Wo kókó ohun márùn-ún tí Seyi Makinde ṣe tí ayé ṣe ń fẹ́ ẹ áti èyí tó mú kí wọn korò ojú sí i láàrin ọdún mẹ́fà tó ti wà nípò gómìnà l'Oyo

Aworan Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Yoruba bọ wọn ni ariṣe ni arika, arika ni baba iregun, ó ti pe ọdun mẹfa ti Seyi Makinde ti wa nipo gomina ipinlẹ Oyo.

Ọpọ igbesẹ ati awọn akanṣe iṣẹ kan ni Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti ṣe eyi to jẹ ki ọpọ eeyan maa sọrọ rẹ.

Awọn nkankan wa ti Makinde ṣe lati igba to ti di gomina ipinlẹ ti inu araalu dun si.

Bakan naa, awọn igbesẹ miran wa ti Makinde gbe gẹgẹ bii gomina eyi to jẹ ki ọpọ eeyan koro oju si i.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba se akojọpọ koko ohun marun ti awọn araalu n yonbo gomina Seyi Makinde fun laarin ọdun mẹfa to ti gori aleefa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo.

Bakan naa, a tun se akojọpọ awọn koko ohun marun miran to se , ti wọn fi n koro oju si i.

Wọnyii lawọn nnkan ti Makinde ṣe to jẹ ki ẹnu maa kun un

Iyansipo awọn ọba

Lọdun 2023 ni Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Ọba Afolabi Ghandi Olaoye gẹgẹ bii Soun ilu Ogbomoso lẹyin awuyewuye to ti waye nile ẹjọ lori ọrọ ẹni ti oye naa tọ si.

Ti ẹ o ba gbagbe, Ọmọba Muhammed Kabiru Olaoye lo gbe Ọba Ghandi lọ ile ẹjọ ti o si sọ fun ile ẹjọ wi pe ko koju oṣunwọn lati jẹ oye naa.

Amọ, gomina ipinlẹ Oyo ko fi ti ẹjọ to wa lori ọrọ oye naa ṣe, o tẹsiwaju lati gbe ọpọ aṣẹ fun Soun.

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Oyo tun da Ọba Samuel Adebayo Adegbola, Eleruwa ti Eruwa ti wọn yọ nipo ọba ni 2019 pada si ori itẹ rẹ lọdun 2025.

Ko tan sibẹ o, Makinde tun kede Ọba Akeem Owoade gẹgẹ bii Alaafin Oyo tuntun lẹyin awuyewuye to ti n waye lori ta ni yoo jẹ oye naa lẹyin ti Alaafin Lamidi Adeyemi ti waja fun bii ọdun meloo kan.

Titako idajọ lori ominira awọn ijọba ibilẹ

Gomina ipinlẹ Oyo fọnmu lori idajọ ile ẹjọ to ga julo Naijiria lọdun 2024, eyi to fawọn ijọba ibilẹ lominira lati maa gba owo wọn sapo taara lati ọwọ ijọba apapọ, dipo bi owo naa ṣe n kọkọ bọ sapo ijọba ipinlẹ wọn.

Makinde sọ pe ijọba ipinlẹ naa ko nilo aṣẹ lati ọdọ ijọba apapọ orileede Naijiria ki wọn to gbe igbesẹ kankan lati tukọ ipinlẹ wọn.

Gomina ipinlẹ Oyo sọ pe pẹlu awọn nnkan ti oun gbọ nipa idajọ naa, iṣini lọna lo jẹ, nitori pe yatọ si ijọba ibilẹ to wa, awọn tun ṣi ni ijọba ibilẹ idagbasoke ti ile-ẹjọ ko mẹnuba, to si ni awọn yoo wa ọna abayọ sii.

O ni oun ko ni jẹ ki iya jẹ awọn araalu nitori idajọ ti ile-ẹjọ agba gbe kalẹ nipa pe ki awọn ijọba ibilẹ maa ṣakoso owo wọn.

Gomina sọrọ yii nibi ipade to ṣe pẹlu awọn alẹnulọrọ ninu eto iṣejọba ibilẹ ipinlẹ Ọyọ lọjọ Aje, nibi to ti gbe igbimọ ti yoo ṣagbeyẹwo awọn ohun to wa ninu iwe idajọ naa.

Ile wiwo ati gbigba ilẹ lati kọle

Ọpọ eeyan ni ipinlẹ Oyo papaa julọ niluu Ibadan lo koro oju si bi ijọba Seyi Makinde ṣẹ bẹrẹ sii wo awọn le kan lagbegbe Podo ni ijọba ibilẹ Oluyole ati Lagelu niluu Ibadan loṣu Keji ọdun 2025 yii.

Kọmiṣọna fun ọrọ ilẹ, ilegbe ati idagbasoke ilu, Arabinrin Willaims AkinFunmilayo ṣalaye pe awọn to kọ ile sori ilẹ ijọba ni ijọba n wo ile wọn.

