Ìtàn bí egúngún ṣe di àṣà nílùú Omu-Aran

Ọkan pataki lara ọdun nilẹ Yoruba, ni ọdun eegun jẹ, deebi pe, ko fẹ ẹ si ilu kan ti wọn ko ti ki n ṣe ayẹyẹ ọdun naa kaakiri ilẹ Yoruba. Iyatọ kan le wa ninu bi wọn ṣe n ṣe e ni.
Lati bi ọjọ diẹ ni ilu ti n dun, ti gbogbo rẹ si n sọkutu wọwọ niluu Omu-Aran, nipinlẹ Kwara.
Eyi ni ko ṣẹyin ọdun eegun to n waye nibẹ, ati awọn ayẹyẹ miran to rọ mọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Eruku ti ilu Omu-Aran, Oloye Agbolade Owolewa, ti o jẹ olori gbogbo awọn alasẹ lori egungun ilu naa sọ pe, Ilu Omu-Aran ti wa lati 13th century sugbon egungun wọ ilu naa ni 15th century.
O ni, ni igba kan, Olomu Ogiyan ran aburo rẹ, Agunbiade lọ si ilu Oyo lati lọ gba ade wa fun oun. Ni igba naa, ati Oyo ni Ọba ilu Omu-Aran ti n gba ade.
Sugbọn nigba ti Agunbiade de Oyo, kaka ti yoo fi gba ade wa fun ẹgbọn rẹ, o wo o pe ade naa yẹ oun naa, o si gbaa fun ara rẹ lẹyin to pa awọn idan kan lati fi han wọn niluu Oyo pe, oun naa kun oju osuwọn.
O gba ade naa tan ni oju rẹ walẹ, to si bẹrẹ si I kọminu nigba naa pe njẹ oun yoo rile wọ pẹlu iwa ti oun wu.
"Ṣugbọn awọn eeyan ilu Oyo fi ọkan rẹ balẹ, wọn ni awọn yoo fun ni eegun ti yoo ma fi sẹruba awọn to ba ba nile ti wọn o fi ni le doju ija kọ ọ.
"Wọn fun ni eegun lootọ, o si ko ẹrú ati ẹrù wọ Omu-Aran lati Oyo.


Orukọ eegun ti wọn fun ni Alabarin, o si mu ọpa dani ti wọn fi n deru ba awọn eeyan.
Igba to de, ẹgbọn rẹ Ogiyan ko fi itẹ silẹ fun-un sugbọn gẹgẹ bi Ọba alade, o lọ tẹdo si agbole Afin, oun naa si n se ijọba rẹ nibẹ.
Laipẹ, Olomu Ogiyan ku, Oba Agunbiade si gba gbogbo isakoso Omu-Aran.
Bi eegun sedi ara asa ati ise ilu Omu-Aran niyi, to fi di pe a n se ọdun eegun."
Bakan naa ni Oloye Owolewa ṣalaye pe, ọdun mẹta-mẹta ni eegun maa n jade.
Pataki ọdun eegun niluu Omu-Aran

Yatọ si itan to rọ mọ bi eegun ṣe wọ ilu Omu-Aran, Eruku ti ilu naa tun ṣalaye awọn pataki eegun fun ilu Omu-Aran.
O ni eegun jẹ ohun ti wọn le fi dẹkun iwa ibajẹ lawujọ, o si tun jẹ ohun pataki ti awọn eeyan maa n tọrọ nkan ti wọn ba fẹ lọwọ rẹ ti yoo si ri bi wọn ṣe fẹ.
O ni laye atijọ, eegun jẹ ohun ti wọn kii fi ṣere, sugbọn bayii, eegun ti di ohun amusere fun awọn ọmọde, o ni o ti di (carnival).
O sọ pe, "tẹlẹ, ti eegun ba jade, awọn eeyan yo tọrọ nkan tan fẹ lọwọ rẹ, yoo si ri bi wọn ṣe fẹ, sugbọn bayii, eegun ti di 'carnival'.
"Ọlaju ati ẹṣin lo da wahala a n pa asa ati ise ti, ọpọlọpọ ohun aburu to n sẹlẹ bayii, ko lee sẹlẹ laye atijọ, nitori wọn ni ọna ti wọn yoo fi dẹkun rẹ.
"Ka ni a n se bose yẹ ka see, a le bọ eegun lati ba ajinigbee ja, beyan ba se aida, eegun ni wọn yoo fi lee kuro n'iluu, a mọ bayi wọn ti sọ eegun di toni paraga.
Ẹwẹ, Oloye Owolewa tun sọ pe nnkan ti buru ju bayii lọ nigbakan, sugbọn wọn ti n tunse bọ diẹ diẹ.
Laye atijọ, niluu Omu-Aran, asiko ọdun eegun ni awọn ọmọge maa n fẹ ọkọ, nitori gbogbo awọn ọmọ ilu yoo darijọ sile, wọn yoo si ri ẹni to wu wọn lati fẹ - gẹgẹ bi nnkan ti oloye naa sọ.
"Ọrọ aje ilu nigba naa ati isinsinyi yoo gbe pẹli, nitori awọn eeyan yoo ti ra ọja to pọ, ti wọn yoo ri gbogbo rẹ ta ni asiko ọdun egungun.
"Iyatọ laarin aye atijọ ati isin-in nipe, eegun jẹ ohun ẹru ati ẹmi laye atijọ sugbọn bayii, eegun ti di ohun amusere fun awọn ọmọde.
"Awọn eeyan yoo wọ ka nibi ti eegun ti n jade, wọn o jẹ ounjẹ ọfẹ.
"Laye atijọ, ẹku eegun jẹ ẹlẹmi, a mọ bayi awọn ọmọde lo n gbe eegun, gbogbo ẹku si kọ ni ẹlẹmi mọ."












