Davido pẹ̀lú iléeṣe Spiro gbé alùpùpù tó ń lo iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì jáde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajumọ olorin takasufe kaakiri agbaye, David "Davido" Adeleke ti kede ibaṣepọ rẹ pẹlu ileeṣẹ kan lati ṣagbekalẹ alupupu ti yoo maa lo ilẹ ilẹtiriki ni Afrika.
Davido, ti wọn ti gbọ orin rẹ nigba 8.6 biliọnu ti tọwọ bọwe adehun pẹlu ileeṣẹ Spiro, to jẹ ileeṣẹ to tobi julọ to n ṣe ọkọ to n lo ina ilẹtiriki ni Afrika lati ṣe awọn alupupu kan to n lo ina.
O ni alupupu naa yoo wulo fun awọn eeyan ni Afrika lati maa rininajo lọna ti ko ni pa wọn lara.
Gẹgẹ bo ṣe sọ "O ti pẹ ti mo ti fẹ maa lo gbajumọ mi fun anfani awọn eeyan ni Afrika.
"Awọn alupupu yii ko kan ni wa fun rinrin kaakiri nikan, yoo tun wulo fun awọn to fẹ maa fi pa owo wọle. Ilẹ Afrika si ni a ti ṣe e, eyii wu mi lori pupọ."
O le ni miliọnu mẹtadinlọgbọn alupupu to wa nilẹ adulawọ gẹgẹ bii atẹjade kan lati ajọ Motor Intelligence to sọ pe iye awọn alupupu ti awọn eeyan yoo lo nilẹ naa yoo to biliọnu mọkanla dọla ti yoo ba fi di ọdun 2029.
Davido ni lilo alupupu to n lo ina kii ṣe ọrọ igbalode amọ nikan amọ o jẹ ọna abayọ mii.
O ni "Igbesẹ yii mu ayipada ọtun ba agbegbe wa."
Ileeṣẹ Spiro ti ṣe alulupu bii ẹgbẹrun lọna ọgbọn to si ti pin kaakiri ilẹ Afrika.
Alupupu to rẹwa to tun lagbara

Nigba to n sọrọ nipa alupupu naa Davido sọ pe "Eyii ko dabii awọn ọkada ti ẹ n ri nigboro o.
"O rẹwa, o ba igba mu, koda ẹ le wa a lọ sinu ile agodo ti a ti n ka orin silẹ tabi sile ounjẹ igbalode, lọ ibiṣẹ atawọn ibomii. Mo lo ọkan ninu rẹ ninu awọn fidio mi to ṣẹṣẹ jade."
Fun ọpọ ilu ti ero pọ si ni Afrika, alupupu to n lo epo bẹntiro ni ọpọ n lo eyii ti eefin rẹ n ṣakoba fun awujọ.
Amọ Davido ti sọ pe lilo alupupu to n lo ina le mu ayipada ba eyii.
O ni "Lawọn ilu bii Eko tabi ni Ivory Coast, ẹ wo ẹgbẹlẹgbẹ awọn to n lo alupupu to n lo epo ati akoba ti alupupu naa n ṣe fun awujọ.
"Bawo ni yoo ti dara to ti gbogbo wọn ba bẹrẹ si n lo alupupu to n lo ina."
Amọ iṣoro nla to wa nibẹ ni ati ri ina ijọba lo.
Atẹjade banki agbaye kan lọdun 2023 sọ pe nnkan bii 600 miliọnu eeyan ni Africa ni ko ni anfani si ina ijọba.
Amọ ṣa, Davido ti sọ pe ẹni to ba ra alupupu naa fun iṣẹ le maa san owo rẹ diẹdiẹ.
Ọmọ Naijiria to n milẹ titi kaakiri agbaye

Yatọ si alupupu to n lo ina, Davido ṣẹṣẹ gbe awo orin kan jade to pe orukọ rẹ ni 5Live.
O ni "Ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo fẹ maa gbọ orin Afrobeat bayii, awọn eeyan wa ti n lọ kọ orin lawọn orilẹede mii."
Yatọ si Davido, awọn olorin mii bii Burna Boy, Rema, Asake, Arya Star, ati TEMS lo n lọ ilẹ okeere bi ẹni lọ ọja lati lọ maa kọ orin nibẹ.
Davido sọ pe kii ṣe pe awọn ko fẹ maa da awọn eeyan laraya nile bi wọn ṣe n ṣe fun awọn to wa nilẹ okere.
O ni "Mo ti kọrin kaakiri ilẹ Afrika bii eyii ti mo ṣe ni Uganda, Kenya, Naijiria amọ ko ta lẹnu to eyii ti mo ṣe ni Atlanta, ilẹ Gẹẹsi, Portugal tabi ni Paris.
Amọ o ni wọn ti bẹrẹ si n kọ awọn gbagede nla lawọn ilu bii Eko, Kigali ati Dakar to farajọ awon to wa loke okun, nitori naa nnkan ti n yi pada.
Davido pari ọrọ rẹ pe ti oun ba lọ kọ orin nilẹ okeere, niṣe lawọn eeyan maa n kun inu papa iṣere bọọlu, oun si n fẹ ki iru are bẹẹ waye nile ni Naijiria laipẹ.












