Ọ̀nà àbáyọ míì fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèèrè tí Trump ní kí wọn má fún ní físà wọ Amẹrika mọ́

Awọn olufẹhonuhan nile ẹkọ giga Harvard l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Rebecca Thorn
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere kaakiri agbaye ti n kọminu bi ijọba Aarẹ Donald Trump ti n gbero lati da fifun awọn akẹkọọ ilẹ okeere ni fisa lati wa kẹkọọ lorilẹede Amẹrika.

Iwe to wa lati ọdọ ijọba ti ileeṣẹ iroyin CBS to jẹ alabaṣiṣẹpọ BBC gan an ni fi idi rẹ mulẹ pe ijọba Amẹrika ti paṣẹ idaduro fifun awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere ni fisa lati wa kẹkọọ ni fasiti Harvard.

Eyi wa lara awọn igbesẹ ti Aarẹ Trump n gbe lati mu adinku ba bawọn eeyan ti n wọle sawọn fasiti Amẹrika to lorukọ gan an.

Trump tun ti fofin de Harvard lati ma gba awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere mọ, aarẹ ni igbiyanju fasiti naa ko to nipa kikoju awọn to n tabuku awọn ẹya Ju nile ẹkọ naa.

Fasiti Harvard ti pẹjọ tako Trump lori ọrọ naa, adajọ si ti da aarẹ lọwọ kọ bayii.

Awọn akẹkọọ wo ni igbesẹ Trump maa ṣakoba fun julọ?

Ajọ Open Doors to n ṣe iṣiro awọn akẹkọọ ilẹ okeere l'Amẹrika ti sọ pe o le ni miliọnu kan akẹkọọ lati orilẹede 210 to wọ oniruuru ile ẹkọ giga lorilẹede Amẹrika ni saa eto ẹkọ 2023-14.

330,000 akẹkọọ lati India lo wọ ile ẹkọ giga l'Amẹrika lọdun to lọ, eyi to jẹ orilẹede ilẹ okeere to ni akẹkọọ to pọ julọ l'Amẹrika.

China lo wa ni ipo keji pẹlu akẹkọọ 280,000, South Korea, Canada, Taiwan, Vietnam, Nigeria, Bangladesh, Brazil ati Nepal lo tẹ le China.

Akọwe ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Marco Rubio, sọ l'Ọjọru ọsẹ yii pe ijọba Trump ṣetan lati gba fisa lọwọ awọn akẹkọọ ọmọ orilẹede China to fi mawọn to ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu ''Chinese Communist Party.''

Ko si ẹni to mọ ni pato iye awọn akẹkọọ ọmọ orilẹede China ti igbesẹ yii yoo pa lara.

Orilẹede China ti tako igbesẹ ijọba Amẹrika yii, wọn ki ijọba Trump tun ero rẹ pa lori ọrọ naa.

Ijọba Trump ti gbe igbesẹ lati le ọpọ awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere kuro l'Amẹrika, bakan naa ni ijọba tun ti gba fisa lọwọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn mii.

Rubio sọ pe ko din ọdunrun un akẹkọọ ilẹ okeere ti ijọba Amẹrika ti gba fisa wọn, eyi wa lara nnkan ti Trump n ṣe lati mu adinku olufẹhonuhan to n ṣatilẹyin fun Palestine lawọn ọgba fasiti to wa l'Amẹrika.

Awọn olufẹhonuhan nile ẹkọ giga Harvard l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn alaṣẹ fasiti Harvard sọ ninu ẹjọ ti wọn pe l'Ọjọru wi pe aigba awọn akẹkọọ ilẹ okeere mọ le ṣakoba fun ile ẹkọ naa.

Adari ẹka to n ri si ọrọ ilẹ okeere nile ẹkọ Harvard, Maureen Martin, sọ nile ẹjọ wi pe erongba ijọba Trump lati ma fawọn akẹkọọ ilẹ okeere ni fisa mọ ti n jẹ ki ọkan awọn akẹkọọ atawọn onimọ maa poruuru.

O ni ọpọ akẹkọọ lo ko le yọju sibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade, nigba tawọn mii ko le rinrin ajo jade lati Amẹrika mọ.

Bakan naa lo sọ pe ẹru n ba ọpọ akẹkọọ ki wọn maa dawọn pada si orilẹede abinibi wọn.

Ọjọgbọn William Brustein ni ipa ti ko dara ni igbesẹ yii yoo ni lori Amẹrika.

Ki lawọn akẹkọọ ilẹ okeere le ṣe?

Aworan ile ẹkọ giga fasiti Harvard

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Canada, UK ati Australia lawọn ilẹ okeere mii to n gbawọn akẹkọọ lati ilẹ okeere lati bi ọdun meloo kan bayii.

Amọ adinku ti iye akẹkọọ tawọn naa n gba lẹnu lọọlọ yii.

