'Ojúbọ̀rọ̀ kọ́ ni mo fi débí, àtẹ̀jíṣẹ́ ikú ni mó ń gbà'- Ẹ̀yà Afrikaner tó di àtìpó l'America

Àkọlé fídíò, Charl Kleinhaus ṣalaye nipa jijẹ atipo l'America
    • Author, Nomia Iqbal and Cai Pigliucci
    • Role, BBC News, Buffalo, New York
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Lọsẹ to kọja, Charl Kleinhaus wa loko awọn mọlẹbi rẹ lagbegbe Mpumalanga, orilẹede South Africa.

Ayika to rẹwa pẹlu awọn iṣẹda ọlọkan-o-jọkan ni. Ibẹ ni a mọ si "Ila -Oorun".

Amọ lonii, ile rẹ tuntun bayii ni otẹẹli olowo pọọku kan to wa nitosi ọna marosẹ kan lorilẹede America.

Kleinhaus ati ọpọ eeyan mi-in ti wọn jẹ alawọ funfun lati South Africa di ero ilẹ America, labẹ iṣakoso Aarẹ Donald Trump.

Aarẹ sọ pe oun fẹẹ da aabo bo wọn kuro nibi iyasọtọ, idẹyẹsi ti wọn n koju, bo tilẹ jẹ pe South Africa ti sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ lọdọ awọn.

Ninu ọrọ Kleinhaus, o ni bo ṣe ri ni Trump wi yẹn. O sọ fun BBC pe oun kuro nilu abinibi oun nigba toun bẹrẹ si i gba atẹjiṣẹ idunkooko iku loju opo WhatsApp oun.

"Mo ni lati kuro nile oniyara marun-un ti mo wa tẹlẹ, ti mo si maa padanu rẹ bayii" Ọgbẹni Kleinhaus lo ṣalaye bẹẹ fun BBC. O fi kun un pe oun ko le gbe mọto oun paapaa, aja oun naa wa nibẹ, koda, iya to bi oun gan-an ko ṣee mu dani. "Ojubọrọ kọ ni mo fi wa sibi."

Kleinhaus ṣalaye pe igbesi aye oun ti yipada leyi toun bẹrẹ si i gbe ni, Buffalo "Aabo wa fun awọn ọmọ mi pẹlu."Ọgbẹni Kleinhaus ti iyawo rẹ ku ninu ijamba ọkọ ni 2006 lo sọ bẹẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ pẹ ti awọn alawọ funfun ọmọ ilẹ South Africa ti wọn jẹ agbẹ ti n pe fun awọn ẹtọ kan ninu oṣelu America.

Aarẹ Trump ati ọrẹ rẹ timọtimọ, Elon Musk, olowo nla toun naa jẹ ọmọ South Africa ti figba kan jiyan ri pe awọn kan n pa awọn agbẹ alawọ funfun ni South Africa, ilu naa si ti ni bẹẹ kọ lọrọ ri.

Loṣu Keji, Trump buwọ lu ofin kan to fun awọn ọmọ Africa laaye lati mọ wọn si atipo, bii ti Kleinhaus, to ni wọn n lepa ẹmi oun.

Ọgbẹni Kleinhaus jẹ ọkan lara awọn eeyan mọkandinlọgọta (59) ti wọn de si papakọ ofurufu Dulles lọjọ Iṣẹgun, nitosi Washington DC, lẹyin ti ijọba Trump lọwọ si eto irinna wọn.

Oun naa sọ pe o ya oun lẹnu boun ṣe sare ri America wọ, ati pe oun dupẹ gidi lọwọ Aarẹ Trump. "O jẹ ki n mọ pe bo ti wu ko pẹ to, ẹnikan ninu aye yii ṣaa n ri ohun to n ṣẹlẹ."

Bi oun atawọn ẹbi rẹ ṣe n balẹ ni papakọ ofurufu naa ni wọn waa ki wọn kaabọ pẹlu awọn fere alawọ pupa, funfun ati awọ aro. Kleinhaus ṣapejuwe ikini kaabọ naa bi eyi to wuni lori jọjọ.

Àkọlé fídíò, Charl Kleinhaus n ṣalaye siwaju si i.

Àwọn wo ni Afrikaner?

Iran ti a mọ si Afrikaners jẹ ida perete alawọ funfun ti wọn darii South Africa lasiko ẹlẹyamẹya; Apartheid. Wọn ṣofin iyasọtọ niluu naa titi ti opin fi ba a ni 1994.

