Timothy Omotosho: Wo àwọn pásítọ̀ ọmọ Naijiria tó ti fìgbàkanrí ní ìṣòro òfin nílẹ̀ òkèèrè

Oríṣun àwòrán, Tobi Adegboyega/Timothy Omotoso/Matthew Asimolowo
Ijọba South Africa ti le pasitọ ọmọ Naijiria, Timothy Omotoso pada wale lẹyin ti ile ẹjọ kan da silẹ lọgba ẹwọn lori ẹsun fifi ọwọ kan obinrin lọna aitọ.
Awọn eeyan ri pasitọ naa ni papakọ ofurufu OR Tambo niluu Johannesburg lana ọjọ Aiku nibi to ti n ba awọn oṣiṣe aṣobode sọrọ ko to wọ baalu wa si Naijiria.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun mẹjọ gbako ni pasitọ ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin naa lo lọgba ẹwọn ki ile ẹjọ to tu silẹ.
Ọrọ igbẹjọ rẹ milẹ titi kaakiri agbaye bi awọn kan ṣe n sọrọ lori bi ijọba South Africa ṣe yan oluṣo aguta naa jẹ lawọn mii n sọ pe o yẹ ki ẹwọn rẹ ju ti ọbọ lọ.
Wayi o, kii ṣe pasitọ yii nikan ni ọmo Naijiria to ko si gbaga ofin nilẹ okeere.
Iwọnyii ni awọn pasitọ ọmọ Naijiria ti ofin ti ṣe ọfintoto wọn nilẹ okeere.
Timothy Omotoso lori ẹsun ibalopọ ni South Africa

Oríṣun àwòrán, @joy_zelda
Omotoso ni olori ijọ Jesus Dominion International Church to wa niluu Druban, ni South Africa ṣaaju idojukọ rẹ.
Ọdun 2017 lo ko si gbaga ọlọpaa lẹyin ti oniruru awọn ọdọbinrin fẹsun kan an pe o tan awọn lọ sile rẹ to wa lagbegbe Umhlanga labẹ asia pe o fẹ maa kọ wọn ni ọrọ Ọlọrun amọ to n fi ọwọ kan wọn lọna aitọ.
Amọ nigba ti yoo di inu ọdun 2025, adajọ Irma Schoeman sọ pe awọn to kọkọ ṣe ẹjọ Omotoso ko ṣe ọfintoto to yẹ ki wọn ṣe, wọn ko si ṣayẹwo gboggbo awọn to yẹ ki wọn fi ọrọ wa lenu wo.
Lẹyin idajọ naa ni Irma Schoeman ni ki wọn tu afurasi ọhun silẹ eyii to bi ọpọ ẹgbẹ ajafẹtọọ awọn obinrin ninu ni South Africa.
Amọ nigba ti yoo di inu oṣu Kẹrin ọdun yii kan naa, wọn tun fi ṣikun ofin gbe lori ẹsun pe o tapa si ofin irinkerindo ilẹ South Africa.
Lẹyinorẹyin, wọn ti da pasitọ naa pada si Naijiria to jẹ ilu bibi rẹ.
Iwadii ijọ Matthew Ashimolowo lori ẹsun ṣiṣi wo na ni UK

Oríṣun àwòrán, @gospelfilmsng
Inu oṣu Keji ọdun 2017 ni ileeṣẹ ọlọpaa ilu London bẹrẹ iwadii lori ijọ Kingsway International Christian Centre, KICC, ti Matthew Ashimolowo jẹ adari rẹ.
Ileeṣẹ iroyin UK Guardian jabọ lọdun naa pe agbabọọlu Premier League kan padanu owo ti iye rẹ to £3.9 lori idokowo kan to so mọ ijọ naa.
Ọrọ naa jẹyọ lẹyin iwadii ajọ Charity Commission to n ṣe ọfintoto bi ijọ KICC ṣe na owo ti iwadii naa si fi han pe KICC dokowo ti iye rẹ to £5m pẹlu Richard Rufus to n gba bọọlu fun Charlton Athletic tẹlẹ.
Ẹwẹ, ile ẹjọ kan lọdun fidi rẹ mulẹ lọdun naa pe Rufus ṣe owo sọ ogun di ogoji laarin ọdun 2007 si 2011, nibi ti awọn onibara rẹ ti padanu owo to le ni £8m.
Ijọ KICC ti Asimolow n dari rẹ ni Rufus n lọ lasiko naa.
Tobin Adegboyega SPAC Nation lori ẹsun ṣiṣe £1.87m kumọmkumọ

Oríṣun àwòrán, Tobi Adegboyega
Ọdun 2005 ni Tobi Adegboyega tẹkọ lọ silẹ Gẹẹsi gẹgẹ bii alejo amọ nigba ti yoo di ọdun 2015 lo gbiyanju lati gba iwe igbelu.
Ni 2024, iroyin gbode pe ijọba ilẹ naa n mura lati le pada si Naijiria latari bo ṣe ṣe owo ijọ rẹ, Salvation Proclaimers Anointed Church, SPAC Nation, ti iye rẹ to £1.87m kumọmkumọ.
Ile ẹjọ giga kan nilẹ Gẹẹsi sọ pe pasitọ ọhun ko le ṣalaye bo ṣe na owo naa.
Awọn ọmọ ijọ rẹ nigba kan ri fẹsun kan awọn alaṣẹ rẹ pe o n fi tipatikuuku mu awọn da owo ọrẹ.
Ọpọ eeyan tun fẹsun kan Tobi pe o n gbe igbeaye faaji, bẹẹ lo n lo oniruru ọkọ bọgini atawọn aṣọ igbalode.
Asiko ti ijọba ilẹ ọhun gbiyanju lati le pada si Naijiiria ni pasitọ naa gba ile ẹjọ lọ amọ ile ẹjọ kọ lati gba ẹbẹ rẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, pasitọ Tobi ṣalaye pe awọn to n jowu ohun lo n sọ ọrọ kobakungbe nipa igbeaye oun nitori ọpọ awọn ọdọ loun ti ran lọwọ ti oun si yi aye wọn pada.
Agbẹjọro rẹ sọ fun BBC pe ilẹ Gẹẹsi ni Tobi yoo maa mimi kan ko si ni mi I kuro nibẹ.