Canada ti n mu adinku ba akẹkọọ lati ilẹ okeere to n wọ orilẹede naa nipa bi beere iye owo ti wọn ni ninu apo asunwọn banki wọn.

UK naa ti n mu adinku ba iye akẹkọọ ilẹ okeere to n wọ awọn ile ẹkọ giga fasiti lorilẹede naa.

Lati oṣu Kinni ọdun 2024 ni UK ti kede wi pe awọn akẹkọọ ko le mu ẹbi wọn maa gbe pẹlu wọn ni UK mọ.

Bakan naa ni ijọba tun sọ pe awọn akẹkọọ ko ni lanfaani lati gba fisa iṣẹ ṣiṣe mọ ti wọn ba pari ẹkọ wọn.

Australia to wa lara orilẹede to n gba akẹkọọ lati ilẹ okeere julọ naa ti mu adinku ba iye akẹkọọ ti wọn n gba.

Anfaani wo lo wa lawọn orilẹede mii?

Anfaani lo jẹ fun ọpọ ile ẹko giga fasiti bi ijọba Amẹrika ko ṣe fẹ fawọn akẹkọọ ilẹ okeere ni fisa mọ, tori owo gọbọi lawọn akẹkọọ ilẹ okeere maa n san.

Ọga agba ile ẹkọ giga Hong KOng, John Lee, ti sọ pe awọn ṣetan lati gba awọn akẹkọọ ti Amẹrika ba ti dẹyẹ si i ti o nira fun lati tẹsiwaju ẹkọ wọn lawọn ile ẹkọ giga fasiti Amẹrika.

O ni ijọba Hong Kong atawọn ile ẹkọ fasiti orilẹede naa ṣetan lati ṣe iranwọ fawọn akẹkọọ to ba fẹ lọ ile ẹkọ ni Hong Kong.

Awọn ile ẹkọ mii ni Asia bii Fasiti Sunway ni Malaysia naa ti sọ pe awọn yoo gba awọn akẹkọọ ti ko ba lanfaani lati tẹsiwaju ẹkọ wọn mọ lorilẹede Amẹrika.

Awọn akẹkọọ fasiti nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade niluu London.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nilẹ Yuroopu, orilẹede Germany ti n gba ọpọ akẹkọọ ilẹ okeere, ajọ to n ri si ọrọ eto ẹkọ to ni ṣe pẹlu ilẹ okeere, DAAD, sọ pe o le ni 400,000 akẹkọọ lati ilẹ okeere to wọ ile ẹkọ giga ni Germany lọdun 2025 yii.

Bakan naa, ijọba orilẹede Germany faye gbawọn akẹkọọ ilẹ okeere lati le maa ṣiṣẹ fun ogun wakati lọsẹ dipo wakati mẹwaa ti wọn ni tẹlẹ lati fi ṣiṣẹ.

Ọjogbọn Brustein sọ pe ayipada nla ti ba eto ẹkọ nilẹ okeere ni nnkan bii ọdun mẹẹdogun sẹyin.

O ni ibi tawọn akẹkọọ ilẹ okeere ti le lọ kawe ti pọ bayii.

Ọjọgbọn Brustein ni ''ọpọ fasiti lorilẹede Malaysia lo dara lati lọ kẹkọọ nibẹ.

Ausrtalia naa ko gbẹyin, bakan naa ni orilẹede France ti seleri owo fawọn Ọjọgbọn olukọ ti wọn ba fẹ fi Amerika silẹ wa ṣiṣẹ nibẹ.''

Njẹ akẹkọọ le tẹsiwaju ẹkọ rẹ lẹka ilẹ okeere fasiti rẹ?

Ọjọgbọn Brustein woye pe o yẹ ki ọpọ ile ẹkọ giga maa ni ẹka lawọn orilẹede mii.

''Mo mọ pe awọn fasiti orilẹede UK ti n ṣe eleyii tipẹ, awọn fasiti ni Malaysia maa n ṣe bẹẹ.

Pẹlu nnkan to n lọ lọwọ ni Amẹrika, oriṣiiriṣii apẹẹrẹ tawọn eeyan le tẹle lo ti wa.

Iru rẹ ni iṣẹ ti ile ẹkọ giga imo ẹrọ Illinois n ṣe ni India ati China.

Bakan naa, o le ni aadọta orilẹede ti ile ẹkọ fasiti Harvard fi soju itakun igbọrọkaye rẹ nibi tawọn eeyan ti le lọ kẹkọọ.

Orilẹede Argentina, England, Korea, Senegal ati Brazil wa lara awọn orilẹede ọhun.

Harvard ko tii kede bo ya awọn akẹkọọ yoo lanfaani lati tẹsiwaju ẹkọ wọn nilẹ okeere ti Trump ba duro lori ẹsẹ rẹ lati ma fawọn akẹkọọ ilẹ okeere ni fisa mọ,'' Ọjọgbọn Brustein lo sọ bẹẹ.