Ṣugbọn lẹyin to ti ju ọgbọn ọdun lọ ti eyi ti waye, awọn agbẹ alawọ dudu ko ni pupọ ninu ile oko to daa nibẹ, ọwọ awọn alawọ funfun ni ọpọ ilẹ ṣi wa.

Eyi ti mu ibinu wa pẹlu bi ayipada ko ṣe tete waye. Ọgbẹni Kleinhaus naa sọ pe awọn alawọ dudu ọmọ South Africa ti jiya gan-an gẹgẹ bi oun naa.

O ni ṣugbọn oun ko ni nnkan kan pẹlu iwa ẹlẹyamẹya ni toun o, bo ti wu ko kere mọ.

Loṣu Kin-in-ni, Aarẹ South African; Cyril Ramaphosa, tọwọ bọwe aṣẹ kan to mu ariyanjiyan wa, eyi to faaye gba ijọba lati gba ilẹ aladaani lai fun wọn ni owo gba-ma-binu kankan.

Wọn ni awọn le ṣe eyi nigba ti ọrọ ba gba bẹẹ, to si jẹ fun anfaani ilu ni."

Ijọba ilẹ South Africa ni awọn ko ti i gba ilẹ kankan ṣa, ṣugbọn Ọgbẹni Kleinhaus sọ pe niwọn igba tijọba ba ti wa to le gba ilẹ eeyan, gẹgẹ bo ṣe ri foun, ko sohun ti eeyan le ṣe.

"Ilẹ rẹ ko ni i wulo mọ, ọrọ ilẹ yii ti lọ jinna gan-an, ẹru n ba awọn eeyan gan-an"

Ṣugbọn awọn Afrikaner miran bii Kleinhaus sọ pe ọkunrin yii ko ìfà ijọba, wọn ni pe o jẹ ẹni to ri idunkooko ko to ohun ti yoo fi jẹ anfaani atipo l'America.

Kleinhaus paapaa sọ pe bi wọn ṣe n pa awọn agbẹ ni South Africa ko fi bẹẹ pọ, o ni ṣugbọn oun ko fẹ kiru ẹ ṣẹlẹ soun. O ni wọn ti yinbọn mọ awọn kan lagbegbe oun ri ti wọn si ku.

O fi kun alaye rẹ pe oun maa n gba atẹjiṣẹ lọpọ igba latọdọ awọn eeyan agbegbe oun nigba naa, ti atẹjiṣe naa yoo maa ka pe " a maa mu ẹ, ori ilẹ mi lo wa."

Ọgbẹni Kleinhaus loun gba atẹjiṣẹ kan koun too lọ si America, o ni oun to wa nibẹ ni: "A n bọ waa ba ẹ, o jẹ ma sun."

Bakan naa lo ni wọn ba awọn irinṣẹ toun fi n dako jẹ, awọn ọlọpaa agbegbe ko si ṣe nnkan kan si ifisun oun lorii rẹ.

Ààrẹ South Africa pe àwọn àtìpò America náà ní ojo

Nigba to n ṣapejuwe awọn ikọ to dero America bii atipo yii, Aarẹ ilẹ South Africa, Ramaphosa, sọ pe ojo ni wọn. O ni wọn ko fẹẹ ṣalaye iwa aiṣe deede wọn lasiko Apartheid ni.

" Gẹgẹ bii ọmọ South Africa, a ni ẹmi igbamọra" Ramaphosa lo sọ bẹẹ nibẹrẹ ọsẹ yii. "A ki i sa lọ fun iṣoro wa. A gbọdọ duro nibi ka yanju iṣoro wa ni."

Ohun kan to mu ki irinajo awọn Afrikaner lọ si America yii di ẹjọ, ni pe wọn ti fofin de awọn aṣatipo mi-in, titi kan awọn ti Afghanistan, ti wọn gba aṣẹ idaboobo wọn pada lọwọ wọn.

Ẹka Homeland Security (DHS), ṣalaye pe igbeṣẹ naa le ri bẹẹ, nitori eto aabo ati ọrọ aje ti n gbera ṣo ni Afghanistan. Bo tilẹ jẹ pe awọn alatako ati awọn ajafẹtọọ ko ri eyi bẹẹ.

