Ìtàn ayé Orúgbó, ìyá àgbà tó dá ìlú Omu-Aran sílẹ̀ ní 13th Century àmọ̀ tí wọn ‘ló wa láyé di òní’

Arugba atawọn eeyan to n lọ si ojubọ Orugbo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Yoruba ni idalu ni iselu nitori itan to rọ mọ isẹdalẹ ilu kan se ọtọọtọ.

Ti a ba si n sọrọ bi ilu kan se sẹ wa, a ko le sai mẹnuba awọn eeyan to se koko, ti wọn para pọ lati da ilu naa silẹ.

Bẹẹ naa ni ti ilu Omu Aran ri nitori wọn ko le sọ ilu naa, lai ma mẹnuba ipa ti iya agba Orúgbó kó ninu idasilẹ ilu naa.

Lati onka ẹgbẹrun ọdun lọna mẹtala (13th century), ti wọn ti da ilu Omu Aran silẹ si ni wọn ti n bọ iya agba Orugbo ni ọdọọdun titi di akoko yii.

BBC Yoruba de ilu Omu Aran nipinlẹ Kwara lati bawọn se ọdun Orugbo ti ọdun yii, ti a si gbọ ẹkunrẹrẹ itan nipa igbe aye Iya agba Orugbo.

Bakan naa la gbọ idi ti iya agba naa se se pataki si ilu naa ati ọba ilu ọhun to jẹ Olomu.

"Iya ọba Olomu akọkọ, to n jẹ Òmúgbòdò ni orukọ rẹ n jẹ Orúgbó"

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa itan aye iya agba Orugbo, Abọrẹ ilu Omu-aran Oloye Ajiboye Ademola, to tun se Onígẹmọ ti ilu Omu-aran ṣọ itan bi ilu Omu-aran se bẹrẹ pẹlu ayẹyẹ ọdun Orugbo.

Abọre ilu Omu-aran salaye pe ni nnkan bi ẹgbẹrun mẹtala ọdun sẹyin ni Olomu akọkọ ilu Omu-Aran kuro ni ilu ile ifẹ ni ipinlẹ Ọ̀sun lati lọ tẹdo si ilu Omu-aran.

O salaye pe bi wọn se n bọ lati ilu Ile Ife, wọn gbà ọna Ikeregbe ni ẹgbẹ Ilesha kọja, to si jẹ pe titi di akoko yii, ilu Omu-aran ati ilu Ikeregbe ni ajọṣepọ to gunmọ.

"Olómù naa ni orukọ Ọba ti wọn jẹ ni ilu Ikeregbe titi di akoko yii.

Bi Olómù akọkọ se n bọ, o mu Ogbomọna dani ti o jẹ atọna fún un ati iya ọba ti orukọ rẹ n jẹ Orugbo."

"Iya agba Orúgbó ko ku, o ṣi n mi dáadáa ni ile rẹ to wa, ṣugbọn emi nikan ti mo jẹ abọrẹ nikan lo le ri soju."

Abọrẹ tẹsiwaju pe bi wọn se n lọ ninu Igbo ni Ogbomọna, to jẹ atọka fawọn eeyan naa sọ fun Olomu pe wọn ti de ibi ti wọn yóò tẹdo si.

"Ibẹ naa si ni ilu Omu-aran ti wọn tẹdo si ṣugbọn kò si omi nibẹ daadaa ni awọn babanla wa fi ko wa si ẹgbẹ titi ti a wa bayi.

Igba ti iya ọba Orugbo dàgbà dàgbà to fẹ ku, lo ba yira pada to si di ẹbọra ti a n bọ titi di oni yii .

Iya agba naa ko ku nitori o ṣi n mi dáa dáa ni ile rẹ to wa, ṣugbọn emi nikan ti mo jẹ abọrẹ nikan lo le ri soju."

Abọrẹ ni ẹẹkan lọdun ni awọn ma bọ ọ́, oun nikan naa si ni oun ma n bọ lọdọọdun.

O ni ọdọ oun naa ni Ogbomọna ti ọba Olomu akọkọ mu dani wa titi di akoko yii.

