Kí ló ṣokùnfà bí ẹlẹ́wọ̀n méje ṣe sá lọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Osun lẹ́yìn àrọ̀ọ̀dá òjò?

Aworan ogiri ọgba ẹwọn kan to ya

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni ẹlẹwọn meje to ti sa kuro lọgba ẹwọn Ilesa, nipinlẹ Osun bayii, latari ojo arọọda to rọ loru ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ oṣu Karun-un ọdun 2025 yii.

Agbẹnusọ ọgba ẹwọn naa, Umar Abubakar, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

Abubakar ṣalaye pe awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn naa ti bẹrẹ iṣẹ lorii bi wọn yoo ṣe ri awọn ẹlẹwọn yii mu pada sọgba ẹwọn.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Ninu atẹjade ohun ni wọn ti ṣalaye pe ojo to rọ naa fẹ atẹgun to lagbara.

Ni nnkan bii aago meji oru ti ojo ọhun n rọ lọwọ ni ogiri ọgba ẹwọn ọlọdun pipẹ naa wo lulẹ.

Eyi lo fun awọn ẹlẹwọn to juba ehoro ni anfaani lati ribi sa lọ gẹgẹ bi alaye awọn alabojuto ọgba ẹwọn Ilesa naa.

Ṣaa,ọga agba pata fun akoso ibudo atunṣe, Sylvester Ndidi Nwakuche,ti paṣẹ pe ki wọn wa awọn ẹlẹwọn to sa lọ naa ri.

O ni ki wọn ri I daju pe wọn pada sọgba ẹwọn naa.

" Ileeṣẹ wa n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo yooku lati ri i pe a mu awọn to sa lọ pada si ahamọ"

Apa kan atẹjade naa lo ka bẹẹ.

Bakan naa ni wọn rọ araalu to ba le ta wọn lolobo nipa bi wọn ṣe le ri wọn mu lati tete ṣe iranwọ.

Wọnyi ni awọn ẹrọ ibanisọrọ ti ileeṣẹ akoso ọgba ẹwọn naa fi sita, bi ẹnikẹni ba ni olobo to fẹẹ ta wọn: 07087086005, 09060004598, 08075050006.

Tabi ki wọn kan si ileeṣẹ agbofinro to ba wa nitosi.