsiwaju.
Pẹlu bo ṣe jẹ pe o to ẹgbẹrun mẹfa ibudo bayii to wa nilẹ, okoowo kan ti ko ṣetan ti yoo wa sopin ni, eyi ti yoo sọ ẹgbẹrun ọmọde ti ko lẹnikan sinu ewu.