O tẹsiwaju pe lati igba ti iya ọba Orugbo ti yira pada, lawọn ti n bọ lọdọọdun.

Olomu ati awn eeyan n lọ si ojubọ iya agba Orugbo lasiko ọdun Orugbo

"Orúgbó, ti a mọ si Orógbó ni wọn maa fi n ka iye ọdun ti ọba kọọkan lo, dipo arugbo, iya yẹn ni wọn wa n pe ni Orugbo"

Alaga igbimọ to se kokari ọdun orugbo fun ti ọdun 2025 naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa pataki iya agba Orugbo fun ilu Omu Aran.

O ni nigba iwasẹ, Orúgbó, ti a mọ si Orógbó ni wọn maa fi n ka iye ọdun ti ọba kọọkan lo.

"Wọn maa n gbe orugbo lọ si igbo Odu, Orugbo yẹn jẹ iya agba ti a n pe ni Omugbodo, ti o bi Olomu Aperan.

Oun lo wa dagba-dagba to kọ ti ko gbo, to kọ ti ko jade laye.

Dipo arugbo, iya yẹn ni wọn wa n pe ni orugbo, ti wọn si maa n se ayẹyẹ iranti rẹ ni ọdọọdun.

Iya yẹn si wa nibi to wa, o wa nibi ti to wa, Abọrẹ nikan lo gbọdọ de ibi to wa, to si lee fi oju kan.

Iya yẹn ko ku, o n bẹ ninu igba nibi to wa, awọn eeyan to ti fi oju ri sọ pe bii iriri eeyan naa lo wa.

Lati 13th Century ti wọn ti da ilu Omu Aran silẹ naa ni iya naa ti wa, awọn eeyan yoku ko si le fi oju kan-an ayafi Abọrẹ nikan."

"Ko si adura ti a se ni ojubọ Orugbo, ti kìí gba, lati igba ti a ti bẹrẹ rẹ"

Abọrẹ ilu Omu-aran Oloye Ajiboye Ademola, salaye pe idi niyii ti ọdun Orugbo maa fi waye lọdọọdun.

"Asekagba ọdun Orugbo ni wọn n pe ni itẹ ọba, ọjọ yii ni kabiyesi Olomu ti ilu Omu-Aran gbọdọ jo ni ita gbangba.

Ẹẹkan ni kabiyesi Olomu gbọdọ jo ni ita gbangba lọdun, o si gbọdọ jẹ ọjọ asakagba ọdun Orugbo ti se itẹ ọba.

Kabiyesi ko gbọdọ lọ ile Orugbo, Abọrẹ nikan lo lasẹ ati lọ, Abọrẹ naa si ni yóò si fun ni nnkan etutu rẹ.

Ti a ba ti fẹ lọ bọ Orugbo, a yóò kọkọ lọ sadura ni oju orori abọrẹ to ba gbesẹ gbẹyin.

Lẹyin ọjọ kẹta itẹ ọba, ni ọdun Egungun maa bẹrẹ ni ilu Omu-aran.

Ko si adura ti a se ni ojubọ Orugbo naa ti kìí gba, lati igba ti a ti bẹrẹ rẹ."

Abọrẹ ni lati ẹgbẹrun mẹtala ọdun ni iya agba Orugbo ti wa titi di asiko yii, ti kosi ku, ko sile ku láé láé.

Ki ni pataki ọdun Orugbo ni ilu Omu Aran?

Ayẹyẹ ọdun Orugbo jẹ asa eyi to pa gbogbo awọn eeyan ilu Omu-aran papọ, o si jẹ ọdun ti gbogbo wọn jọ n ṣe.

Lọjọ ọdun naa, Arugba yóò gbe Orugbo lọ si aafin, wọn o si wure si, lẹyin eyi wọn yóò jẹ akara .

Ayẹyẹ naa jẹ eyi ti wọn fi n ka iye ọdun ti ọba ti lo lori itẹ.

Asiko ọdun naa ni wọn ma n gbe Ogbomọna jade.