Ajínigbé ṣekúpa alága ẹgbẹ́ APC l'Ondo lẹ́yìn tí wọ́n kọ́kọ́ gba ₦5m owó ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ebenezer Adeniyan
Awọn ajinibe ti ṣekupa alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ijọba ibilẹ Ose to wa nipinlẹ Ondo, Nelson Adepoyigi.
A gbọ pe asiko ti ọkunrin naa n jade kuro ninu ọkọ ayekẹlẹ rẹ niluu Ifon ni awọn ajinigbe naa kọlu u, ti wọn si gbe lọ.
Lẹyin iṣẹlẹ naa lawọn ajinigbe ọhun bere ọgọrun miliọnu naira lọwọ awọn mọlẹbi rẹ gẹgẹ bii owo itusilẹ, amọ lẹyin ọpọ idunadura wọn fẹnuko si miliọnu marun un naira.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, eeyan meji lara awọn ọmọ ilu rẹ yan lati lọ gbe owo itusilẹ naa fun awọn ajinigbe ọhun, amọ nigba ti wọn yoo de ibẹ, niṣe lawọn ajinigbe naa tun mu awọn eeyan ọhun mọlẹ ti wọn tun n bere owo gọbọi mii si.
Awọn ajinigbe naa kan si awọn ẹbi alaga ọhun pe ọgbọn milọnu naira lawọn yoo gba lati tu awọn mẹtẹta silẹ.
Amọ ṣa, lẹyin akoko diẹ, awọn ajinigbe naa tu awọn meji tuntun ọhun silẹ ti a si gbọ pe wọn ti pinnu pe pipa lawọn yoo pa Adepoyigi.
Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, alaga ijọba ibilẹ Ose, Kolapo Ojo sọ pe eto abo agbegbe Ifon ati ijọba ibilẹ Ose ti buru kọja afẹnusọ.
Ojo ni "Bi awọn ajinigbe yii ṣe n ṣọṣe bayii ti wọn tun n ji eeyan gbe lẹnu ọna ile rẹ n fi han pe eto abo ti mẹhẹ.
"A rọ awọn eeyan wa ki wọn ma sun asungbera ki wọn si maa bun awọn agbofinro gbọ ni gbogbo igba ti wọn ba kofiri iwa ọdaran kankan layika wọn...."