Arabinrin Akinfunmilayi nnkan ini ijọba ni ilẹ ti ọpọ eeyan kọ ile sori rẹ eyi to lodi sofin.

O fikun ọrọ rẹ pe ẹnikẹni to n ba n kọ ile sori ilẹ ti kii ṣe tiẹ fẹ ji ilẹ naa gba ni.

Kọmiṣọna ni ẹka 3(1) ofin to n daabo bo ohun ini nipinlẹ Oyo ọdun 2017 dabaa ẹwọn ọdun mẹẹdogun fun ẹnikẹni ti o ba jẹbi ẹsun ilẹ gbigba.

Nina owo gọbọi N28.3bn fun ina oju popo lai sisẹ

Makinde kede akanṣẹ iṣẹ ṣiṣẹ ina soju popo nipinlẹ Oyo eyi ti ijọba ni awọn yoo na N28.3bn le lori.

Gomina ipinlẹ sọ pe ina oju popo ṣe pataki gan an, ati pe ṣiṣe ina oju popo yii jẹ apa keji akanṣẹ iṣẹ naa lati igba to ti de ipo gomina.

Makinde ni ina oju popo ṣe pataki fun abo araalu, bakan naa ni o sọ pe ina oju popo yoo tun jẹ ki ọrọ aje ipinlẹ Oyo gberu si i.

Ti ina ko ba ṣẹju fun wakati mẹrinlelogun, awọn oṣiṣẹ eleto abo yoo le ṣiṣẹ wọn daadaa, awọn ọlọja naa yoo lanfaani lati ta ọja wọn.

Ṣugbọn ọpọ araalu lo ti sọ pe awọn ko ri ina lalẹ lọpọ oju popo ni agbegbe awọn nipinlẹ Oyo.

Aipese owo fun itọju ile ẹkọ

Ọpọ eeyan nipinlẹ Oyo lo ti kọminu lori bi ko ṣe sawọn nnkan amayedẹrun lawọn ile ẹkọ nipinlẹ naa.

Iṣẹ iwadii kan fidi rẹ mulẹ pe ọpọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni ipinlẹ Oyo ni ko ni ile iyagbẹ, omi to dara lati mu atawọn nnkan amayedẹrun mii.

Iwadii naa sọ pe ọpọ awọn to wa nijọba lonii lo ti jẹ anfaani ijọba gidi to pese eto ẹko to ye kooro fun, amọ, ti wọn ti kuna lati ṣe iru eto ti wọn janfaani rẹ fun araalu bayii.

Ọpọ ile ẹkọ nipinlẹ Oyo ni a gbọ pe awọn akẹkọọ maa n wa omi kiri adugbo ki wọn to le ri omi lo.

Aiṣeto to mọyan lori lẹka eto ilera

Lara ẹka ti ọpọ ti n sọ pe ijọba Makinde ko ṣe daadaa to nibẹ lati ọdun mẹfa to ti jẹ gomina ipinlẹ Oyo ni ẹka eto ilera.

Iwadii fi han pe oṣiṣẹ eleto ilera 2,149 pere lo n ṣiṣẹ ni gbogbo ile iwosan alabọde to wa ni gbogbo ijọba mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ Oyo.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa imọ iṣegun ni iya awọn eeyan yii kere gan an ti a ba wo iye araalu ti wọn maa tọju.

Bi o tilẹ jẹ pe ajọ to n seto adojutofo lẹka eto ilera, OYSHIA wa amọ ọpọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo ni ko ni igbẹkẹle ninu awọn ile iwosan ijọba nitori ipo ti wọn wa.

Ile iwosan aladaani lawọn kan maa n gbe ẹbi wọn to ba n ṣaisan lọ.

Awọn aṣeyọri ti araalu n gboriyin fun Makinde le lori

Atunse ọna laarin igboro Ibadan

Lara awọn nnkan ti araalu n gboriyin fun Makinde fun ni ṣiṣe oniruuru ọna ni igboro ilu Ibadan wa.

Makinde ni akanṣe iṣẹ ọna ṣiṣe ti ijọba oun gunle jẹ ọna kan gboogi lati pese ohun amayedẹrun fun araalu ilu.

Gomina sọrọ yii nigba to n ṣi ọna kilomita 38.48 laarin ilu Ibadan eyi ti o ṣatunṣe rẹ.

Lara awọn ọna naa lo gba ibudokọ ile itura D'Rovans, Ring Road.

Bakan naa ni Makinde tun ṣatunṣe awọn ọna ni ẹkun iwọ oorun guusu ilu Ibadan, iwọ oorun ariwa Ibadan to fi mọ ila oorun guusu Ibadan.

