Kókó márùn-ún tó jáde láti ibi ìpàdé Ààrẹ Trump àti Ààrẹ Ramaphosa l'Amẹ́ríkà

Àkọlé fídíò,
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donlad Trump ati Aarẹ orilẹede South Africa, Cyril Ramaphosa ba awọn akọroyin sọrọ ni Oval Office ni ọjọ kọkanlelogun oṣu karun un ọdun 2025.

Ipade yii n waye lẹyin ti Ramaphosa pe awọn agbẹ alawọ fufu mọkindinlọgọta to jẹ ọmọ orilẹede South Africa ti wọn wa aabo lọ Amẹrika ni, ojo.

Trump ni awọn agbẹ alawọ funfun ti n sa kuro ni South Africa.

Aarẹ Amẹrika ati ọrẹ rẹ timọtimọ to jẹ ọmọ orilẹede South Africa, Elon Musk ti sọ ṣaaju pe iṣekupani n waye lọrilẹede abinibi rẹ.

Ọrọ yii ni ọpọ yii danu.

Okoowo naa wa lara nnkan ti wọn jiroro le lori bi South Africa ṣe bẹrẹ si ni gba ida Ọgbọn lorija lati Amẹrika.

Awọn agbẹ alawọ fufu to bere fun aabo lọwọ Amẹrika

Trump dahun awọn ibeere lori ọrọ to jẹ mọ awọn agbẹ to bere fun aabo, "A n gbọ iroyin nipa nnkan to n ṣẹlẹ ni Afrika pe awọn agbẹ alawọ fufu n ṣa kuro ni South Africa.

Ramaphosa yari tako eyi ṣugbọn Trump koju rẹ pẹlu fọnran, to si fi aworan iroyin ọhun han.

Sibẹsibẹ Ramaphosa yari pe iṣẹlẹ naa ko waye ati pe ki i ṣe ijọba lo ran wọn ni iṣẹ.

Olubanidamọran Trump, Elon Musk darapọ mọ ipade naa ṣugbọn ko sọrọ.

Trump ni oun ko fẹ Musk sinu ipade nitori ko dun mọ ọ ninu.

Ogun Ukraine

Aarẹ Trump mu ẹnu ba ogun to n lọwọ laarin Ukraine-Russia, to si pe e itajẹsilẹ to se e dena.

"Nnkan ti ko da ni", Trump sọrọ, to si fi kun un pe oun gbọ pe Aarẹ Volodymyr Zelensky lọ si South Africa.

Ramaphosa ni awọn nifẹ lati ri opin ogun naa, to si ni oun fọwọ si igbiyanju Trump lati fi opin si ogun ọhun.

Igbẹjọ ICC lori Israel

Trump ni oun ko reti nnkan ko jade lati igbẹjọ Ileẹjọ agbaye fun iwa ọdaran ti pe tako orilẹede Israel.

Akọroyin kan lo beere ibeere yii lẹyin ti ICC ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan Israel lori Gaza

Okoowo

Ramaphosa wa ọna lati ba Trump sọrọ lori okoowo to wa laarin orilẹede mejeeji.

Aarẹ South Africa bẹrẹ pẹlu ọrọ nipa ajọṣepọ imọ ẹrọ to wa laarin orilẹede Am]ẹrika ati South Africa.

Ọkunrin kan to rin pẹlu Aarẹ Ramaphosa, Zingiswa Losi, sọ pe ọpọ eeyan ni yoo padanu iṣẹ wọn ti awọn ileeṣẹ orilẹede Amẹrika ba pinnu lati ma ba South Africa siṣẹ mọ, to si gba Amẹrika ni imọran lati tẹsiwaju ninu biba South Africa dowopọ.

5. Ipade G20

Wọn beere lọwọ Trump boya yoo wa si ipade G20 ti yoo waye lorilẹede South Africa fun igba akọkọ ninu ọdun yii.

Trump ni lai si orilẹede Amẹrika, Ipade G20 ko ṣe koko rara.

Ramaphosa ni Amẹrika lo bẹrẹ ipade naa, ti o si ṣe koko ki Amẹrika tubọ ma gbe igbesẹ nla.

Amẹrika yoo gba ipo olori ẹgbẹ naa ni ọdun to n bọ, Ramaphosa ni inu orilẹede South Africa yoo dun pupọ lati gbe olori fun orilẹede to da ipade naa silẹ.