Wo àwọn fásìtì àti Poly tó o le fi máàkì JAMB tí kò tó nnkan wọ̀ lọ́dún yìí

Awọn akẹkọọ to n ṣe idanwo JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lootọ ni esi idanwo aṣewọle sile ẹkọ giga, JAMB, ti jade, ti awuyewuye lori aṣiṣe ajọ naa si ti n rọlẹ bayii.

Nnkan to gba ọkan ọpọlọpọ akẹkọọ ati obi, paapaa awọn ti maaki ti wọn gba ko dara to iye ti ọpọ awọn fasiti n beere fun, ti wọn ko si si lara awọn to tun idanwo naa kọ, ni ọna ti wọn le gba ti awọn naa yoo fi wọ ile ẹkọ giga lọdun yii.

Gẹgẹ bi ajọ JAMB ṣe sọ, esi idanwo ti ọdun 2025 wa lara awọn eyi to ti i buru ju ninu itan idanwo naa. O to milinu meji akẹkọọ to ṣe idanwo naa, amọ 12,400 pere lo ni maaki to ju 300 lọ.

Ajọ naa pada jẹwọ pe oun ṣe aṣiṣe lasiko idanwo ọhun, eyi to mu ki iye awọn to fidirẹmi pọ to bẹẹ.

Nnkan to wọpọ ni pe akẹkọọ to ba gba maaki to to 200 ti yege lati wọ fasiti, bo tilẹ jẹ pe awọn ile-ẹkọ kan ma n gba awọn to ba ni 180 fun awọn ẹka eto ẹkọ kan.

Ṣugbọn lati bi ọdun diẹ sẹyin ni awọn fasiti kan ti sun maaki igbaniwọle wọn si 150. Eyi ni ko ṣẹyin bi awọn akẹkọọ ṣe n fidirẹmi. Awọn iroyin kan to n lọ, amọ ti a ko le fidirẹmulẹ ti ẹ sọ pe, o tun ṣe e ṣe ki maaki naa tun lọ silẹ ju bẹẹ lọ lọdun yii.

Oṣiṣẹ kan ni Fasiti ipinlẹ Abia, sọ fun BBC Pidgin pe, ile-ẹkọ naa ko ti i kede maaki igbaniwọle rẹ, o ni amọ oun ko lero pe o le wa silẹ ju 140 lọ.

Oṣiṣẹ miran ni Fasiti Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu University, eyi ti a mọ si Anambra State University tẹlẹ, sọ pe, fasiti naa ko ni i gba maaki to ba kere ju 150 lọ fun eyikeyi eto ẹkọ ti ko ni i ṣe pẹlu ofin tabi iṣegun oyinbo.

Bakan naa ni ẹnikan lati Fasiti ipinlẹ Sokoto sọ pe awọn ko tii fẹnuko lori maaki igbaniwọle, "nitori pe idanwo JAMB ko ti I pari".

Ẹni naa ti ko fẹ ka darukọ oun ninu iroyin yii sọ pe, yoo to oṣu Kẹjọ ki awọn to o le ṣe ipade lori rẹ. o ni ajọ JAMB yoo ti gba wọn ni imọran lori ọna abayọ. Amọ, 140 ni wọn gba lọdun to lọ.

Diẹ lara awọn fasiti to ṣe e ṣe ko gba maaki kekere

Awọn akẹkọọ to n ṣe idanwo

Oríṣun àwòrán, JAMB

Awọn akọsilẹ yii la ṣe lati ara iwoye nipa awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin, ati ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn oṣiṣẹ fasiti ni Naijiria.

Abia State University (ABSU) Uturu - 140

Ebonyi State University - 140

Ekiti State University - 140

Delta State University - 140

Federal University Gashua - Yobe State - 140

Kingsley Ozumba Mbadiwe University, Imo State - 140

Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu University, Anambra State - 150

Sokoto State University - 140

Usmanu Danfodiyo University Sokoto - 140

Benue State University Makurdi - 150

Ile-ẹkọ Gbogboniṣe (Polytechnic)

Akanu Ibiam Federal Polytechnic - Ebonyi State - 100

Delta State Polytechnic - 100

Kano State Polytechnic - 100

Federal Polytechnic Ede - Osun State - 120

Federal Polytechnic Ayede - Oyo State - 120