Ẹni tí a jọ ń gbé lábẹ́ òrùlé kan ló tà mí sóko ẹrú ní Mali – Adeola, ọmọ Jumoke George

Abike Dabiri

Oríṣun àwòrán, Abike Dabiri

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Adeola, to jẹ ọmọ akọbi ọmọ oṣere tiata Yoruba, Jumoke George, ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lorilẹede Mali to wa fun ọdun mẹrin gbako.

Obinrin ẹni ogoji ọdun naa ṣalaye pe ẹni to sunmọ oun bii iṣan ọrun lo ta oun si oko ẹru ni Mali, oun si n fẹ ko jẹ iya to tọ labẹ ofin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, orilẹede Malaysia lo ro pe oun n lọ tẹlẹ ko to di ẹni to n ṣi ẹru ni Mali.

Bi mo ṣe di ero Mali

Adeola ṣalaye pe ẹni to ta oun sọ pe "Ṣe ẹ maa lọ si Mali, emi wa ro pe Malaysia lo n sọ.

"O ni niwọn igba ti mo mọ nipa iṣẹ oogun tita daadaa, oun ni obinrin kan ni Mali to ni ile itaja oogun nla kan ti mo ti maa ṣiṣe.

"Mo ni mo ti gbọ amọ mi o ni sọ fun Amoke, to jẹ iya mi nitori wọn ko ni jẹ ki n lọ... odidi ọjọ bii mẹrin si marun un ni a lo loju ọna Cotonou si Mali.

Adeola ṣalaye pe nigba ti oun yoo de Mali ti oun lọ ba ẹni ti wọn ni oun yoo ma gbe lọdọ rẹ, ni iyẹn wa sọ fun oun pe wọn ti ta oun ati pe iṣẹ aṣẹwo ni oun yoo maa ṣe lọhun.

O ni oun kọ jalẹ pe oun ko le ṣisẹ aṣẹwo lailai bo tilẹ jẹ pe wọn dunkoko mọ oun ti wọn si sọ fun oun pe wọn yoo fun oun ni majele jẹ.

"Ohun ti oju mi ri ni Mali kọja afẹnusọ"

Lẹyinorẹyin, Adeola sọ pe oun kọ jale oun si kuro lọdọ awọn ti wọn ta oun fun lati maa ṣowo nọbi.

O ṣalaye pe N1.5m ni ẹni ti wọn ta oun fun sọ pe oun yoo san ki oun to gba ominira.

Lati ibẹ lọ, o ni oun pade obinrin mii to nile ounjẹ ti oun n ṣiṣẹ ọmọ ọdọ nile ounjẹ rẹ.

O sọ siwaju si pe yatọ si iya ti oun jẹ ni Mali, ogun awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram tun ṣoju oun lọhun.

O ni "Awọn ọmọ ogun Russia atawọn ọmọ ogun Boko Haram ja niwaju ile ti mo n gbe, koda wọn ju ado oloro sibẹ.

"Ọlọrun lo ko mi yọ nitori mo ro pe mo maa ku lọjọ naa ni."

Adeola rọ awọn obinrin akẹgbẹ rẹ pe ki wọn ma da aba pe awọn fẹ rinrinajo lọ orilẹede Mali, Libya atawọn orilẹede mii bẹẹ nitori ikoro lo maa n gbẹyin irufẹ irinajo bẹẹ.

Lẹyin naa lo tọrọ aforijin lọwọ iya rẹ, Jumoke George fun bi oun ko ṣe kan si fun odidi ọdun mẹrin gbako ti oun fi wa ni Mali.

Ìròyìn ayọ̀! Àjọ NiDCOM ti gbé ọmọ Jumoke George padà sílé láti Mali

Ọga Ajọ NiDCOM, Abike Dabiri, Biola Adebayo ati Adeniyi Johnson

Oríṣun àwòrán, Abike Dabiri/X

Ajọ to n mojuto igbaye-gbadun awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okeere, The Nigerians in Diaspora Commission (NiDCOM) ti mu Adeola, ọmọ osẹrebinrin, Jumoke George, wa sile lati orilẹede Mali.

Ọsan ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun un, ni Ọga Agba ajọ NiDCOM, Arabinrin Abike Dabiri, fi ikede sita loju opo X rẹ pe, oṣerebinrin, Biola Adebayo ati akẹgbẹ rẹ Adeniyi Johnson, ti tẹwọ gba arabinrin ọhun.

Ọsẹ to kọja ni agba oṣere naa ke gbajare sita pe lati bi ọdun mẹrin ni akọbi ọmọ oun, Adeola, ẹni ọdun mọkanlelogoji, ti dawati.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu Biola Adebayo lori eto rẹ Talk to B, ni eyi ti jẹyọ.

Kini Jumoke George sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo ọhun ni Arabinrin Jumoke George ti Ninu fidio kan ti n sunkun kikoro pẹlu alaye pe ki awọ abiamọ gbadura fun oun. "Ẹyin abiamọ, ẹ fadura ran mi lọwọ, teeyan o bajẹ lọwọ mi ri o, ẹmi mi o gbe e mọ."