Nigba to n dahun si eyi, Ọgbẹni Kleinhaus sọ pe, : " O dun mi fun awọn eeyan Afghanistan ti wọn ko le debi. Ṣugbọn mo mọ pe ilana kan wa nibi. Mo si mọ pe ti wọn ba mu ọ bi ọkan lara awọn ti eto naa kan, wọn maa tọju rẹ."

Se ko lero pe Trump ti sọ ọ di agbatọ rẹ nitori oṣelu? Ati pe aarẹ mi-in le yi anfaani to n jẹ yii pada lẹyin ọdun mẹrin pere?

Kleinhaus mi kanlẹ ko too dahun eyi, lẹyin naa lo ni: "Bẹẹ ni, o ba eeyan lẹru loootọ, ṣugbọn onigbagbọ ni mi. Pe mo tiẹ wa lara awọn iṣi akọkọ to wa sibi yii, iṣẹ Oluwa ni.

Mo nigbagbọ, nitori ko si idaniloju kankan tẹlẹ naa pe wọn tiẹ le mu eeyan lakọkọ."

Àkọlé fídíò, Watch: Wo idi ti America ṣe n fun awọn South Africans lanfaani ati ṣ'atipo

Ìbéèrè nípa àyẹ́wò àtìpó

Eebu ati ọrọ ọlọkan-o-jọkan ni Ọgbẹni Kleinhaus ti n koju lori ayelujara lori awọn ọrọ ẹlẹyamẹya si ijọ Jew, bo tilẹ jẹ pe wọn ko si nibẹ mọ.

Nigba to n ṣalaye nipa eyi, o ni ero ẹnikan loun gbe loju opo rẹ toun lo, ati pe wọn n lo awọn oogun kan foun lasiko naa to lagbara, bo tilẹ jẹ pe oun mọ pe eyi ki i ṣe awijare kankan.

O ni ohun toun gbe jade ni 2023 naa ṣẹlẹ nigba ibinu, lẹyin toun ri fidio kan (BBC ko le fidi ẹ mulẹ), nibi ti wọn ni awọn Jew ti n tutọ si awọn Kristẹni lara ni Israel.

Ọgbẹni sọ pe gbogbo ọrọ to jẹ jade lori rẹ ko ju igba naa lọ, ki i ṣe ọrọ to kari gbogbo Jew. " Koda ni bayii, ti mo ba ri ẹnikan to n tako ẹsin mi, mo maa tako o."

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ naa ni ijọba America paapaa n koju awọn ibeere, pe awọn nnkan wo ni wọn n wo ki wọn too gba awọn aṣatipo naa wọle. Ajọ UN to n ri si ọrọ awọn atipo, sọ fun BBC pe wọn ko fi ilana ti wọn fi ṣa awọn Afrikaner yii to oun leti ti wọn fi ko wọn de America, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe fun awọn aṣatipo mi-in to ba fẹẹ wọle si orilẹede naa.

Ṣaaju ni ẹka Homeland Security (DHS) ti sọ pe oun n yẹ oju opo ayelujara awọn arinrinajo naa wo lati mọ boya wọn ni ọrọ atako nibẹ, awọn si n lo o lati dena awọn to ba ni i.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si BBC, ọga kan lati DHS, sọ pe: "Ẹka Homeland Security maa n ṣayẹwo gbogbo atipo. Bi a ba ri apẹẹrẹ iwakiwa kan, a maa wadii rẹ finni-finni, a si maa gbe igbesẹ to ba yẹ. DHS ki i sọ ohunkohun lori ipo tabi aaye ti arinrinajo kan wa."

Latigba ti Aarẹ Trump ti gba ipo lo ti mura si ọna ti yoo gba lati fi din awọn arinrinajo to n wọ America ku. Eyi la ṣe beere pe bawo lo ṣe ri lara Ọgbẹni Kleinhaus boun ati awọn eeyan rẹ ṣe ri America wọ?

" Awọn eeyan ko gbọdọ maa ro o pe a kofa tabi a da ọgbọn kan pẹlu anfaani yii."

"A wa sibi lati sa ipa tiwa naa fun orilẹede yii ni.

" Emi o bẹru pe boya o maa daru, nitori mo gbagbọ pe eto Ọlọrun fun mi leyi.

"Aye mi wa lọwọ rẹ. Bi ko ba si fẹ ki n wa sibi, mi o ni wa nibi."