"Kò sí ẹni tó mọ bí bàbá mi, Remilekun Amos, ṣe di àwátì, àhesọ lásán ni pé ó jóná mọ́ inú ọkọ̀ tàbí wọ́n fi ṣe ètùtù"

Àkọlé fídíò, “Kò sí ẹni tó mọ bí bàbá mi, Remilekun Amos, ṣe di àwátì, àhesọ lásán ni pé ó jóná mọ́ inú ọkọ̀ tàbí pé wọ́n fi ṣe ètùtù ni”
"Kò sí ẹni tó mọ bí bàbá mi, Remilekun Amos, ṣe di àwátì, àhesọ lásán ni pé ó jóná mọ́ inú ọkọ̀ tàbí wọ́n fi ṣe ètùtù"

Gbajumọ akọrin ẹmi ni Remilekun Amos, ti ọpọ eeyan si fẹran orin rẹ.

Lara awọn gbajumọ orin ẹmi ti Remilekun Amos kọ ni 'Awani wa laye' ati awọn orin ẹmi miran.

Lọpọ ọdun sẹyin, lọdun 2000, tii se ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin ni akọrin ẹmi naa di awati.

Awọn ẹbi, ara ati ojulumọ si wa akọrin ẹmi naa titi amọ ti wọn ko ri.

Lekan Remilekun Amos, to jẹ ọmọ gbajumọ akọrin ẹmi kan, Remilekun Amos wa ba BBC Yoruba sọrọ lori bi baba rẹ se di awati.

Remilekun Amos ati ọmọ rẹ, Lekan

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Lekan Amos salaye ọpọ awuyewuye to rọ mọ iku baba rẹ.

O ni oniruuru ahesọ ọrọ si lawọn eeyan n sọ nipa bi baba rẹ se poora naa.

"Wọn pe baba mi fun isẹ iransẹ lọdun 2000 ni ilu Akure, ti wọn ko si pada wa sile.

A se ikede, a lọ sọdọ ọlọpaa amọ a ko gburo wọn.

Koda, eto Kola Olawuyi gang be nigba yẹ pe wọn fi baba mi se oogun ow oni amọ titi di akoko yii, a ko mọ otitọ ọrọ.

Awọn eeyan miran tiẹ ni boya wọn jina mọnu mọto ni.

Amọ a n ro pe boya Ọlọrun fi ina gbe wọn bii Elijah ni tabi o fi kẹkẹ gbe wọn bii Enoch ni.

Sugbọn titi di akoko yii, a ko mọ ohun to sẹlẹ si wọn."

Lekan Amos wa salaye bo se n saaro baba rẹ lojoojumọ, to si nilo atilẹyin rẹ.

O wa gba awọn ọmọ nimọran lati maa sun mọ obi wọn nitori pe wọn nilo imọran ati iriri wọn, ki wọn maa ba jin si ọfin.

Lekan Remilekun Amos