Ko sile ko si nnkankan, odidi ọmọ, mi o tun ri i, ko si alaafia. O ti su mi, ipa mi ti pin.

" Akọbi mi, Deola, mi o ri i, lati ọdun mẹrin sẹyin ni mo ti n wa a ti mi o ri i, o pe ẹni ọdun mọkanlelogoji lọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un yii, ọdọ mi naa lawọn ọmọ ẹ wa.

"Lati ọjọ keji oṣu Kin-in-ni ọdun yii ni ara temi naa ko ti ya. Mo ti gbiyanju gẹgẹ bi eniyan, gẹgẹ bii onigbagbọ.

"Gbogbo ayẹwo ni mo ti ṣe. Ayẹwo to tun ku ti mo fẹẹ ṣe bayii ni ti ọpọlọ ati ọkan, o le ni ẹgbẹrun lọna irinwo naira (400,000) ti wọn pe e, nibo ni mo ti fẹẹ ri i.

"Mi o le sun, gbogbo ara maa n ni ọta mi ni, gbogbo nnkan lo n ṣe mi, ko ye mi mọ.''

Mama onitiata naa ṣalaye pe ẹnikan lo n ba oun yawo toun n na, gbese naa si ti wọ miliọnu meji naira.

O fi kun un pe oun ko tilẹ nile lori, o ni o ti n sun mọ ọdun mẹfa lọ bayii to jẹ pe ṣọọṣi loun n gbe, iya ṣọọṣi loun n foun lounjẹ lọpọ igba.

Biola Adebayo gburo ọmọ na ni Mali

Abike Dabiri, Adeola, ati Biola Adebayo

Oríṣun àwòrán, Abike Dabiri/X

Ọjọ diẹ lẹyin ti fidio iọrọwanilẹnuwo naa jade sori ayelujara, ni Biola Bayo tun ṣafihan ọrọ to ba ọmọ Jumoke George, ẹni ti wọn pe ni Adeola sọ.

Ninu ọrọ Adeola pẹlu Biola Bayo, o ṣalaye pe orilẹede Mali ni oun wa bayii.

Biola wa rọ Adeola pe ko wa sile lati wa ri iya rẹ nitori pe on saaro rẹ, to si n jẹ ẹ lẹnu pupọ.

Ninu ọrọ ti awọn mejeeji jọ sọ lori foonu ni Adeola tun tẹnubọ ọrọ pe, ko si bi oun ṣe fẹ waye pada wa si ile nitori oun ko ni iwe asẹ irinna.

"Lọwọ yii, n ko ni iwe asẹ ti maa fi rin lọna, koda ko si owo ti maa fi wa si ile bayii.

"Iya mi o ṣẹ mi, bẹẹ ni a ko si fi igba kankan ja ṣugbọn n ko lee ba iya mi sọrọ fun ọdun mẹrin nitori n ko ni nọmba wọn lọwọ."

"Ti mo ba ki n ma rin irinajo lai ni iwe irinna, o ṣeeṣe ki wọn gbe mi si ahamọ.

"Ọpọ ọmọ Naijiria lo wa ni ahamọ awọn agbofinro nibi bayii nitori wọn ko ni iwe irinna.

"Mo mọ iya mi, ti mo ba pe e, wọn yoo kan maa ṣunkun ni, mo kan fẹ yọ si wọn ati awọn ọmọ mi lojiji ni."

Adeola wa rọ Biola Bayo pe gbogbo agbara to ba le sa fun oun lati kuro orilẹede Mali ni ko sa, nitori ilu naa ti su oun gan an.

Ta a ni Jumoke George?

Jumoke George

Oríṣun àwòrán, Others

Margaret Amoke Olatunde tawọn eeyan mọ si Jumoke George, lo wa nipo kẹta ninu ọmọ ti awọn obi rẹ bi.

Ṣọja ni baba rẹ, iya rẹ si jẹ olukọ.

Jumoke George lọ sileewe alakọọbẹrẹ Command Children School, Yaba, l'Ekoo ati Anglican Grammar School, Orita Mefa, Ibadan.

Bakan naa lo lọ sileewe ẹkọṣẹ ọwọ l'Osogbo.

Nipa ere ori itage, ọdun 2024 lo pe aadọta ọdun ti Jumoke George ti n ṣe ere tiata.

Iya naa ṣalaye ninu ifọwerọ kan, pe ileeṣẹ tẹlifiṣan ijọba apapọ (NTA) ni wọn ti ṣawari oun.

O loun fẹran ere ori itage toun yoo maa ri awọn eeyan to n wo o, ju fiimu agbelewo lọ, nitori ori itage gan-an ni idan wa, ti oṣere yoo le fi ipa rẹ han gidi.

Jumoke George ṣalaye nigba naa pe asiko kan wa ti wọn ko pe oun si fiimu fun ọdun mẹrinla, nitori oun kọ lati ba awọn kan to fẹẹ ba oun sun ṣe.

O loun fẹran lati maa kopa iya, tabi iya-iya ninu ere, oun fẹran koun wọṣọ ti yoo foun ni alaafia, oun si korira ariwo.