Ko tan sibẹ, ijọba Makinde tun ṣe ọna lawon ilu mii to wa nipinlẹ Oyo.

Lara iru awọn ọna bẹẹ ni ọna to lọ si ilu Iseyin lati Ogbomoso.

Sisan owo osu oṣiṣẹ deede ati ajẹmọnu oṣiṣẹfẹyinti

Lara nnkan ti ọpọ eeyan ipinlẹ fẹran nipa ijọba Makinde ni sisan owo oṣu ati ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ wa.

Bakan naa ni ijọba Makinde n san owo awọn oṣiṣẹfẹyinti ni ipinlẹ Oyo deede.

Ṣaaju ni gomina ti sọ pe eto ọrọ aje ipinlẹ Oyo ti duro daadaa tori bii ijọba oun ṣe n fi N24bn sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ ipinlẹ ati ijọba ibilẹ loṣooṣu.

Makinde ni eleyii ti jẹ ki ọpọ awọn olokowo wa da dokowo kaakiri ipinlẹ Oyo.

Gomina rọ awọn araalu lati maa ba ara wọn gbe ni alaafia tori ninu alaafia ni idagbasoke wa.

Ṣiṣe atilẹyin fun Aarẹ Tinubu lati wọle ibo aarẹ

Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan lẹyin ti Makinde ṣatilẹyin fun Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2023, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ APC lẹgbẹ Tinubu.

Nigba ti o n sọ idi ti o fi ṣe bẹẹ, Makinde to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ni ṣiṣe atilẹyin fun Tinubu ninu ibo aarẹ ṣe pataki fun eto oṣelu Naijiria.

Gomina ipinlẹ Oyo sọ pe ododo, ati aiṣegbe lẹyin ẹnikan loun duro fun.

Makinde iṣọkan orilẹede Naijiria lo jẹ oun logun, ati pe oun n fẹ orilẹede ti yoo fun gbogbo eeyan lanfaani lai fi ti ẹya ṣe.

Gomina ipinlẹ Oyo ni idi niyii toun fi ṣe atilẹyin fun Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2023.

Sisọ papakọ ofurufu Ladoke Akintola di ti agbaye

Sisọ papakọ ofurufu Samuel Ladoke Akintola di ti agbaye jẹ ọkan lara awọn akanṣe iṣẹ ti Makinde ṣe tawọn eeyan fi n gboriyin fun un.

Ni ẹka jẹka ni iṣẹ to ti bẹrẹ lori papakọ ofurufu lati oṣu kẹsan ọdun 2024 ṣe n lọ.

Ni oṣu Kẹfa ọdun 2026 ni ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe iṣẹ yoo pari lori papakọ ofurufu naa.

Ijọba ni awọn eeyan yoo lanfaani lati maa rinrin ajo lati papakọ ofurufu naa lọ si ibikiki to wu wọn ki ọdọ 2025 yii to pari.

Makinde ni papakọ ofurufu yii yoo jẹ ki ọpọ eeyan to rinrin ajo kaakiri agbaye maa wa si ipinlẹ Oyo.

Sisan owo ile iwe awọn akẹkọọ nipinlẹ Oyo

Gomina ipinle Oyo ti sọ pe ko din ni 80,000 akẹkọọ to ti pada sile ẹkọ lẹyin ti ijọba oun ni kawọn obi ma san N3,000 ti wọn maa n san lori ọmọ kọọkan mọ.

Ti ẹ o ba gbagbe, lẹyin ti Makinde wọle ibo gomina tan lọdun 2019 ni o kede pe kawọn akẹkọọ ma san owo naa mó.

Makinde ni o ṣe eleyii lati ri pe gbogbo ọmọde ni ipinlẹ Oyo lo lanfaani lati lọ ile ẹkọ.

Gomina ipinlẹ Oyo ni ohun tun ṣe eleyii lati jẹ ki eto ẹkọ rinlẹ si nipinlẹ naa.

Gbigba olukọ 19,500 siṣẹ laarin ọdun marun un

Ẹgbẹ awọn olukọ nipinlẹ Oyo, NUT, ti gboriyin fun Makinde lori bi o ti gba olukọ 19,500 siṣẹ laarin odun marun un.

Ẹgbẹ NUT ni ẹgbẹrun marun un olukọ ni Makinde gba siṣẹ ni saa akọkọ ti o lo gẹgẹ gẹgẹ bii gomina.

Bakan naa ni ẹgbẹ naa ṣalaye pe ẹgbẹrun mẹrinla ati abọ olukọ ni Makinde to gba siṣẹ bayii ni saa keji ijọba rẹ.

NUT ni igbesẹ ijọba yii yoo wa ojutuu si iṣoro aito olukọ to n koju eto ẹjọ alakọbẹrẹ ati girama nipinlẹ Oyo.

Ko din ni eeyan 902 to jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba mii ti Makinde tun gba siṣẹ.