Ìbẹ̀rùbojo gbilẹ̀ lórí owó orí ẹran àgbò bí ìjọba ṣe fòfin dé kíkó àgbò lọ sórílẹ̀ èdè míì lásìkò Ileya

Àwọn ẹran àgbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ́ àwọn tó ń ta nǹkan ọ̀sìn àti oúnjẹ ní orílẹ̀ èdè Niger ti kọminú pé ó ṣeéṣe kí owó àwọn nǹkan ọ̀sìn tún gbẹ́nu sókè ṣáájú ọdún Iléyá tó ń bọ̀ lọ́nà.

Wọ́n ní èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ látàrí òfin tuntun tí ìjọba Niger ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ pé wọ́n kò gbọdọ̀ kó nǹkan ọ̀sìn jáde kúrò ní orílẹ̀ èdè náà mọ́.

Ẹgbẹ́ àwọn olókoòwò ní Niger ti wá rọ ìjọba Niger láti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin náà nítorí àwọn aráàlú.

Alága ẹgbẹ́ náà, Dókítà Muhammad Tahir sọ fún BBC pé àdínkù yóò bá ọjà ẹran títà tí ìjọba kò bá gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin náà.

"Tí ìjọba bá rò pé àwọn fẹ́ mú nǹkan rọrùn fún aráàlú pẹ̀lú òfin náà, irọ́ ńlá ni nítorí àwọn tó ń ta ẹran ní Niger, tí wọn kò bá rí oníbàárà, wàhálà ńlá ni fún wọn," Tahir sọ

Ó ní àwọn àgbò tó lé ní 50,000 ni àwọn olókoòwò àgbò ti rà láti orílẹ̀ èdè Chad àmọ́ tí wọn kò ri kó wọ Niger.

Ó fi kun pé àwọn ẹran náà wà ní ẹnubodè Chad àti Niger.

Ó sọ pé tí àwọn kò bá rí ẹran tí wọ́n rà náà kó wọ Niger, ó máa jẹ́ kí àwọn ọlọ́jà gbówó lé iye ẹran tó wà nínú ìlú lọ́wọ́, tí yóò sì mú ìnira bá àwọn tó bá fẹ́ ra ẹran láti ṣe ọdún Iléyá.

Niger jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tó máa ń ta ẹran àgbò sáwọn orílẹ̀ èdè tó súnmọ́ ọn lásìkò ọdún Iléyá.

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè Niger ní àwọn gbé ìgbésẹ̀ láti fòfin de kíko ẹran lọ sílẹ̀ òkèèrè láti mú àdínkù bá iye táwọn èèyàn ń ta ẹran àgbò lásìkò ọdún Iléyá tó súnmọ́.

Ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹfà ni ìrètí wà pé ọdún Iléyá 2025 máa bọ́ sí.

Láti bíi ọdún méjì sẹ́yìn ni iye tí wọ́n ń ta ẹran àgbò ń wọ́n si, tó sì lọ sókè púpọ̀ ní ọdún tó kọjá.

Lásìkò ọdún Iléyá tó kọjá, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ra ẹran àgbò láàárín N250,000 sí N500,000 ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.