Ọdún ìtẹ́ ọba nìkan ni mo ti gbọdọ̀ jó lẹ́ẹ̀kan lọ́dún - Olomu ti Omu-Aran

Olomu ti ilu Omu-Aran joko nibi ayẹyẹ ọdun Itẹ Ọba
Àkọlé àwòrán, Ọjọ mẹwaa ni wọn fi ma n ṣe ọdun Itẹ Ọba niluu Omu-Aran
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbogbo ọmọ ilu Omu-Aran ni ijọba ibilẹ Irẹpọdun ni ipinlẹ Kwara nile, loko, ati lẹyin odi ni wọn peju pesẹ si ilu naa lọjọ Ẹti ọjọ kẹrindinlogun oṣu Karun un fun ayẹyẹ ọdun Orugbo.

Afin Olomu ilu Omu-Aran, Ọba Abdulraheem Oladele Adeoti, nibi ti ọdun naa ti waye ko gba ẹsẹ eero rara.

Ọjọ mẹwaa sẹyin ti ayẹyẹ ọdun naa ti bẹrẹ, asekagba naa to waye lọjọ Ẹti si ni wọn n pe ni Itẹ Ọba.

Ọdun Ite Oba nikan ni ọdun ti Olumu ti n jo

Awọn to n ṣe ajọyọ ọdun Orugbo

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu BBC Yoruba, Ọba Adeoti, ṣalaye pe ọdun Itẹ Ọba ni ọjọ kan ṣoṣo ti oun le jo ninu ọdun.

Olomu Omu-Aran fikun ọrọ rẹ pe ọdun yii jẹ ajọyọ itẹdo ilu naa lati Ile-Ife wa si ibi ti awọn wa lonii.

O ni ọdun naa ti bẹrẹ lati ọjọ mẹwaa sẹyin ti awọn si ti ṣe ọpọlọpọ eto.

Ọba Adeoti sọ wi pe lara ohun ti wọn ti ṣe sẹyin ni gbigbe Orugbo lọ si ile ẹbi ati aafin, ti awọn si jẹ akara lati se ajọyọ naa.

Kabiyesi naa tun se e lalaye pe ilu Omu-Aran jẹ ilu kan pataki ti o wa lara awọn ilu akọkọ ni ilẹ Igbomina.

O ni Ogbo, to jẹ nnkan to se atọna awọn lati Ile-Ife wa si ilu Omu-Aran wa ni ilu naa.

Aworan Olomu ilu Omu-Aran

Ori ade naa ni Omu-Aran nikan ni o ma n se ọdun yii, awọn ko si pa a jẹ ri lati igba ti awọn ti tẹdo.

Kabiyesi fikun un pe ni ọpọ ọdun sẹyin Orangun Ile-Ila gan an maa n wa lati se ajọyọ ọdun Orugbo, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹri lati fidi ọrọ naa mulẹ.

Olomu sọ pe ko si nnkan ti ilu fẹ ki Orugbo ṣe ti ko ni ṣe.

O salaye pe ti ojo ko ba rọ n'iluu, ti awọn ba ti lọ si ojubọ Orugbo lati ṣalaye, ni ṣe ni ojo yoo bẹrẹ lọ gan.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa ọdun Orugbo

Aworan lati ibi ayẹyẹ ọdun Orugbo

Onigẹmọ ti ilu Omu-Aran, Oloye Ademọla Ajiboye, to jẹ Abọrẹ Orugbo sọ pe Orugbo jẹ iya agba to bi Olomu Apẹran.

O ni iya naa jẹ iya nla fun ilu Omu-Aran.

O fi kun un pe iya naa ti di agbalagba, nitori o ti wa lati ọdun 1300 ti awọn ti tẹdo si ilu Omu Aran.

Igbagbọ Abọrẹ ati awọn to n ṣọdun Orugbo ni pe iya agbalagba naa si wa laaye titi di oni.

Onigẹmọ sọ pe iya yii ko lara mọ nitori ọjọ ori rẹ, amọ, o si wa loke eepẹ.

Abọrẹ Orugbo sọ pe ohun ti awọn maa n ṣe lasiko ọdun Orugbo dabi ọjọ ibi iya agba naa.

O ni ọdun Orugbo jẹ asa kan ti o so gbogbo ilu Omu-Aran papọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Oloye Lukman Adeniyi, Onigẹmọ agboole Ora Ayọka sọ pẹ ayẹyẹ itẹ Ọba jẹ ọdun ti ''a maa n fii ka ọdun ti ọba ti lo lori itẹ.

O ni ti awọn ba n se ọdun Orugbo ni awọn maa n gbe ada ogbo ti apẹja rẹ n se ogbomọna jade.